Fijilańté yarí, kọlu ibùba ajínigbé tó jí èèyàn méjìlá, òkú sùn

Oríṣun àwòrán, AwonFigilante
Awọn fijilante ilu Ibbi to wa ni Ipinlẹ Niger ti kọju ija sí awọn ajinigbe agbebọn to n ṣe ikọlu si wọn, wọn si gbẹmi aadọta ninu awọn agbebọn naa
Ile iṣe akọroyin Leadership fìdi rẹ mulẹ pe awọn fijilante naa bẹrẹ si ni kọlu awọn alakatakiti ọhun, ti wọn si ba agọ wọn jẹ ni isalẹ oke nla kan to wa ninu Kainji, lẹyin ti wọn ji awọn eeyan mejila gbe ni nnkan bi ọṣẹ meji sẹyin.
Ẹnikan ninu ilu ọhun lo ṣalaye wi pe, awọn fijilante Ibbi pẹlu iranlọwọ awọn fijilante lati Guusu ipinlẹ Niger lo jọ kọwọrin lati ṣe ikọlu naa.
O ni fun bi ọjọ mẹrin ni awọn fijilante ti wa ninu Igbo lati ṣawari ibudo awọn alakatakiti agbebọn ọhun.
Meji ninu awọn fijilante naa padanu ẹmi wọn, ti awọn agbebọn si fi ibinu gbẹmi mẹsan ninu awọn to wa ni ahamọ wọn.
Awọn fijilante ilu Ibbi lo se ikọlu si agọ awọn agbebọn naa nigba ti wọn n reti kí awọn ara ilu ọhun san owo itusilẹ lori awọn mejila ti wọn jigbe, ti wọn si gbẹmi aadọta lara awọn alakatakiti naa.
Lara awọn mejila ti awọn agbebọn jigbe ni akọwe ile ẹjọ Sharia kan, obinrin mẹfa, ọkunrin mẹta, ti awọn mẹta to ṣeku si mori bọ .
Abdul Ahmed, olugbe Ibbi ni awọn agbebọn ọhun ni wọn ti wa ni Kanji fun igba pipẹ, ti wọn si ma n ṣe ikọlu si awọn ara ilu Ibbi àti awọn ilu to yi i Kanji ka.
Wayi o, ileesẹ ọlọpaa ti fidi isẹlẹ naa mulẹ.
Abdul ni eyi lo jẹ ki awọn ẹgbẹ fijilante pẹlu ifọwọsi ijọba wọ ahamo awọn agbebon naa lo lati fopin si iṣẹlẹ ijinigbe awọn alakatakiti ọhun.
Ọga agba kan nilẹ iṣẹ ijọba fidi isẹlẹ naa mulẹ o ṣi ni ijọba ipinlẹ Niger fọwọsi igbesẹ awọn fijilante ọhun.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Niger Wasiu Abiodun ni ko ti fesi si iṣẹlẹ naa lẹyin ti awọn akọroyin gbiyanju lati pe,ṣugbọn ọga kan nilẹ iṣẹ ọlọpa fìdi ọrọ naa mulẹ to ṣi ni ile ọlọpa ma n pese aabo fun awọn fijilante nigba ti wọn ba fẹ se iru ikọlu bi eyi ti awọn fijilante Ibbi ṣe.
Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn bẹ́ orí ọlọ́pàá, jù ú òkú rẹ̀ sínú kànga

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom ti bẹrẹ iwadi lori iku ọkan lara wọn, Uwem Cletus, ẹni ti wọn so mọ agbegbe Ikot Abasi Akpan ni ijọba ibilẹ Mkpat Enin.
Iwadi fihan pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to n da wahala silẹ ni agbegbe Mkpat Enin lo sekọlu si Ọlọpaa ọhun ti wọn si bẹ lori, ti wọn si tun ju sinu Kanga.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Odiko Macdon, nigba to n bawọn akọroyin sọrọ niluu Uyo ni ọrọ naa ba Kọmisọna Olatoye Durosinmi ninu jẹ gan, to si ti da awọn ọlọpaa sita lati wa awọn kọlọrọsi eda to se isẹ buruku naa.
“Oloogbe Uwem Cletus jẹ ọkan lara wa. Nigba ti a kọkọ gba iroyin naa, wọn o sọnu, ti a si bẹrẹ si ni ma wa kiri, lasiko ti a n wa ni ri pe wọn ti bẹ lori, ti wọn si tun ju oku rẹ sinu kanga.
