Wold Bank fi $800m ta ìjọba Naijiria lọ́rẹ

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari
Ijọba Naijiria ti ri owo ọfẹ ti iye rẹ to $800,000,000 gba lọwọ banki agbaye.
Owo ọhun, ti Naijiria ko ni da pada fun banki agbaye mọ lo wa fun irọrun awọn araalu ṣaaju ki ki ijọba apapọ to yọ owo iranwo ori epo bẹntiro ‘subsidy.’
Inu oṣu Kẹfa ọdun yii ni ijọba Naijiria yoo yọ owo iranwọ ori epo naa gẹgẹ bo ṣe wa ninu eto iṣuna ọdun yii.
Ijọba apapọ ti sọ pe oun yoo pin owo naa fun nnkan bii aadọta miliọnu araalu, tabi fun miliọnu mẹwaa idile ni Naijiria.
Wọn ni awọn idile ti owo naa yoo tọ si jẹ awọn idile ti ko rọwọ họri.
Pinpin owo naa yoo tun ran awọn idilẹ ọhun lọwọ lati koju atubọtan yiyọ owo iranwo ori epo bẹntiro ọhun.
World Bank ti sọ ṣaaju pe niṣe ni eto ọrọ aje Naijiria n fidi wọ nilẹ, nitori naa ko le gbe bukata ida ogoji awọn araalu to n gbe ninu iṣe ati oṣi.
Iye owo ti Naijiria ya sọtọ lati na gẹgẹ bii owo iranwọ ori epo bentiro lọdun yii le ni tiriliọnu mẹta naira, eyii ti yoo dopin ninu oṣu Kẹfa.
Nigeria lo ni epo rọbi to pọ ju nilẹ adulawọ amọ ni ṣe lo ṣi n ko epo wọle lati ilẹ okeere.
Ọpọ awọn onimọ nipa ohun to n lọ lo ti n fun rere pe asiko ti to fun ijọba lati fopin si sisan owo naa nitori iwọnba awọn eeyan perete kan lo n janfani rẹ.












