Mọ̀ nípa àwọn ìlànà tí àgùnbánirọ̀ nílò láti tẹ̀lé fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ stream C batch 1

Àwọn àgùnbánirọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn àgùnbánirọ̀ ní Nàìjíríà, NYSC ti fi léde pé ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kọkànlá ọdún 2024 ni àwọn yóò máa ṣí ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn ìsín “batch C stream 1” àwọn tó fẹ́ sin ilẹ̀ baba wọn.

Ṣíṣe Àgùnbánirọ̀, ìyẹn sínsin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fún ọdún kan gbáko pọn dandan ní Nàìjíríà fún gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ tó bá kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ilé ẹ̀kọ́ gíga kódà bí onítọ̀hún bá kàwé nílẹ̀ òkèrè.

Àmọ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí kò bá ì tíì pé ọgbọ̀n ọdún lásìkò tó bá ṣetán ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ni ètò náà pọn dandan fún.

Ètò sínsin ilẹ̀ baba ẹni wáyé lọ́dún 1973 ní ìrètí láti mú ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn ọmọ Nàìjíríà nípa gbígbé èèyàn lọ sí ìpínlẹ̀ tó jìnà sí agbègbè rẹ̀.

Èyí máa ń ṣokùnfà kíkọ́ ṣe nípa àwọn ẹ̀yà mìíràn àti mímọ̀ nípa àṣà tó yàtọ̀ sí tẹni.

Ṣùgbọ́n láti bíi ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, tí ètò ààbò Nàìjíríà ti mẹ́hẹ ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kìí fẹ́ lọ sí ọ̀nà jíjìn nítorí ààbò ẹ̀mí àti dúkìá wọn.

Ní báyìí tí NYSC ti kéde ṣíṣí ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún sáà yìí, wọ́n gba àwọn àgùnbánirọ̀ lámọ̀ràn lójúnà àti lè mú kí ètò náà lọ nírọ̀rùn.

Àwọn ìgbésẹ̀ tí NYSC là kalẹ̀ fáwọn àgùnbánirọ̀ nìyí:

Àjọ NYSC nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi sórí ìkànnì X wọn lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kọkànlá ni:

  • Káwọn àgùnbánirọ̀ má ṣe rìn ìrìnàjò alẹ́ lọ sí ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wọn. Wọ́n ní tí ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà bá jìnà, kí àgùnbánirọ̀ bẹ́ẹ̀ wá ọ̀nà láti pín ìrìnàjò rẹ̀ tí yóò fi dé ibùdó náà lójú mọmọ.
  • Kí àwọn àgùnbánirọ̀ ri dájú pé wọ́n dé ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní ìgbà tí wọ́n dá fún wọn láti débẹ̀.
  • Ṣe àyẹ̀wò orúkọ wọn dáadáa lórí ìkànnì ìtàkùn àgbáyé wọn láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó wà bó ṣe yẹ.
  • Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣe ìforúkọsílẹ̀ tán ní ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́, wọn kò le ṣe àyípadà kankan lórí ọjọ́ ìbí, ọdún tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ jáde, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àti àwòrán mọ́.
  • Bákan náà ni wọ́n ní akẹ́kọ̀ọ́ tí àìṣedédé bá wà nínú nǹkan tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè lé lórí àti ohun tí NYSC fi léde kò gbọdọ̀ lọ sí ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Irú ẹni bẹẹ nílò láti lọ yanjú àwọn kùdìẹ̀kudiẹ náà ní ilé ẹ̀kọ́ tó ti jáde.
  • Àwọn obìnrin tó bá ti wà nílé ọkọ, tí wọ́n gbé lọ sí ìpínlẹ̀ tó yàtọ̀ sí ibi tí ọkọ wọn wà nílò láti kó àwọn ìwé ẹ̀rí láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ti ṣe ìgbéyàwó dání, kí wọ́n fi dá wọn padà sí ìpínlẹ̀ ọkọ wọn.
Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post