“Gbogbo awọn mọlẹbi ni a ba kẹdun sugbọn gẹgẹ Kọmisọna se se ileri, a ri pe mu awọn janduku, ti wọn yoo si jiya labẹ ofin
“Kọmisọna ti palasẹ pe ki iwadii nikunkun bẹrẹ lori isẹlẹ naa, a n se ileri pe awọn janduku naa yoo ri ijiya labẹ ofin laipẹ,”
Kílódé ti DSS ṣe gbé Páṣítọ́ Arayomi àti ìyàwó rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Facebook/Tomi Arayomi
Oludasilẹ ile ijọsin RIG Nation, Tomi Arayomi ti sọrọ sita fun igba akọkọ lẹyin ti iroyin nipa bi ajọ DSS se palẹmọ oun ati iyawo rẹ, Tahmar Arayomi se gba ori ayelujara
Lọjọ Ẹti, ọsẹ to kọja ni iroyin naa gba ori afẹfẹ pe ajọ DSS mu Pasitọ kan ati Iyawo rẹ sugbọn oun to fa ti DSS fi gbe igbesẹ naa lo sokunkun bayi.
Pasitọ Arayomi, ẹni to ma n sapejuwe ara rẹ gẹgẹ bi ‘Woli orilẹede’, ninu atẹjade kan to fi ransẹ sawọn akọroyin ati eyi to tun gbe sori ayelujara, fi idi rẹ mulẹ pe otitọ ni pe ajọ DSS palẹmọ oun, iyawo rẹ ati amugbalẹgbẹ rẹ, Emmanuel Ezerika lẹyin ti wọn balẹ si ilu Abuja lọjọ keje oṣu kẹrin ọdun 2023.
O ni awọn osisẹ ajọ naa bi mẹfa ti wọn ko wọ asọ tabi ni ami idanimọ lo ya bo awọn, ti wọn si gba ẹrọ ibaraẹnisọrọ lọwọ wọn, ti wọn si ko wọn lọ ileeṣẹ ajọ DSS.
“Lọjọ keje, oṣu tawa yii ni awọn DSS ti wọn ko wọ asọ tabi ni ohun idanimọ se abẹwo si wa , ti wọn si ko wa lọ si agọ wọn.
“Wọn fipa mu emi, Iyawo mi, ati ọkan lara awọn to n bami sisẹ, Emmanuel Ezerika, ri wọn si gba ẹrọ ibaraẹnisọrọ wa, ti wọn si ko wa lọ agọ wọn.
Arayomi ni awọn kan lara awọn osisẹ DSS to wa kowọn ni wọn fi nnkan boju wọn, ti oun ko si mọ pe osisẹ DSS ni wọn se.
O ni oun ko le sọ pato nnkan to sẹlẹ ti wọn fi wa mu oun sugbọn wọn bere ọpọlọpọ ibeere.
Pasitọ ọhun ni oun ko le sọ nnkan ti awọn osisẹ DSS n se iwadi le lori nitori ọkan lara wọn si wa ni atimọle.
Tomi Arayomi salaye oun ti oju rẹ ri lọwọ Ajọ DSS
Pasitọ Arayomi ni oun ni igbagbọ pe ariwo awọn eeyan lori ayelujara lo fa ti ajọ DSS se tun oun ati iyawo rẹ silẹ.
O ni wọn ya aworan, gba ami ọwọ wọn silẹ, ti wọn si ti wọn mọ yara kan, ti wọn ko si mọ ohun pato ti wọn se.
“Wọn ya aworan wa, gba ami ọwọ wa silẹ ati awọn nnkan miiranki wọn to lọ ti wa mọle. Lẹyin ọpọlọpọ ifọrọwerọ, ariwo awọn eeyan lori ayelujara lo jẹ ki wọn tu emi ati iyawo mi silẹ.
“Amugbalẹgbẹ mi si wa ni agọ DSS, ti wọn ko sọ pato ibi ti wọn fi pamọ si. A ko ni le sọrọ ju nitori iwadi n lọ lọwọ bayi.”
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
“A yoo kuro lorilẹẹde Naijiria”
Pasitọ ọhun ni oun ati mọlẹbi rẹ ti pinnu lati kuro lorillẹede Najiria.
O ni igbesẹ naa nira sugbọn awọn ko ni dẹkun ninu fifi adura ransẹ si orilẹede Naijiria.
Arayomi ni oun ni igbagbọ pe awọn yoo pada si orilẹede Naijiria lọjọ kan nibi to jẹ ilu abinibi wọn















