Iléeṣẹ́ ìfọpo Dangote dín iye owó lítà epo kù fún àwọn alágbàtà

Oríṣun àwòrán, Dangote
Ileeṣẹ ifọpo Dangote ti kede padinku iye owo jala epo bẹntiro fun awọn alagbata.
Dangote lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjde kan loju opo X rẹ lọsan an ọjọ Aiku.
Atẹjade naa sọ pe jala epo ti wọn n ta ni ₦990 tẹlẹ ti dinkun si ₦970 bayii.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa to buwọlu atẹjade ọhun, Anthony Chiejina, sọ pe awọn dupẹ pupọ lọwọ awọn ọmọ Naiiria fun atilẹyin wọn lati mu ala ileeṣẹ ifọpo naa ṣe.
O ni “Ileeṣẹ ifọpo Dangote ti din iye owo epo bẹntiro ku lati ₦990 si ₦970 fun awọn alagbata.

Oríṣun àwòrán, Dangote
“Bi ọdun ṣe n lọ sopin, eyii jẹ ọna lati fi ẹmi imoore han si awọn ọmọ Naiijiria fun atilẹyin wọn lati mu ki ala wa le wa si imuṣẹ.”
Anthony tun dupẹ lọwọ ijọba apapọ fun atilẹyin rẹ fun ileeṣẹ ọhun.
O fi kun pe ileeṣẹ naa yoo tẹsiwaju lati maa pese ojulowo epo bẹntiro fun awọn ọmọ Naijiria.
O pari ọrọ rẹ pe awọn n ṣiṣe takuntakun lati ri daju pe awọn pese epo lọpọ yanturu fun araalu ki wọn le maa ri epo naa ra loorekoore.















