Ọwọ́ tẹ àgbẹ̀ tó ṣekúpa 'àwọn tó wá ṣa ìgbín' lóko rẹ̀, Ó ní wọ́n wá ja òun lólè ni

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbẹ oko kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Adegoke ni ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣe afihan rẹ pe o ṣekupa afurasi ole kan.
Yatọ si pe o ṣekupa eeyan naa, ọpọ eeyan lo tun ran lọ si ile iwosan lori pe wọn kọlu oko rẹ to wa ni agbegbe Mile 10 niluu Ọrẹ ni ipinlẹ Ondo.
Awọn eeyan to fara kaasa ikọlu Adegoke lo wa ni ile iwosan bayii nibi ti wọn ti n gba itọju.
Gẹgẹbi ohun ti a ri gbọ, awọn afurasi ole yii ni wọn ti n ji awọn nnkan ọgbin oko agbẹ naa fun ọjọ pipẹ, ti wọn si tun ji ọkada rẹ lawn igba kan sẹyin.
- Ìyá ìjọ kó sí àhamọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tí ìyá àti ọmọ tuntun kú sí ilé ìjọsìn lásìkò ìgbẹ̀bí
- Ìyá àgbà àti ọmọọmọ rẹ̀ mẹ́rin jáde láyé lẹ́yìn tí wọ́n mu ògì nílùú Akure
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin kan tó gún ẹni tó yá a ní N2,000 pa l'Ondo
- Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin SS3 gún akẹgbẹ́ rẹ̀ pa ní ìpínlẹ̀ Ondo
- Ọdún Igogo tí Kábíyèsí Olowo ìlú Owo ti máa ń múra bí obìnrin ní ìrántí Olorì Ọrọnṣẹn gbérasọ l'Ondo
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe oju wọn ti wọn ba awọn akọroyin sọrọ ṣalaye pe o ti pẹ diẹ ti awọn ole ti n da oko Adegoke laamu ṣugbọn ti ko sọrọ sita.
“Adegoke na awọn afurasi yii, ti ọkan ninu wọn si jade laye.”
Nigba ti o n fesi lori iṣẹlẹ naa, alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Funmi Odunlami ni awọn eeyan ti Adegoke ka mọ inu oko rẹ ki i ṣe ole. DSP Ọdunlami ni igbin lawọn eeyan naa wa ṣa ninu oko rẹ.
Odulami ni iyawo Adegoke lo wa sọ fun un pe awọn eeyan kan ti ya wọ inu oko rẹ.
“Kete to gbọ eyi lo sare lọ sinu oko rẹ, to si gbena koju awọn eeyan naa."
ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo sọ pe Iwadii si n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa.















