Ènìyàn méje jóná nínú ìjàmbá ọkọ̀ márosẹ̀ Ibadan sí Eko

Oríṣun àwòrán, Others
Eniyan meje lo ti padanu ẹmi wọn lasiko ti ọkọ meji kọlu ara wọn nitosi afara Sapade ni ijọba ibilẹ Ariwa Remo, nipinlẹ Ogun.
Adari ajọ ẹsọ oju popo, FRSC, Ahmed Umar lo kede pe eeyan meje to wa ninu awọn ọkọ naa, lo jona raurau.
Umar ni ohun to fa ijamba ọkọ ni aibọwọ fun ofin eto irinna loju popo eyi to fa ere asapajude.
Iroyin ni eeyan mẹtadinlọgbọn lo fara gba ninu iṣẹlẹ naa, to fi mọ ọdọ langba marundinlọgbọn, obinrin meji ati ọmọdebinrin ẹyọ kan.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni Ọkọ Toyota Sienna ati ọkọ Mazda lo kọlu ara wọn ninu ikọlu naa.
Wọn ni ọkọ Toyota lo kọlu ọkọ elero Mazda naa loju popo, to si gbina.
Ajọ FRSC wa kesi awọn awakọ loju popo lati ṣọra ṣe pẹlu aibọwọ fun ofin oju popo nipa sisare asapajude loju popo.
Ajọ naa ni ki wọn ranti pe ẹmi wọn ko pe meji , to si pọn dandan ki wọn wa laaye.
'Wọ́n yìbọn lu ọkọ mi lásìkò tó fẹ́ dóòlà àwọn ènìyàn'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn olugbe ipinlẹ Benue ti wọn farakasa ikọlu to waye lọjọ keje oṣu kẹta sọ BBC ohun ti oju wọn lasiko ikọlu naa.
Ikọlu ọhun to waye lo jẹ ki awọn eeyan maa se iranti awọn ololufẹ wọn to padanu ẹmi wọn lasiko ikọlu naa.
Awọn agbegbọn yabo ibudo awọn eeyan ti ko ni ile lori ati awọn agbegbe lo wa layika ijọba ibilẹ Guma nipinlẹ Benue, ti wọn si sekupa ọpọlọpọ eeyan.
O to ọgbọn eeyan to padanu ẹmi wọn nibi isẹlẹ naa.
Sewuese Anene, Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni isẹlẹ naa waye asalẹ ọjọ Ẹti.
Eyi lo jẹ ọkan lara ọpọlọpọ ikọlu to ti n waye ni arin-gbogbo ipinlẹ Benue.
Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa sọ fun BBC pe oun ati ọkọ rẹ sun lọwọ ni wọn gbọ iro ibọn.
O ni o gbinyanju lati ikilọ fun ọkọ oun lati ma jade sugbọn o kọ , to si bọ sita lati ran awọn eeyan lọwọ, to si padanu ẹmi rẹ nibẹ.
Faith Shawa ni awọn agbebọn sekupa ọkọ oun ati awọn ẹgbọn rẹ lobinrin , ti oun si farapamọ sinu yara lasiko ikọlu naa.
Ẹlomiiran to pe orukọ ara rẹ ni Veronica ni oun n sun labẹ igi kan niluu ile rẹ lọwọ ni oun gbọ iro ibọn, ti awọn eeyan si bẹrẹ si ma saa kijo kijo.
O sọpe pe awọn agbebọn naa sekupa ọmọ rẹ ati ọpọlọpọ eeyan lasiko ikọlu ọhun
Veronica ni oun ko le sọ pato nnkan ti awọn se fun awọn agbebọn.
‘Wọn sekupe eeyan 37, ti eeyan 43 ti si farapa’
Ọkan lara awọn osojumikoro sọ pe awọn agbebọn to aadọta ni ye, ti wọn se ikọlu nibi ago mẹsan alẹ.
O ni wọn sina bolẹ bi wọn se wọle, ti wọn miiran ninu si mu ada, ibọn ati okuta da ni.
“Ki a to mọ nnkan to sẹlẹ, wọn ti bẹrẹ sini ma yinbọn , ti wọn si gbe igi dena fun lati ma le kọja.
“Wọn ba awọn ile jẹ, jo ọkada ati ọkọ.
“Wọn sekupa eeyan mẹtadinlogoji, ti eeyan mẹtalelogoji si farapa yanayana .”
Osojumikoro miiran rawọ ẹbẹ si Aarẹ Muhammadu Buhari ati Gomina Samuel Ortom lati pese ohun abo fun awọn ara agbegbe naa.
Nítorí oyún oṣù méjì, ọmọ ọdún 20 gbẹ̀mí ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, àṣírí tú!

