Iléeṣé ológun sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn tó ní ọ̀pọ̀ ọmogun Nàìjíríà ń kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ torí àìrí ìtọ́jú

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/X
Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà ti sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn kan pé àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ ń fi iṣẹ́ sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí ìwà àjẹbánu, àìsí ìpèsè ohun èlò iṣẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àtẹ̀jáde kan tí agbenusọ iléeṣẹ́ ológun, Ọ̀gágun Onyema Nwachukwu fi léde ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà àti pé wọ́n fẹ́ fi ìròyìn náà da rúgúdù sílẹ̀ ni.
Nwachukwu nínú àtẹ̀jáde náà tẹmpẹlẹmọ pé àwọn ọmọ ogun le fi iṣẹ́ sílẹ̀, tí iléeṣẹ́ ológun náà sì ní àṣẹ láti yọ ènìyàn níṣẹ́ níwọ̀n ìgbà tí tó ti wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin àti ìlànà tó dé iṣẹ́ àwọn.
Ó ní kìí ṣe òótọ́ rárá pé àwọn òṣìṣẹ́ ń fi iṣẹ́ sílẹ̀ nítorí àwọn kò pèsè kóríyá àti ohun èlò to yẹ fún wọn.
Ó sọ pé àwọn tó ń gbé ìròyìn náà mọ̀ọ́mọ̀ fẹ́ bá iléeṣẹ́ ológun ní orúkọ jẹ́.
Ó ṣàlàyé pé, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà káàkiri àgbáyé, iṣẹ́ ológun jẹ́ iṣẹ́ tí àwọn máa ń fi ìfẹ́ ṣe ni, èyí tó fi ààyè gba ológun láti fi iṣẹ́ sílẹ̀ nígbà tó bá wù wọ́n.
“Àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ ológun ní àǹfàní láti fi iṣẹ́ sílẹ̀ nígbà tó bá wù wọ́n tí wọ́n bá ti tẹ̀lé ìlànà àti òfin Harmonized Terms and Condition of Service.”
Agbẹnusọ náà tẹ̀síwájú pé iléeṣẹ́ ológun tún máa ń ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn òṣìṣẹ́ láti ìgbà dé ìgbà tí wọ́n sì máa ń lé àwọn òṣìṣẹ́ kan lẹ́nu iṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà òfin.
Ó ní èyí ló máa ń mú àwọn lẹ orúkọ àwọn ọmọ ogun tí yóò kúrò lẹ́nu iṣẹ́ láti fún wọn ní ààyè àti àsìkò láti gba àwọn nǹkan tí wọ́n ní ẹ̀tọ́ sí bíi owó àjẹmọ́nú, owó ìfẹ̀yìntì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Nwachukwu sọ pé lára nǹkan tó máa ń mú àwọn lé òṣìṣẹ́ fi iṣẹ́ sílẹ̀ ni ipo ìlera irú òṣìṣẹ́ bẹ́ẹ̀ tàbí tí wọ́n bá gbèrò láti lọ ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí ológun àtàwọn nǹkan míì.
Ó bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn iléeṣẹ́ tí wọ́n ń kọ ìròyìn láì ṣe ìwádìí tí àwọn òṣìṣẹ́ náà fi fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀, kí wọ́n tó má a kọ ọ́ pé iléeṣẹ́ ológun ni kò pèsè àwọn nǹkan tó yẹ fáwọn òṣìṣẹ́.
Ó fi kún ọ̀rọ̀ pé láti ìgbà tí ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun, Taoreed Lagbaja ti gba ipò ni ìlọsíwájú tún ti ń bá iléeṣẹ́ ológun, tí àwọn ń gba àjẹmọ́nú àwọn déédéé, mú ìgbáyégbádùn àwọn òṣìṣẹ́ àti ẹbí wọn ní òkúnkúndùn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















