Ìyá àgbà àti ọmọọmọ rẹ̀ mẹ́rin jáde láyé lẹ́yìn tí wọ́n mu ògì nílùú Akure

Posi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bàbá àwọn ọmọ mẹ́ta nínú àwọn ọmọ mẹ́rin to jáde láyé lẹ́yìn tí wọ́n mu ògì, ti rọ ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo láti ṣèwádìí ikú àwọn ọmọ náà.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló wáyé ní òpópónà Gaga, Oke Aro, Akure, ìpínlẹ̀ Ondo níbi tí ìyá àgbà àtàwọn ọmọọmọ rẹ̀ mẹ́rin ti jáde láyé lẹ́yìn tí wọ́n mu ògì.

Ìròyìn ní ìyá náà, Esther Adeola àtàwọn ọmọ náà jáde láyé ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

Ìyá àgbà ọ̀hún ni wọ́n ní ó kọ́kọ́ jáde láyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, kí àwọn ọmọ náà tó jáde láyé lọ́jọ́ Àìkú lẹ́yìn tí wọ́n ń bí, tí wọ́n sì ní inú ń dun àwọn.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Ọ̀gbẹ́ni Ademola ṣàlàyé bí àwọn rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ si ní ṣe àárẹ̀ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta lẹ́yìn tí wọ́n mu ẹ̀kọ náà tán.

Ó ní èyí ló mú òun kó àwọn ọmọ ọ̀hún lọ sí ilé ìwòsàn University of Medical Sciences Teaching Hospital (UNIMEDTH), Akure àmọ́ tí ìgbìyànjú àwọn kò so èso rere.

Ó ṣàlàyé pé nígbà tí òun dé ilé ìwòsàn náà, àwọn dókítà tí òun bá kò mọ nǹkan tó yẹ kí wọ́n ṣe, tí wọ́n sì sọ fún òun láti fún àwọn ọmọ náà lépo pupa mu.

Ademola sọ pé ọ̀kan lára àwọn dókítà náà ní àwọn kò mọ oògùn tí àwọn máa lò fún àwọn ọmọ náà.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“Mo gbọ́ tí ọ̀kan lára àwọn dókítà náà sọ pé mi ò mọ nǹkan tí mà á fún wọn, ó ti sú mi.

“Lẹ́yìn náà ni wọ́n lo àwọn oògùn kan tí mo gbàgbọ́ pé òun ló ṣe okùnfà ikú àwọn ọmọ náà.”

Ó ṣàlàyé pé lẹ́yìn tí àwọn fún àwọn ọmọ náà ní epo mu ni àárẹ̀ tún lágbára si táwọn sì tún gbé wọn lọ sílé ìwòsàn mìíràn.

Ó ní ilé ìwòsàn aládàni tí àwọn gbé wọn lọ ni ara wọn ti balẹ̀ díẹ̀ àmọ́ tí ilé ìwòsàn náà tún dá àwọn padà sí UNIMEDTH nítorí pé wọn kò ní àwọn irinṣẹ́ láti fi tọ́jú wọn.

“Nígbà tí a padà sí UNIMEDTH ni dókítà kan fún wọn ní abẹ́rẹ́ kan tó sì mú kí àárẹ̀ wọn tún pọ̀ si kí wọ́n tó jáde láyé.”

Ó di ẹ̀bi ikú àwọn ọmọ náà ru àwọn dókítà náà pé wọn kò kájú òṣùwọ̀n rárá.

Ó bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn UNIMEDTH fún bí wọ́n ṣe fi ọwọ́ jábútẹ́ mú ìtọ́jú àwọn ọmọ náà tí ẹ̀mí fi bọ́ lára wọn.

Ademola wá rọ ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo láti gbé ìgbìmọ̀ tí yóò ṣe ìwádìí ikú àwọn ọmọ náà dìde láti fìdí ohun tó ṣokùnfà ikú wọn múlẹ̀.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Kọmíṣọ́nà fún ètò ìlera ìpínlẹ̀ Ondo, Dókítà Banji Alaka ní àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn UNIMEDTH kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìtọ́jú àwọn ọmọ náà gẹ́gẹ́ bí bàbá wọn ṣe fẹ̀sùn kàn.

Alaka ní àwọn dókítà tó fi mọ́ àwọn àgbà dókítà mẹ́rin ló gbìyànjú láti dóòlà ẹ̀mí àwọn ọmọ náà àmọ́ gbogbo ìgbìyànjú wọn já sí pàbó.

Ó ní ilé ìwòsàn náà ní àwọn irinṣẹ́ láti fi tọ́jú àwọn ọmọ ọ̀hún ṣùgbọ́n ó ṣeni láàánú pé wọ́n jáde láyé.

Ó gbàdúrà kí Ọlọ́run tu àwọn ẹbí wọn nínú láti gba àdánù náà.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ondo, Funmilayo Odunlami ní wọn kò fi ọ̀rọ̀ náà tó iléeṣẹ́ ọlọ́pàá létí àmọ́ àwọn ti ṣe àbẹ̀wò sí ilé náà láti mọ nǹkan tó ṣẹlẹ̀.

Àwọn ọmọ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àti ìyá àgbà náà ni wọ́n ti sin sílé wọn.