Ọdún Igogo tí Kábíyèsí Olowo ìlú Owo ti máa ń múra bí obìnrin ní ìrántí Olorì Ọrọnṣẹn gbérasọ l'Ondo

Ilu Owo nipinlẹ Ondo wa ninu pọpọṣinṣin ọdun Igogo bi Kabiyesi Ọlọwọ yoo ṣe jade loni.
Ọdun Igogo to ti le ni ẹgbẹta ọdun jẹ ọkan lara awọn ọdun ibilẹ to gbajumọ julọ nipinlẹ Ondo ati ni iwọ-oorun-guusu orilẹ ede yi.
Ọdun Igogo ni wọn n ṣe ni iranti Ọ̀rọnṣẹ̀n, ti o jẹ arẹwa, ọlọrọ, ati alagbara aya Ọlọwọ Rẹ̀nrẹ̀ngẹnjẹ̀n, ti wọn si wi pe ọpọ ogun ni o ti ọkọ rẹ lẹyin lati bori.
Olori Oronsen jẹ abami eniyan eyi ti Ọlọwọ fẹ ni iyawo pẹlu adehun pe gbogbo awọn olugbe aafin ati Ọlọwọ ko ni ṣe ohun to jẹ eewọ rẹ.
Lara awọn eewọ naa ni pe wọn ko gbọdọ lọ ila tabi da omi si agbala loju rẹ, bẹẹni enikeni to ba n bọ lati oko ko gbọdọ ju iti igi silẹ loju rẹ.
Gbogbo eewọ yi ni Ọlọwọ igba naa se ni alaye fun gbogbo awọn olori pẹlu ileri pe wọn yoo tẹle awọn eewọ náà.
Ṣugbọn owu jijẹ awọn Olori to ku ninu Aafin naa mu ki wọn ṣe lodi si eewo Olori Oronsen lasiko ti Ọba Rerengejen rin irin.
Eyi mu ki Olori naa binu kuro ninu Aafin naa.


Awọn esọ aafin le Oransen de Ugbo Laja nibi ti wọn ti bẹẹ lati pade si Aafin naa sugbọn o fariga ki o to wọ Ugbo Oluwa eyi to jẹ igbo ti eniyan ki n wọ titi di oni.
Oransen fi ọja rẹ silẹ si Ugbo Laja eyi ti awọn esọ naa ko lọ ba Ọlọwọ ti Oransen si fi ìṣe ransẹ pe oun koni pada sinu Aafin naa, amọ, ki wọn ma bọ oun ni ọdọọdun pẹlu ohun elo igba, pẹlu ileri pe oun yoo maa dabo bo ilu Ọwọ.
Wo awọn nnkan to maa n jẹyọ lasiko ọdun Igogo
Lati kopa ninu ọdun Igogo, awọn ọkunrin yio dirun wọn, wọn o si tun wọṣọ obirin pẹlu akun loriṣiriṣi.Wiwe gele ati dide fila, to fimọ ilu lilu pẹlu ibọn yinyin ni ko si igbalaaye fun lakoko ọdun yi, ni bo ṣe jẹ pe agogo nikan ni wọn maa n lu lakoko ọdun Igogo.
Ọba Ajibade Ogunoye ti yio dirun rẹ, ti yio si tun wọṣọ bi obirin pẹlu ọpọlọpọ akun ni yio dari awọn araalu ninu iwọde kaakiri ilu titi de aafin Ọjọmọlúdà ilu Ijẹbu ati awọn aaye to lapẹrẹ laarin ilu.















