Ọ̀gá Àgbà Iléèṣẹ́ NNPCL, Mele Kyari pàdánù ọmọ rẹ̀ obìnrin

Oríṣun àwòrán, Others
Ọga Agba ileeṣẹ NNPCL, Mele Kyari, ti padanu ọmọ rẹ obinrin.
Iroyin sọ pe ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa, ni ọdọmọbinrin naa ku lẹni ọdun marundinlọgbọn.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ NNPCL fi sita ni oju opo Instagram wọn ni alẹ ọjọ Ẹti, ni wọn ti kede pe Aarẹ Bola Tinubu, ba Kyari kẹdun iku ọmọ ọhun.
Bakan naa ni atẹjade naa fidi rẹ mulẹ pe Fatimah ku lẹyin ti ṣe aisan fun igba pipẹ.
Wọn ti sin oku rẹ niluu Abuja, ni ibamu pẹlu ilana ẹsin Isilaamu.
Lara awọn to peju si ibi isinku naa lati ba ẹbi Kyari kẹdun, gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria, ṣe sọ ni igbakeji aarẹ, Kashim Shettima.
Agbẹnusọ fun Aarẹ Tinubu, Bayo Onanuga, sọ ninu atẹjade pe aarẹ ba ẹbi Ọga Agba ileeṣẹ NNPCL kẹdun iku ọmọ wọn.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post








