Òpópónà Ogbomoso: 'Pàkúté ikú fáwọn arìnrìnàjò'

Ọkọ̀ ńlá tó dánú
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Niṣe ni awọn eeyan ilu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo ti n rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ naa ati ijọba apapọ lati tete wa ojutuu si awọn ọna igboro to la ilu naa kọja.

Arọwa yii lo n waye lẹyin ti awọn eeyan ilu naa ko ri ọna gba kọja mọ latari bi awọn ọkọ nla to n ṣe irinajo gba ilu naa kọja ṣe maa n danu sawọn opopona naa to si maa n fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.

Sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ yii lo maa n fun ọjọ meji si mẹta lọpọ igba, tawọn arinrinajo ko si ni ri ọna gba kọja bo ṣe yẹ.

Ni kete ti eeyan ba ti n wọ igboro ilu Ogbomoso lati ilu Oyo ni yoo ti maa kan sunkẹrẹ fakẹrẹ naa ni ọpọ ọna ti o kọja ni igboro Ogbomoso lo ti di panpe iku eyi ti awọn ara ilu si n ke gbajare si ijọba apapọ ati ti ipinlẹ Oyo lati wa nnkan ṣe ni kiakia.

Awọn ọna lo so guusu iwọ oorun Naijiria papọ pẹlu ariwa.

Òpópónà tí kò dára
Ọna ti ko dara

Irinajo ti ko yẹ ko gba eeyan ju ogoji iṣẹju lati Oyo de Ogbomoso ti wa di ohun ti awọn arinrinajo n lo ọjọ meji si mẹta loju ọna nitori ipo ti ọna naa wa.

Iwadii fi han pe idawọduro akanṣe iṣẹ ọna Marosẹ (new express) ilu Oyo si Ogbomoso ti agbaṣẹṣe dawọ rẹ duro wa lara nnkan to n fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọhun.

Bakan naa ni ọna atijọ tawọn ọlọkọ n ṣamulo rẹ ko fẹ to bẹẹ pẹlu bi awọn ọkọ nlanla ṣe n gba ibẹ, to si n ṣokunfa ki ọna naa maa di ni ọpọlọpọ igba paapaa julọ lati bii oṣu mẹta sẹyin.

Awọn olugbe ati arinrinajo to n gba ilu Ogbomoso kọja ni wọn n rawọ ẹbẹ ijọba lati ṣe atunṣe awọn ọna yii paapaa ni agbegbe Caretaker, Seminary, Apake ati Sabo.

Ipo ti ọna naa wa ti ṣokunfa ijamba ọkọ eyi ti o ti fa iku ojiji fun ọpọlọpọ eeyan.

Awọn awakọ nla ti o ba oniroyin sọrọ jẹ ko di mimọ wi pe aimọye igba ni awọn maa n lo to ọjọ mẹta si marun-un laaarin Ogbomoso nigba ti ọna ba di ti ko si si ọna miiran lati gba fawọn lati tẹsiwaju ninu irinajo awọn.

Ọpọ awọn ounjẹ ti wọn maa n ko wọ ipinlẹ Eko lati ariwa orilẹ ede Naijiria ni wọn maa n gba ọna yii kọja nitori ko si ibomiran ti wọn le gba.

Sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ
Ọna ti wọn pati