'Baba Sala tó bí mi lọ́mọ jẹ ìyà lójú mi dáadáa lágbo Tíátà, bí èmi náà ṣe di olórin..., hmmn!'

Àkọlé fídíò, Baba Sala's daughter: Adejumo Oyindamola sọ ìdí tó ṣe bẹ̀rù agbo òṣèré tàbí orin kíkọ
'Baba Sala tó bí mi lọ́mọ jẹ ìyà lójú mi dáadáa lágbo Tíátà, bí èmi náà ṣe di olórin..., hmmn!'

O ṣeeṣe ki ẹ mọ Baba Sala daadaa gẹgẹ bii gbajugbaja adẹrinpoṣonu lagbo ere tiata Yoruba ati ni Naijiria lapapọ, amọ o tun ni orin kan ti ọpọlọpọ maa n kọ daadaa ti yoo ya yin lẹnu pe ọmọ bibi Baba Sala lo kọ ọ.

Oyindamola Adejumo to jẹ ọmọ Apostle Moses Olaiya Adejumo ti ọpọ mọ si Baba Sala ba BBC Yoruba sọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo yii nipa bo ṣe bẹrẹ orin kikọ lati kekere bo tilẹ jẹ pe iya rẹ ko tii lẹyin amọ baba rẹ tii lẹyin gbágbá.

Aworan Baba Sala ati ọmọ rẹ, Oyindamola

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Amọṣa lasiko yii, onimọ nipa eto ọrọ aje ni Oyindamola jẹ nitoripe ibẹru aduru iya to ṣe oju rẹ ti baba rẹ, Baba Sala jẹ gẹgẹ bi oṣere ti iya rẹ naa ko si fẹ ko la iru rẹ kọja muu lọ ka iwe.

Oyin ka iwe titi de fasiti to tun ka awọn akanṣe iwe mii fun ipo giga nitori ẹka to ti n ṣiṣẹ pẹlu ijọba.

Baba Sala

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ẹwẹ, Oyin ni bi wọn ba ji oun pẹpẹ, orin lo ṣi maa jade lẹnu oun nitorinaa, owo oṣu maa n lọ fun eto orin kikọ ti oun maa n lọ ṣe iṣẹ iranṣẹ tabi isọji kaakiri.

Orin to sọọ di gbajugbaja to si maa n mu inu rẹ dun bo ṣe n gbọ ọ kaakiri Naijiria atawọn orilẹede agbaye ni “Ọlọrun mi mọ ohun ti yoo ṣe, taye mi yoo fi dara”.

Oyindamola