Mi ò forúkọ NAFDAC bojú láti ta omi ìyanu - Pásítọ̀ Jeremiah Fufeyin fèsì

Pásítọ̀ Jeremiah Fufeyin

Oríṣun àwòrán, PROPHET JEREMIAH FUFEYIN/NAFDAC/FACEBOOK

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Àlùfáà ìjọ Christ Mercyland Deliverance Ministries, Jeremiah Fufeyin ti sọ pé òun kò máa fi àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ oúnjẹ àti oògùn ìyẹn National Agency for Food and Drug Administration and Control (NAFDAC) tan àwọn aráàlú.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí olórí ìjọ náà fi sórí ayélujára, Àlùfáà Fufeyin ní ìjọ òun kò máa lo nọ́ḿbà àjọ NAFDAC sára àwọn nǹkan ẹ̀mí tó ń pèsè láti fi tu àwọn ará ìlú lójú.

Èyí ló ń wáyé lẹ́yìn tí NAFDAC kéde pé àwọn ń ṣe ìwádìí àwọn ètò ilẹ̀ ìjọsìn náà pé wọ́n ń lo orúkọ àjọ àwọn láti fi máa tàn àwọn ará ìlú.

Adarí àjọ NAFDAC, Mojisola Adeyeye fi sórí ayélujára pé ìjọ tí Àlùfáà Jeremiah Fufeyin ń darí ń pèsè àwọn omi àti ọṣẹ tí wọn kò forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú iléeṣẹ́ àwọn.

Ó ní NAFDAC ti ti àwọn iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń pèsè àwọn omi àti ọṣẹ náà fún ìwádìí tó péye

Ẹ̀ ṣọ́ra fún omi 'ìyanu' àti ọṣẹ ti ṣọ́ọ̀ṣì Christ Mercy Land ń tà, NAFDAC ò fòntẹ̀ lù ú - NAFDAC

Aworan omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ NAFDAC to n mojuto ounjẹ ati oogun lilo ti kilọ fawọn ọmọ orilẹede Naijiria wi pe ki yago fun omi ìyanu àti ọṣẹ ti ijọ Christ Mercy Land Deliverance Ministries labẹ alaṣẹ, Wolii Jeremiah Fufeyin.

Ninu atẹjade kan ti NAFDAC fi sita lọjọ Aiku eyi ti ọga agba ajọ naa, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye buwọlu, ni ajọ naa ṣalaye pe ìjọ naa n lo orukọ NAFDAC lati tan awọn eeyan jẹ lasan ni.

Ajọ NAFDAC ṣalaye ninu atẹjade ọhun pe oniruuru eeyan lo ti kọwe s'awọn lori bi wọn ṣe n kọminu nipa omi ati ọṣẹ t'awọn eeyan n ra lati ijọ naa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

NAFDAC ni wọn n polowo omi naa wi pe o n ṣiṣẹ iwosan ati iyanu.

Ajọ NAFDAC tun sọ ninu atẹjade ọhun pe wolii ijọ naa n sọrọ lori itakun ayelujara wi pe omi ati ọṣẹ iyanu yii le sọ agan di ọlọmọ.

Ajọ NAFDAC sọ ninu atẹjade naa wi pe ounti bẹrẹ iwadii lori omi yii lẹyin tawọn eeyan kan ti kọ iwe ranṣẹ si oun lori rẹ.

‘’Ajọ NAFDAC gbiyanju lati ba ijọ Christ Mercy Land Deliverance Ministries to fi ipinlẹ Delta ṣe ibujokoo sọrọ, amọ, ijọ naa kọ lati ṣiṣẹ pọ pẹlu wa lori iwadii ti a n ṣe.

Gbogbo nkan ti ijọ yii n ṣe ti wọn pe orukọ rẹ ni ‘’Miracle Water ati River Jordan Water” ni ko ni ontẹ NAFDAC lara.

Bakan naa ni NAFDAC ti ti gbe ileeṣẹ to n pese omi to n ṣiṣẹ pẹlu ijọ naa tipa, nigba ti iwadii ṣi n tẹsiwaju.

A wa n rọ awọn araalu wi pe ki wọn yago fun rira omi atawọn nnkan mii ti ajọ NAFDAC ko ba fontẹ lu.

Bakan naa ni a tun rọ awọn ijọ wi pe ki wọn ye nnkan ti ajọ NAFDAC ko ba fontẹ lu,’’ NAFDAC lo sọ bẹẹ ninu atẹjade to fi sita.

Ajọ naa sọ pe oun o ni kaarẹ lori akitiyan oun lati daabo bo eto ilera ọmọ Naijiria.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post