Wo ẹ̀bùn ńlá tí Saheed Osupa fún Asake Alalubosa ní Ibadan lẹ́yin tó ní ò wu òun láti náwó fún olórin náà

Oríṣun àwòrán, King Saheed Osupa/Facebook
Arabinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Asake Alalubosa ni o ma gba alejo to ya lẹnu, alejo naa si fi ẹrin si ẹnu rẹ.
Asake ninu ifọrọwerọ kan to se eyi to gba ori ayelujara kan, ṣalaye pe o wu oun ki oun na owo oun fun ilumọka olorin Fuji, Saheed Osupa sugbọn oun ko ti ni iru owo bẹ.
Asake Alalubosa n kọrin Saheed Osupa ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu Ayo Adam, akọroyin niluu Ibadan.
Ko pe ọṣẹ kan ti ifọrọwerọ naa jade ni iroyin naa de ọdọ Saheed Osupa, to si pinnu lati se abẹwọ si arabinrin ninu ọja Oje niluu Ibadan.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ninu fọnran kan to wa loju opo ayelujara Saheed Osupa, nibi to ti lọ se abẹwo si Asake Alalubosa lati fi ẹmi more han si i bi o ṣe nifẹ si orin rẹ.
“Ọmọbinrin Asake Alalubosa ni bi o ṣe fi ifẹ han si orin mi ati emi gan an dun mọ mi ninu pupọ, lia sọ ani ani, ẹ ti ma ri pe ololufẹ Osupa ni arabinrin yii.
“Awọn ọrọ to sọ ninu ifọrọwerọ naa pa mi lẹrin pupọ, paapa eyi to ni, ‘Mo jẹ Saheed Osupa lowo, emi kini buruku yii ma na owo fun Saheed Osupa ti mo ba ni owo.
“Mo lọ si sọọbu rẹ ninu ọja Oje niluu Ibadan, mo ya lẹnu, ti mo fi owo ta lọrẹ
“Asake jẹ ọkan ninu awọn ọpọ eeyan to jẹ ololufẹ mi ti wọn ṣetan lati gbogbo owo wọn lati gbe orinyin fun orin mi.”















