"Àwọn agbébọn ṣekúpa àbúrò mí obìnrin, yínbọ̀n fún bàbá mi lásìkò ìkọlù"

aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Mike Yusuf, agbegbe Atak Njei nijọba ibilẹ Zangon Kataf nipinlẹ Kaduna wa ni ile wosan bayii nibi to ti n tọju baba rẹ ti awọn agbebọn yinbọn fun lasiko ti wọn ṣọṣẹ lagbegbe naa.

Mike salaye fun BBC pe inira nla loun atawọn mọlẹbi oun wa.

O ni oun tun padanu ẹgbọn oun kan ti orukọ rẹ n jẹ Grace Yusuf lọjọru ti ikọlu naa waye, pẹlu arọwa si ijọba pe o to akoko lati fopin si idunkoko awọn agbebọn lasiko yii.

Eeyan kan ti iṣẹlẹ naa ṣe oju rẹ sọ pe, awọn agbebọn yabo agbegbe naa ni ago nnkan bii mẹsan alẹ, ti wọn si pa eeyan mẹjọ, ti ọpọ mii si farapa yanayana.

“Igba keji ree ti irufẹ ikọlu yii yoo waye,ni agbegbe wa. Igba kẹyin ti wọn wa, wọn sekupa eeyan meji

“Mo wa ni Kajuru nigba ti mo gba ipe pe nnkan ti sẹlẹ si awọn mọlẹbi mi.

“Wọn sekupa ẹgbọn mi obinrin Grace, ti wọn si tun yinbọn fun baba mi ni igbaya, mo wa pẹlu rẹ bayi to ti n gba itọju.”

Mike ni inu ibanujẹ ni oun wa pe awọn ko ti gbọ nnkan lati ọdọ awọn ijọba sugbọn aworan kan ti ri lori ayelujara fihan pe Francis Sani, ẹni to jẹ alaga ijọba ibilẹ Zangon Kalaf se abẹwo sawọn eeyan to farakasa isẹlẹ naa.

BBC igbinyanju layi kan si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, SP Muhammed Jalige sugbọn ko da ipe wa ati tẹjisẹ wa pada

‘Ohun to ba wa ninu jẹ nipe awọn ẹsọ abo ko gbe igbesẹ kan lori isẹlẹ yii’

aworan

Oríṣun àwòrán, others

Alaga ijọba ibilẹ naa, Franci Sani ni o dun gan pe pẹlu bi ikọlu se n waye ni agbegbe wọn, awọn ẹlẹsọ abo ko fi awọn eeyan ti wọn mu sita fun araaye.

Gẹgẹ bi alaga se sọ, o ni nnkan to bi awọn eeyan ninu ti wọn fi ni ki ijọba wa ko awọn ọmọ ogun kuro ni agbegbe naa niyẹn nitori wọn ko ri isẹ kankan ti wọn se pato lati igba ti wọn ti fi wọn ransẹ si agbegbe naa.

Ni pari, o ni awọn yoo se eto isinku fun gbogbo awọn eeyan to padanu ẹmi wọn lasiko isẹlẹ naa.

Gbájúẹ̀ ọmọ Nàìjíríà, ‘Woodberry ọ̀rẹ́ Hushpuppi’ jẹ́wọ́ ìwà jìbìtì, Amẹ́ríkà yóò gbẹ́sẹ̀lé $8m àti dúkìá míì

Ponle 'Mr Woodberry '

Oríṣun àwòrán, other

Ilumọọka gbajuẹ ọmọ Naijiria kan ti orukọ rẹ n jẹ Ọlalekan Jacob Pọnle, ti inagijẹ rẹ n jẹ Mr Woodberry, ti jẹwọ ẹṣẹ rẹ niwaju awọn alaṣẹ kan nilẹ Amẹrika.

Ponle si ti gba lati jọwọ miliọnu mẹjọ dola lara awọn owo jibiti ayelujara to ri, to fi mọ ọkọ ati aago olowo iyebiye to jẹ dukia rẹ.

Awọn ijọba ilẹ okeere lawọn ibi to ti ṣ’ọṣẹ si ni yoo jogun awọn dukia naa.

Ponle ‘Mr Woodberry ' fẹran ati maa ṣafihan igbe aye ọla to n gbe lori ayelujara Instagram ki ọwọ to tẹ ẹ.

O ti kọkọ sọ fun ile ẹjọ pe, oun ko jẹbi ẹsun mẹjọ ti wọn fi kan an fún ṣiṣe jibiti.

Eyi tumọ si awọn to maa n gbẹburu wọ inu apoti ifiwe ranṣẹ igbalode E-mail lati lu jibiti.

Amọ sa, lẹyin o rẹyin, o tọwọ bọ iwe igbọraeniye mo jẹbi kan, eyi ti wọn fi sọwọ si ile ẹjọ agbegbe kan ni ẹkun ariwa Illinois Eastern Division ni ọjọ kẹfa oṣu kẹrin.

Iwe igbọraẹniye naa lo sọ pe Pọnle ‘Mr Woodberry’ ti tun ọrọ naa ro, o siti gba pe oun jẹbi ọkan lara awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Gẹgẹ bi adehun to tọwọ bọ naa ṣe sọ, ‘Mr Woodberry ' ti gba lati da miliọnu mẹjọ Dollar to fi jibiti gba lọwọ ọkan lara awọn ileeṣẹ meje to ko s’ọwọ jibiti rẹ.

Bakan naa ni wọn tun fi ye Pọnle pe gbogbo awọn dukia olowo iyebiye bii ọkọ, aago ọwọ gbogbo to wa nilu Dubai ni yoo padanu.

Pọnle 'Mr Woodberry '

Oríṣun àwòrán, Instagram/ Woodberry

Lara awọn ọkọ olowo nla naa ni Rolls Royce Cullinan ti nọmba rẹ jẹ J9153, Lamborghini Urus (N4973) ati Mercedes-Benz G-class (G68816)

Lara awọn ọkọ olowo nla naa ni Rolls Royce Cullinan ti nọmba rẹ jẹ J9153, Lamborghini Urus (N4973) ati Mercedes-Benz G-class (G68816).

Awọn dukia miran ti ile ẹjọ tun gbẹsẹle ni ago Rolex merin, ago Patek Philippe kan, ago Audemars Piguet mẹta, yẹrii golu ati okuta iyebiye dayamọndi mẹta pẹlu ẹgba ọrun olomi goolu mẹfa.

Lọdun to kọja, owo igbalode bitcoi ti owo rẹ to miliọnu mẹfa dollar lo padanu fun ìjọba ilẹ Amerika, lara igbesẹ ati gba gbogbo owo ti ọmọ Naijiria naa ti fi Jibiti ko jọ.

Ọjọ kẹwaa oṣu kẹfa ọdun 2020 ni wọn mu Pọnle, toun ti akẹgbẹ rẹ ninu owo jibiti, Ramon Hushpuppi Abbas, to n ṣe ẹwọn ọdun mọkanla bayii fun iwa jibiti ayelura kan naa.

Àkọlé fídíò, Lady Mechanic: Ajayi Oluwatosin ní a kò nílò láti ṣe yẹsà fún ẹnikẹ́ni, ká tó débi gíga