Oríṣun àwòrán, Kanopolice
Gende ọkunrin meji lo ti wa ni ahamọ ọlọpaa lẹyin ti ile iṣẹ ọlọpaa kẹfin oku ọmọdebinrin kan to loyun ni agbegbe ijọba ibilẹ Bebeji nipinlẹ Kano.
Abdullahi Kidaya agbẹnusọ ile isẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ni, oku ọmọbinrin naa ni wọn ri lẹgbẹ ọna. O ni awọn kan lo ri oku naa ti wọn si fi to ile isẹ ọlọpaa leti ki awọn osisẹ ilera to fidi rẹ mulẹ wi pe ọmọbinrin naa ti padanu ẹmi rẹ.
Agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹta ọdun yii ni isẹlẹ naa waye ni agbegbe Anadariya, to wa ni opopona Kano si Jos ni ijọba ibilẹ Bebeji.
Obinrin ti wọn gbẹmi rẹ naa ni Theresa Yakubu ẹni ogun ọdun to wa lati abule Anadariya kan naa.
Agbẹnusọ ile ise ọlọpaa Kano ni, Afurasi ọhun lo fẹnu ara rẹ sọ wi pe oun ko fẹ oyun, ki orẹbinrin rẹ Theresa wa nkan ṣe sii.
Ọrẹ meji gbimo pọ gbẹmi Theresa
Kiyawa ni iwaadii fihan wi pe Theresa loyun oṣu meji ki wọn to gbẹmi rẹ, eyi lo mu awọn osisẹ ile iṣẹ ọlọpaa fi pampẹ ofin mu orẹkunrin Theresa, ọmọ ogun ọdun.
O ni ọrẹkunrin Theresa jẹwo pe oun lo ni oyun inu Theresa, ti o si tun gbimọ po pẹlu ọrẹ rẹ kan ẹni ọdun marunlelogun lati pa Theresa nitori gbogbo ọna ti wọn gba lati sẹ oyun inu rẹ lo jasi pabo.
Nigba ti o n jẹwọ fun awọn ọlopaa o ni, oun fi gele rẹ fun un lọrun ti ọrẹ oun si ba di ọwọ Theresa mejeji mu ninu igbo kan.

Oríṣun àwòrán, KANOPOLICE
Iwadii Ọlọpaa.
Ile iṣẹ ọlọpaa Kano ṣalaye wi pe obinrin kan lo fi to awọn ọlọpaa leti wi pe oku ọmọbinrin kan wa lẹgbẹ igbo.
Eyi lo jẹ ki kọmisona ọlọpaa Kano pasẹ ki SP Taminu Wada ẹniti o jẹ DPO ile iṣẹ ọlọpaa Bebeji lọ ṣe iwadii ni kikun nipa iṣẹlẹ naa.
Wọn gbe Theresa lọ si ile iwosan ijọba to wa ni Tiga nibi ti wọn ti kede pe o gbẹmi mi.
Kiyawa ni wọn ti fa ẹjọ naa le ẹka to ri si iṣẹlẹ isekupani fun ayẹwo to peye, o si ṣeleri wipe ile iṣẹ ọlọpaa yoo gbe ẹjọ naa lo si ile ẹjọ ti iwaadii ba ti pari.
















