Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin kan tó gún ẹni tó yá a ní N2,000 pa l'Ondo

Aworan Afurasi ni ahamọ

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ ọkunrin kan, Monday Chukwu, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn to gun Kefa Ofando, ẹni ọgbọn ọdun pa ni abule Akintola nijọba Ibilẹ Odigbo nipinlẹ Ondo.

Afunrasi naa lo ya owo ti iye rẹ jẹ ẹgbẹrun meji naira lọwọ oloogbe naa, ti oloogbe naa si bere owo rẹ pada eyi to yọri si ariyanjiyan ti Monday si fi alumọgaji (Scissors) gun oloogbe na pa lasiko ariyanjiyan naa.

Iṣẹlẹ naa to waye ni ogunjọ osu kẹsan an ọdun 2024 ti fa ibẹrubojo ni agbegbe naa ti afunrasi Monday Chukwu si na papa bora ni kete ti iṣẹlẹ naa waye.

Lasiko to n foju ọdaran naa ati awọn miran lede ni olu ileeṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Ondo, Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa, Abayomi Oladipo ni kete ti awọn ikọ ileeṣẹ ọlọpaa de oriko ti iṣẹlẹ naa ti waye, wọn ri Scissor ti afunrasi naa fi sekupa oloogbe.

Kọmisana sọ pe wọn mu Scissors naa lọ sọdọ Dokita fun ayẹwo to si fidi rẹ mulẹ pe Scissors naa ni wọn fi sekupa Ofando.

Oga agba olo tun sọ di mimọ pe lẹyin ọpọlọpọ iwadi, ọwọ ti tẹ afurasi naa, ti yoo si foju ba ile-ejọ ni kete ti wọn ba pari awọn iwadi.

Bakan naa, Kọmisana ọlọpaa tun ṣafihan awọn afunrasi ọdaran mejila mii to fi mọ ọkan lara awọn to sekupa gbajugbaja alasẹ arabinrin Adeni Iyabode n'ilu Akure.

Ọdọmọkunrin naa Kolawole Precious ni o jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun lo jẹwọ pe oun ko mọ ohun to ba le oun lati kopa ninu iwa ibi naa.

" Emi kọ lo da ba pe ki a pa obinrin naa, ọmọ to n ba obinrin naa sise lo gbogun ti mi pe ka pa ọga oun ti mo si gbọran si lenu"

Saaju ni awọn ọlọpaa ti kọkọ mu ọkan lara awọn afunrasi naa Philip Emmanuel, ẹni ọdun mẹtadinlogun, to jẹ ẹni to n ṣiṣẹ pelu oloogbe naa.

Kọmisana Abayomi Oladipo sọ pe awọn miran ti ọwọ ofin tẹ naa ni Ujukene Uzoma, 32, n'ilu Arogbo nijọba ibilẹ Ẹsẹ-Odo.

Ifeanyi Chukuemeka, 36, Joseph Agu, 43 wọn jẹ ole to ma n ji awọn ẹya ara ọkọ ati Obinna Onyeamadu, 32, to fi mọ Onyeka Okoye, 38.