Tọkọtaya àtàwọn mìíràn wọ gàù fún ẹ̀sùn ìjínigbé, ẹgbẹ́ òkùnkùn ṣíṣé

Oríṣun àwòrán, Ileeṣẹ Ọlọpaa Ekiti
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti kede pe ọwọ ti tẹ awọn afurasi ajinigbe mẹwaa ati awọn meje miiran pẹlu tọkọtaya kan fun ẹsun to jẹmọ ẹgbẹ okunkun sise ati idigunjale.
Awọn afurasi ajinigbe ọhun, ti ọkan lara wọn n jẹ Usman, ẹni ti iwadi ni oun lo siwaju lọ sekọlu si osisẹ Ajọ NSCDC kan, Segun Ayebule, ẹni ti wọn yinbọn pa ni Oke Ako lọdun to kọja.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Sunday Abutu, nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Ado Ekiti lọjọ Isẹgun lasiko ti wọn se afihan awọn afurasi naa ni ọwọ tẹ Usman ninu igbo kan ni Oke Ako ni ijọba ibilẹ Ikole nipinlẹ Ekiti.
Abutu ni tọkọtaya ti orukọ wọn n jẹ, Lateef ati Jumoke ni ọwó tẹ pẹlu afurasi miiran ti orukọ rẹ n jẹ , Ademoye fun bi wọn se jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun, ti wọn si n se agbatẹru bi ija se n waye lemọlemọ laarin ẹgbẹ okunkun Eye ati Aye niluu Ado Ekiti.
“Awọn ọmọ ogun ileeṣẹ ọlọpaa RRS lo kẹfin awọn tọkọtaya, ti wọn si jẹwọ lẹyin ifọrọwerọ pe awọn ma gbe gbogi oloro naa.
“Ninu igbinyanju wa lati fopin si bi ija se n waye laarin awọn ẹgbẹ okunkun Aye ati Eye, ọwọ tun ọkan lara wọn ti orukọ rẹ n jẹ Malik
“Ọpọlọpọ ohun ija ni aka mọ awọn afurasi naa lọwọ, bi ibọn ati ọta ibọn. Lẹyin ọpọlọpọ ifọrọwerọ pẹlu awọn afurasi naa, wọn jẹwọ pe otitọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun.
“Akitiyan ti wa bẹrẹ lati mu awọn yooku wọn laipẹ.”
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì OAU dáwọ́ jọ lu akẹ́kọ̀ọ́jáde pa torí ẹ̀sùn pé ó jí fóònù

Oríṣun àwòrán, Twitter
Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì Obafemi Awolowo University, OAU, Ile-Ife, Okoli Chizoputam, ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn dáwọ́ jọ nà án dójú ikú.
Ẹ̀sùn pé Chizoputam jí fóònù ni wọ́n fi kàn án kí wọ́n tó pa wọ́pọ̀ lù ú.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ, ní Awo Hall nínú ọgbà OAU ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà tí wáyé.
Ìwà lílu akẹ́kọ̀ọ́ pa burú jáì, ó lòdì sí ìwà ọmọlúàbí - Ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́
Àtẹ̀jáde kan tí Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga náà, Folahan Festus fi léde ní, nígbà tí àwọn fi máa gbé Chizoputam dé ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú, ẹ̀mí ti bọ̀ lọ́rùn rẹ̀.
Festus nínú àtẹ̀jáde náà ìwà tí àwọn ènìyàn tó na ọmọkùnrin náà dójú ikú burú jáì tó sì lòdì sí ìwà ọmọlúàbí.
Bákan náà ló ní àwọn yóò ṣe àrídájú rẹ̀ pé ìdájọ́ òdodo wáyé lórí àwọn tó ṣekúpa akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún.
"Ó jẹ́ ohun tó bàwá lọ́kàn jẹ́ láti kéde ikú akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní ìpele karùn-ún sọ́wọ́ àwọn kan tó lù ú dójú ikú."
"À ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn agbófinró láti fi àwọn tó hùwà náà jófin"
"Ìwádìí tí a ṣe fi hàn pé ẹ̀sùn pé ọmọkùnrin náà jí fóònù ni wọ́n fi kàn án kí wọ́n tó lù ú títí ẹ̀mí fi bọ́ lára rẹ̀."
Ó ní àwọn ṣì ń retí èsì ìwádìí látọwọ́ àwọn agbófinró láti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan àmọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà bani lọ́kàn jẹ́ nítorí àwùjọ àwọn ẹ lẹ́kọ̀ọ́ tó ti wáyé.
Bákan náà ló ní ìwádìí àti fífi páńpẹ́ òfin mú àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìwà búburú náà tí ń lọ lọ́wọ́ láti fi wọ́n jó òfin.
Festus tún ṣàlàyé pé àwọn ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ àwọn àtàwọn òṣìṣẹ́ ààbò láti ri dájú pé àwọn fi òfin mú àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ó fi dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà lójú pé iṣẹ́ ń lọ láti wawọ́ irú ìwà bẹ́ẹ̀.
Àwọn aláṣẹ OAU sọ̀rọ̀ lórí ìwà ìpànìyàn yìí
Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ gíga OAU ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ tó ṣokùnfà ikú akẹ́kọ̀ọ́ onípele karùn-ún.
Nínú àtẹ̀jáde tí Agbẹnusọ OAU, Abiodun Olarewaju fi síta ní gíwá àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà,Ọ̀jọ̀gbọ́n Adebayo Simeon Bamire ti gbé ìgbìmọ̀ kan dìde láti wádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Olarewaju ní ìwà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà hù lòdì sí òfin Nàìjíríà àti ti ilé ẹ̀kọ́ náà, tí àwọn sì ti fi tó àwọn ọlọ́pàá létí, ìwádìí sì ti bẹ̀rẹ̀ lórí rẹ̀.
Ó ní ilé ẹ̀kọ́ OAU bá òbí, ẹbí akẹ́kọ̀ọ́ náà kẹ́dùn lórí àdánù ńlá yìí.
Bẹ́ẹ̀ náà ló gbàdúrà kí Ọlọ́run fún àwọn òṣìṣẹ́ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ọkàn akin láti lè fi gba àdánù náà mọ́ra.
Bákan náà ló tún rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti jìnà sí àti máa ṣe ìdájọ́ lọ́wọ́ ara wọn tí wọ́n bá rí nǹkan tí kò bá wọn lára mú.
Ó fi kun pé ó sàn kí wọ́n fi irúfẹ́ ìwà bẹ́ẹ̀ tó àwọn aláṣẹ létí láti gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ lórí nǹkan tí kò bá tẹ́wọn lọ́rùn.
















