Afipábánilòpọ̀ dáná sun ara rẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó díbọ́n pé òun kú fún ọdún kan, àṣírí tú

aworan Thabo Bester

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹede Tanzania ti fi ogbologbo aṣekupani, afipabanilopọ, ọmọ ilẹ South Africa, Thabo Bester sọko pada lẹyin to parọ pe oun ku si ọgba ẹwọn, to si salọ si orilẹede ila oorun naa.

Bester lọ ti fẹsẹ fẹ fun odidi ọdun kan bayi lẹyin ti ọpọ ro pe o ti jẹ Ọlọrun nipe.

Se lo dana sun ara rẹ ninu ahamọ to wa niluu South Africa, Bloemfontein.

Wọn bẹrẹ si ni maa wa Bester losu to kọja, lẹyin ti iwadi fihan pe oku to jona kii se ti Bester .

Baba gbajugbaju dokita, Zolile Sekeleni ati asọ ọgba ẹwọn ti wọn ti ni ko lọ rọkun nile fun igba diẹ, Senohe Matsoara, ni wọn ti fẹsun isekupani kan ati bi wọn se lẹdi pupọ pẹlu Bester lati salọ.

Tanzania fí afipábánilòpọ̀ Ọmọ ilẹ̀ South Africa sọ̀kọ̀ padà sílè

Bester ni wọn gbe sinu ọkọ baalu pada si orilẹede South Africa lẹyin ti ọwọ tẹ lorilẹede Tanzania lọsẹ to kọja.

Ọrẹbinrin rẹ to jẹ gbajugbaja dokita, Nandipha Magundumana, ẹni ti ọwọ jọ tẹ wọn papọ, naa pẹlu rẹ ti wọn fi sọko pada.

Wọn ti fẹsun kan baba ọmọbinrin naa pe o ran Bester lọwọ lati salọ kuro ni ọgba ẹwọn.

Awọn afurasi mejeeji farahan si ileẹjọ Magistrate ni Bloemfontein saaju ọsẹ yii.

Wọn ti ko fun wọn ni anfani lati sọrọ boya wọn jẹbi tabi wọn ko jẹbi ẹsun naa.

Igbẹjọ naa ni wọn ti sun siwaju di ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹrin.

Eeyan meji miiran ni ọwọ ti tẹ pe wọn lọwọ si bi Bester se sa kuro lọgba ẹwọn.

Bester ni wọn ti gbe lọ ọgba ẹwọn to lagbara julọ ni olu ilu, Pretoria, ti wọn si gbe iyawo rẹ lọ ọgba ẹwọn to wa ni Bloemfontein.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn yoo fi ẹsun ipaniyan, jibiti, ati bo se ran Bester lọwọ kan iyawo rẹ.

Ọwọ tẹ Bester lọdun 2012 fun ẹsun ifipabanilopọ ati isekupani ọrẹbinrin rẹ, Nomfundo Tyhulu.

Afikun yoo de ba ẹsun Bester pẹlu bi o ṣe kuro lọgba ẹwọn.

Bester ni ọpọ si Afipanilopọ ori ayelujara’ fun bi o ṣe fi ayelujara tan awọn obinrin wọle.

Ọwọ tẹ Bester lọdun 2012 fun ẹsun ifipabanilopọ ati isekupani ọrẹbinrin rẹ, Nomfundo Tyhulu.

Lọdun to kọja, ileẹjọ ni jẹbi ifipabanilopọ ati idigunjale to se pẹlu obinrin meji.

Bi Bester se kuro lọgba ẹwọn lo da ọpọlọpọ awuywuye silẹ lorilẹede South Africa , eyi to jẹ ohun lo ni ifipabanilopọ to pọju lagbaye.

Ileeṣẹ to n sakoso ọgba ẹwọn ni ilẹ Gẹẹsi G45 lo n se agbatẹru sisọ ọgba ẹwọn ti Bester ti sa kuro.

Ijọba ti gba isakoso ọgba ẹwọn naa, fun igba ti iwadi bi Bester se sa kuro lọgba ẹwọn yoo fi pari.

Ile igbimọ asofin wa ti ransẹ pe G45 lati yọju si ile gbimọ asofin lori bi Bester se sa kuro lọgba ẹwọn.