Ìdí tí ‘UK Immigration’ fi tàbùkù Peter Obi, kí wọn tó tìí mọ́lé fúngbà díẹ̀

PeterObi

Oríṣun àwòrán, @PeterObi

Oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ oselu Labour, Peter Obi ni awọn osisẹ to n ri si wọle wọde ẹru ati ero nilẹ UK ti yaju si.

Bakan naa, ni wọn tun ti Obi mọle fun igba diẹ, ki wọn to fi silẹ.

Isẹlẹ yii ni wọn lo waye lasiko ti gomina tẹlẹ nipinlẹ Anambra naa tẹkọ leti lọ si London fun ọdun ajinde.

Oludari eto ipolongo fun ibo aarẹ fẹgbẹ oselu Labour, Diran Onifade lo sisọ loju ọrọ yii fawọn akọroyin ninu atẹjade kan to fisita.

Atẹjade naa ni papakọ ofurufu Heathrow to wa nilẹ UK ni isẹlẹ naa ti waye. O fikun pe se ni awọn osisẹ Immigration naa tun gbe oludije sipo aarẹ naa lọ si ahamọ lẹgbẹ kan.

Onifade se ni wọn tun n fi ọrọ wa Peter Obi lẹnu wo, to si dabi ẹni pe eeyan kan ti n dibọn bii Obi nilu London.

"Wọn ni ki Peter Obi yẹba kuro lori ila, ko si bọ sẹgbẹ kan fun ifọrọwanilẹnuwo"

O ni ọpẹlọpẹ bi awọn ọmọ Naijiria to wa ni papakọ ofurufu naa, se dide si isẹlẹ yii, lo gba Obi lọwọ wọn.

Atẹjade naa isẹlẹ yii waye lọjọ Ẹti rere lasiko ti Peter Obi gunlẹ si papakọ ofurufu naa, to si dara pọ mawọn ero to to silẹ fun ayẹwo iwe irinna wọn.

Onifade ni asiko yii ni awọn osisẹ naa gba Peter Obi mu, ti wọn si ni ko yẹba kuro lori ila, ko si bọ sẹgbẹ kan naa fun ifọrọwanilẹnuwo.

Idi ti wọn se fọrọ wa Peter Obi lẹnu wo:

Nigba to n salaye idi ti wọn se fọrọ wa Peter Obi lẹnu wo, Onifade salaye pe ọkunrin kan to n dibọn bii Peter Obi, lo ti huwa ọdaran nilu London.

Bakan naa, o ni afurasi naa tun n huwa jibiti lorisirisi lorukọ Peter Obi.

“Lati igba ti afurasi naa ti salọ, se ni wọn n we oniruuru iwa ọdaran yii mọ oludije sipo aarẹ naa lọrun.

Awọn igbesẹ naa si lo n tabuku Obi atawọn ẹbi rẹ peẹlu awọn Obidients, ti wọn jẹ alatilẹyin rẹ.