"Ọ̀pọ lára èèyàn 153 tó kú níbí ìbúgbàmú tánkà agbépo la ti sín síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà"

Awọn eeyan to padanu ẹmi wọn ninu ibugbamu tanka agbepo to ṣẹlẹ nipinlẹ Jigawa ti pe 153 bayii.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Jigawa, DSP Lawan Shiisu Adam, lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC Pidgin.
DSP Adam ṣalaye wi pe eeyan bi ọgọrun un to farapa nibi iṣẹlẹ ọhun ti n gba itọju bayii nile iwosan Aminu Kano to wa ni Jahun, ati ile iwosan to wa niluu Nguru, Hadejia ati ni Gumel.
Eto isinku ti waye fun ọpọ ninu awọn to ku nibi iṣẹlẹ naa, lẹgbẹ ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye ni wọn sin awọn eeyan naa si.
Ni nnkan bi ago mọkanla abọ lalẹ ọjọ Iṣẹgun ni ijamba ọhun ṣẹlẹ nigba ti tanka agbepo kan to n bọ lati ilu Kano n lọ Nguru nipinlẹ Yobe ṣubu.
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, nigba ti ọkọ naa de ilu Majiya ni ijọba ibilẹ Taura nipinlẹ Jigawa ni awakọ nla naa ko le dari tanka ọhun mọ ti ijamba naa fi ṣẹlẹ.
Awakọ tanka naa to moribọ ti wa ni ahamọ ọlọpaa
Lẹyin ti tanka naa ṣubu tan ni epo inu rẹ jo danu sori titi tawọn eeyan si bẹrẹ si ni gbọn epo ti tanka naa si bu gbamu lẹẹkan naa.
DSP Lawan sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn ẹṣọ eleto abo gbiyanju lati ma jẹ kawọn eeyan gbọn epo nibi iṣẹlẹ ọhun, amọ o ni awọn eeyan naa pọju awọn agbofinro to ba nibẹ lọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa tun fidi rẹ mulẹ pe awakọ tanka naa moribọ, o si salọ lẹyin ti tirela ọhun ṣubu tan.


Oríṣun àwòrán, FRSC
Ọwọ ọlọpaa ti tẹ awakọ naa, o si ti wa ni ahamọ, nigba tawọn ọlọpaa si ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.
Fọto ati fidio iṣẹlẹ naa tawọn eeyan n pin lori ayelujara ṣafihan bi ọpọ eeyan ṣe jona ti ẹnikẹni ko si le da wọn mọ.
Ewe ni wọn ja bo oku awọn eeyan to ti jona nibi iṣẹlẹ naa.
Ijamba ina tanka agbepo wọpọ lorilẹede Naijiria, o maa n ṣẹlẹ nigba mii latari ọna ti ko dara.
Eeyan mọkandinlọgọta lo ku ninu ijamba ọkọ tanka agbepo to kọlu ọkọ akero kan to tun ko maalu nipinlẹ Niger loṣu Kẹsan an to kọja lọ.
"Epo tí wọn ń gbọ́n lára Tírélà tó dànù ló fa ìbúgbànú iná tó pa èèyàn 147, tí 100 míì sì farapa"

Ọkọ agbepo kan to gbina ti ṣekupa ọgọrun eeyan nipinlẹ Jigawa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Lawan Shiisu Adam, lo fidi iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin nibi to ti sọ pe ko din ni eeyan mẹtadinlaadọjọ to jade laye.
O fikun pe eeyan bii ọgọrun mii lo tun farapa nibi iṣẹlẹ naa to waye lalẹ ọjọ Iṣẹgun naa.

Oríṣun àwòrán, FRSC
"Bi epo naa ṣe danu lawọn araalu yabo ibẹ lati bẹrẹ si gbọn epo ọhun, ti ina si sọ eyi to jo ọpọ eeyan"
Adari ajọ ẹṣọ oju popo ipinlẹ naa, Aishatu Sa'adu sọ fun BBC pe ilu Majia, ni ijọba ibilẹ Taura ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Sa'adu ṣalaye pe ṣe ni awakọ epo ọhun gbiyanju lati ya fun ọkọ mii to ko tomato.
Ibi ti awakọ agbepo naa ti n ṣe eyii ni ori ọkọ rẹ fo yọ kuro lara rẹ, ti epo to gbe si danu si aarin oju popo.
Alukoro ọlọpaa sọ pe ni kete ti epo naa danu lawọn araalu yabo ibẹ lati bẹrẹ si n gbọn epo ọhun amọ awọn agbofinro gbiyanju lati le awọn araalu naa nitori ina to le ṣẹyọ.
Lẹyinorẹyin, ina sọ lara epo ti awọn eeyan n gbọn, ti ọpọ ẹmi ti jona gurugu.

Oríṣun àwòrán, FRSC
"Ọkọ agbepo naa jo fun odidi wakati meji gbako, ki wọn to ri ina rẹ pa"
Ọkan lara awọn araalu ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe ọkọ agbepo naa jo fun odidi wakati meji gbako ki wọn to ri ina rẹ pa.
Eto ti n lọ lọwọ bayii lati sin oku awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Awọn aworan ti araalu fi ṣọwọ si BBC ṣafihan bi wọn ṣe fi ewe bo ara awọn to ku lẹba ọna, nigba ti ko si ẹya ara lara awọn oku mii mọ nibẹ.
Wayi o, kii ṣe igba akọkọ ree ti irufẹ iṣẹlẹ bayii yoo waye ni Naijiria.
Ni ibẹrẹ oṣu Kẹsan an ọdun yii, irufẹ iṣẹlẹ yii kan naa mu ẹmi eeyan mọkandinlọgoota lọ ni ipinlẹ Niger nigba ti ọkọ agbepo fori sọ ọkọ akero ati eyii to ko maalu.

Oríṣun àwòrán, @Rotus
















