Lóòtọ́ Nàìjíríà ń pa owó wọlé lásìkò yìí, àmọ́ṣá a ṣì nílò láti yáwó síi - Wale Edun, Mínísítà fún ìṣúná

Aworan Wale Edun

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Minisita fun eto isuna lorilẹede Naijiria, Wale Edun ni ijọba Naijiria si nilo lati ya owo se awọn iṣẹ akanṣe kan pẹlu bi o ṣe jẹ pe alekun ti ba owo ti awọn ẹka ijọba n pa.

O sọ eyi lasiko to n sọrọ nibi ipade pẹlu awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin agba.

Gẹgẹ bi o ṣe ti sọ, o ni owo ti wọn fẹ ya ni yoo ni ipa rere ti ile igbimọ ba le buwọlu pe ki wọn ya owo kun owo eto isuna.

“Alekun ba owo ti a n pa wọle ṣugbọn a ni lati se dada si, ti a si nilo lati ya owo ti yoo nipa nla fun eto ọrọ aje Naijiria.

“Ki i se fun iṣẹ akanṣe nikan ṣugbọn fun igbaye gbadun araalu, eto ilera, eto ẹkọ ati awọn nnkan ti yoo se araalu ni anfani.”

Nigba ti oun naa n sọrọ, Minisita to n risi sise eto isuna, Sẹnetọ Atiku Bugudu ni ijọba nilo lati ya owo l;ati fi kun owo eto isuna paapa ni awọn ẹka lati pese fun araala.

“A ni erongba ọjọ pipẹ fun ọdun 2050, ti yoo mu alekun ba GDP,

Ti ijọba ba mọ ohun ti wọn ṣe, wọn ko nilo lati yawo- EFCC

Ẹwẹ, ajọ to n gbe ogun ti iwa ibajẹ EFCC ati ajọ to n pawo wọle fun ijọna ni awọn gbagbọ pe ti ijọba ba mọ ohun ti wọn ṣe , wọn ko nilo lati yawo lati fi kun eto isuna.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alaga EFCC, Ola Olukoyede sọ fun awọn amofin pe ajọ EFCC ti gba owo toto N197 bilọnu naira lati ibẹrẹ ọdun 2024, to si jẹ ko di mimọ pe ti ijọba ba le sisẹ karakara, orilẹede ni owo lati fi kun owo eto isuna.

Bakan naa alaga ajọ to n sọ ẹnu ibode, Custom, Bashir Adeniyi, ninu alaye rẹ ni Custom ti pa owo toto N6.382 ni ọdun 2024.

Ẹka NNPCL ati FIRS naa ṣalaye iye owo ti wọn ti pa wọle ni ọdun 2024.

Ni ọjọbọ ọsẹ to koja ni ile igbimọ aṣofin agba buwọlu ibeere Aarẹ Bola Tinubu lati ya owo.

Igbakeji aarẹ ile igbimọ aṣofin, Barau Jibrin lo buwọlu owo yiya naa lẹyin Sẹnetọ Wammako Magatarkada jabọ fun ile lori iwadii ti oun ati awọn akẹgbẹ rẹ se.

Ọrọ owo yiya lo ti fa ariwo kaakiri orilẹede Naijiria, ti ọpọ awọn araalu si ti bu ẹnu atẹlu igbesẹ naa.

Igbakeji aarẹ tẹlẹri ati oludije sipo aarẹ labẹ aisa ẹgbẹ oṣelu APC, Atiku Abubakar ṣapejuwe owo yiya gẹgẹ bii eyi to kan eegun araalu.

Atiku ni owo yiya naa ko se anfani kankan fun awọn ọmọ Naijiria.