Àwọn adigunjalè ṣọṣẹ́ ní ọjà fóònù l'Abeokuta, pa ọlọ́jà kan, jí fóònù tó tó N14m gbé lọ

Oríṣun àwòrán, POLICE OGUN
Àwọn adigunjalè ní ọjọ́rú, ọjọ́ Kejìlá oṣù Kẹrin, ọdún 2022, yawọ ilé ìtajà fóònù kan tó wà ní agbègbè Ibara, Abeokuta, ìpínlẹ̀ Ogun.
Ilé ìtajà fóònù ọ̀hún tí wọ́n ń pè ní Tarmac ni àwọn adigunjalè ti lọ ṣọṣẹ́ tí wọ́n sì pa òǹtàjà fóònù kan níbẹ̀.
Ìròyìn ní nǹkan bí i aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ ń lọ lù ni àwọn adigunjalè náà tí wọ́n tó mẹ́jọ bẹ̀rẹ̀ sí ní yìbọn sókè láti fi dẹ́rùba àwọn ènìyàn.
Alága ẹgbẹ́ àwọn tó ń ta àti tó ń tún fóònù ṣe ní ìpínlẹ̀ Ogun, Ifebola Togunwa ní àwọn adigunjalè ọ̀hún, tó da àwọ̀n bojú, pín ara wọn sí ọ̀nà mẹ́rin láti fi ja ṣọ́ọ̀bù mẹ́fà lólè láàárín wákàtí kan.
"Ọwọ́ ba ọ̀kan nínú àwọn adigunjalè náà, tí àwọn sì ti fà á lé àwọn ọlọ́pàá ti àgọ́ Ibara lọ́wọ́"
Togunwa ṣàlàyé pé n ṣe ni gbogbo àwọn ọlọ́jà náà sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ń lọ lọ́wọ́.
Ó ní fóònù tí iye rẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́rìnlá náírà ni àwọn adigunjalè náà gbé lọ.
Ó fi kun pé lọ́gán ni àwọn pé àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n sì wá láti kojú àwọn adigunjalè náà.
Ó tẹ̀síwájú pé nígbà tí àwọn adigunjalè náà ń gbìyànjú láti sá lọ ni àwọn ọlọ́jà fóònù náà kan darapọ̀ mọ́ àwọn ọlọ́pàá, láti sá tẹ̀lé àwọn adigunjalè ọ̀hún.
"Nígbà tí wọ́n ń lé àwọn adigunjalè náà lọ ní òpópónà Ibara-Omida, ìbọn ba ẹnìkan nínú àwọn ọlọ́jà wa, tó sì jáde laye nígbà ta fi máa gbe dé ilé ìwòsàn ní Ìjàyè."
Togunwa ní ọwọ́ ba ọ̀kan nínú àwọn adigunjalè náà, tí àwọn sì ti fà á lé àwọn ọlọ́pàá ti àgọ́ Ibara lọ́wọ́.
Ọlọ́pàá fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ...
Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, Agbẹnusọ ọlọ́pàá Ogun, Abimbola Oyèyemi ní kété tí àwọn ọlọ́jà fóònù náà pe àgọ́ ọlọ́pàá Ibara láti fi tó wọn létí pé àwọn adigunjalè ń ṣọṣẹ́ lọ́wọ́ ni DPO da àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ lọ síbẹ̀ láti lọ nawọ́ gán wọn.
Ó ní àwọn ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò Amotekun láti lè rí pé àwọn ṣe àṣeyọrí.
Ó ní bí àwọn adigunjalè náà ṣe rí àwọn ọlọ́pàá ni wọ́n da ìbọn bolẹ̀ láti kojú àwọn àmọ́ agbára àwọn ọlọ́pàá ju ti àwọn olè náà lọ tí wọ́n sì gbìyànjú láti sá lọ.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá ní lásìkò tí àwọn olè náà ń sá lọ ni àwọn ọlọ́pàá pẹ̀lú àtìlẹyìn àwọn ọlọ́jà fóònù náà fi mú ọ̀kan lára àwọn adigunjalè náà, Adeniji Sakiru tó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n.
Bákan náà ló ní ó ṣeni láàánú pé ọ̀kan lára àwọn ọlọ́jà náà fara gba ọta ìbọn àwọn adigunjalè náà tó sì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ní ilé ìwòsàn tó ti ń gba ìtọ́jú.
Ó ṣàlàyé pé lára àwọn nǹkan tí àwọn rí gbà lọ́wọ́ afurasí tí ọwọ́ tẹ̀ náà ni ìbọn àti òògùn ìbílẹ̀.
Ó ní Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Frank MBA ti ní kí wọ́n gbé ẹjọ́ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn fún ìwádìí tó péye.
Oyeyemi fi kun pé Mba ti pàṣẹ pé kí àwọn ṣe àwárí àwọn afurasí yòókù láìpẹ́.
Ó wá pàrọwà sí àwọn ènìyàn pàápàá ilé ìwòsàn láti fi ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí pẹ̀lú ọgbẹ́ ìbọn lára tó ọlọ́pàá létí ní kíákíá.
Ẹ ṣe àwárí àwọn yòókù kíákíá - Gómìnà Abiodun pàṣẹ fáwọn ọlọ́pàá
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun, Dapo Abiodun ti rọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà láti tètè ṣe àwárí àwọn adigunjalè tó lọ ṣọṣẹ́ ní ọjà fóònù náà.
Abiodun nínú àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ rẹ̀, Kunle Somorin júwe idigunjalè náà bí èyí tó burú jáì tó sì ṣèlérí àtìlẹyìn tó péye fún àwọn ọlọ́pàá láti rí àwọn ẹni ibi náà mú.
Ó kan sáárá sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá àti Amotekun bí wọ́n ṣe tètè jí gìrì sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní èyí tó ṣokùnfà kí wọ́n rí ẹnìkan mú nínú àwọn afurasí náà.
Bákan náà ló yin àwọn ará ọjà náà lákin fún ìgboyà wọn.
Gomìnà Abiodun tún bá àwọn ẹbí ọlọ́jà tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà kẹ́dùn.
Ó sọ àrídájú rẹ̀ ohun gbogbo tó bá gbà láti nawọ́ gán àwọn tó sá lọ ní àwọn yóò ṣe àti pé òun ní ìfarajìn sí ààbò ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ogun.















