Wo ibi ìsìnkú Alaafin mẹ́rin tó lògbà l’Oyo Igboho níbí tí nǹkan abàmì tí ń ṣẹlẹ̀

Àkọlé fídíò, Ojú oórì Alaafin
Wo ibi ìsìnkú Alaafin mẹ́rin tó lògbà l’Oyo Igboho níbí tí nǹkan abàmì tí ń ṣẹlẹ̀

Igbo Ọba ree niluu Oyo Igboho nipinlẹ Oyo nibi ti wọn sin Alaafin mẹrin to jẹ laye ọjọun si.

Onpitan Oladoja Razaq sọ fun BBC Yoruba wi pe ''kete ti awọn ara Oyo kurọ ni Oyo ile, wọn duro niluu Igboho, ki wọn to morile Oyo Alaafin nibi ti wọn wa bayii.''

Ọgbẹni Oladoja sọ pe Oyo Igboho ni Alaafin mẹrin ti kọkọ lo igba ko to di pe iṣipo pada de lọ si Oyo ile.

Amọ, o ni nigba ti wọn de Oyo ile, atẹgun ibẹ ko ṣe deedee ara wọn.

Onpitan Oladoja fidi rẹ mulẹ pe awọn Alaafin mẹrin ọhun ni Alaafin Ofinran, Alaafin Oropoto Ajiun Arobosete, Alaafin Ajiboyede ati Alaafin Egungun Oju.

O fikun ọrọ rẹ pe ‘’lẹyin igba ti Alaafin Egungun Oju ku, Alaafin karun un ti ko ba jẹ ti ilu yii ko ba fi dagba soke si, ni Tella Abipa tabi Ọba Mọrọ.

Lasiko Alaafin Ajiboyede, gẹgẹ bi itan ṣe sọ, ilu Igboho roju, o si raye, eku n ke bi eku ẹyẹ si n ke bi ẹyẹ nigba rẹ.

Ọgbẹni Oladoja ni awọn ọjọ kan wa to jẹ wi pe awọn nnkan abami maa n ṣẹlẹ ni asiko iyalẹta ni oju oori awọn Alaafin to ti waja yii.

Ẹgbẹni Oladoja ni awọn eeyan ko le rin gbere gbere lagbegbe saare awọn Alaafin yii laye igba kan ki wọn ma fara kaasa.