NDLEA sọ̀rọ̀ lórí ìlànà rẹ̀ tó ní ọkọ gbọ́dọ̀ kọ lẹ́tà ìyọ̀nda fún ìyàwó tó bá fẹ́ rìnrìn àjò

Iroyin kan to jade l’Ọjọbọ lo sọ pe awọn iyawo ile to ba fẹ rinrin ajo lọ si ilẹ okeere lati orilẹede Naijiria gbọdọ maa gbaṣẹ bayii lọwọ ọkọ wọn.
Iroyin naa fidi rẹ mulẹ wi pe ajọ NDLEA to n gbogun ti lilo ati fifi oogun oloro ṣe kata-kara ni Naijiria lo gbe ilana yii kalẹ fawọn obinrin to ti ṣe igbeyawo.
Iroyin naa sọ pe gbigba aṣẹ lọwọ awọn ọkọ wọn jẹ ọkan lara amuyẹ fawọn iyawo ti wọn ba fẹ rinrin ajo lọ silẹ okeere lati le ri fisa gba.
Yatọ si gbigba aṣẹ lọwọ ọkọ wọn, awọn iyawo ile yii tun gbọdọ fi fọto wọn ranṣẹ si ajọ NDLEA.
Ọrọ yii si ti fa awuyewuye lori ayelujara lati igba ti iroyin naa ti jade.
Ajọ NDLEA sọrọ lori iroyin to lawọn iyawo to ba fẹ japa gbọdọ gbaṣẹ lọwọ ọkọ wọn
Ajọ NDLEA ti ṣalaye pe loootọ ni atunṣe n lọ lọwọ lori alakalẹ ti ajọ naa maa n tẹle fun ayẹwo awọn iyawo to ba fẹ gba fisa rinrin ajo lọ silẹ okeere lati Naijiria.
Amọ ajọ naa ti sọ wi pe awọn ti yọ alakalẹ to ni awọn iyawo to ba fẹ rinrin ajo lọ si ilẹ okeere gbọdọ gba iwe aṣẹ lọwọ ọkọ wọn kuro ninu awọn amuyẹ ti NDLEA maa n wo lasiko ayẹwo ti wọn maa n ṣe fawọn iyawo ile to fẹ ba japa.
Ajọ naa ṣalaye pe alakalẹ to ni kawọn obinrin maa gbaṣẹ lọwọ ọkọ wọn waye nitori awọn iṣẹlẹ kan ti ko ṣee gbọ leti to ti ṣẹlẹ ṣaaju lawọn orilẹede ilẹ okeere kan.
Ajọ NDLEA wa lo anfaani yii lati sọ fun araalu wi pe awọn ti ṣe ayọkuro alakalẹ naa eyi to fa awuyewuye lori ayelujara l’Ọjọbọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















