Ìgbà wo ni aáwọ̀ inú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP yóò parí?

Aburada, tii se ami idamọ ẹgbẹ oselu PDP

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDPNig

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lọjọ aje ọsẹ yii lawọn gomina kan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP joko lati jiroro lori ọna abayọ si idarudapọ to n fi ẹgbẹ naa logbologbo.

Ṣaaju ni awọn kan ninu ẹgbẹ ọhun ti kọkọ jawe lọ rọọku nile fun agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Debo Ologunagba, ati amofin rẹ, Kamaldeen Ajibade.

Lẹyin naa ni abala awọn mii ninu ẹgbẹ ọhun tun jawe lọ rọọkun nile fun alaga fidihẹ rẹ, Umar Damagun, ti wọn si kede Yayari Mohammed dipo rẹ.

Lara awọn awuyewuye wọnyii lo ṣokunfa ipade ti awọn gomina ẹgbẹ naa ṣe, nibi ti wọn ti wọgile idaduro Damagun atawọn mii, ti wọn si kede pe ki onikaluku pada sipo rẹ.

Igbesẹ naa lo jẹyọ ninu atẹjade kan lati ọwọ alaga awọn gomina ẹgbẹ naa, to tun jẹ gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed.

Wayi o, ibere ti ọpọ n bere ni pe, igba wo gan ni awuywuye inu ẹgbẹ naa yoo dopin ti ẹgbẹ ọhun yoo si pada sipo aṣaaju to ea tẹlẹ ni Naijiria?

Ki lo ṣokunfa ija inu ẹgbẹ PDP?

Lati ọdun 1998 ti wọn ti gbe ẹgbẹ oṣelu PDP kalẹ ni ẹgbẹ naa ti n koju oniruru wahala laarin awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ.

Lẹyin ti ẹgbẹ ọhun lulẹ ninu eto idibo Aarẹ ọdun 2015, ipinya de ba a bi awọn kan ṣe tẹle Ahmed Makarfi to jẹ gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ, ti awọn mii si tẹle Ali Modu Sheriff to jẹ gomina ipinlẹ Borno nigba kan ri.

Ni bayii, PDP ni ẹgbẹ alatako to tobi julọ ni Naijiria, o si ni ireti pe oun yo gbakoso ijọba Naijiria pada lọdun 2027.

Awọn kan gbagbọ pe aawọ to wa ninu ẹgbẹ naa lọwọ yii bẹrẹ lẹyin eto idibo abẹnu to kọja, ninu eyii ti Atiku Abubakar ti fidi Nyesom Wike janlẹ lati du ipo Aarẹ.

Wike atawọn gomina mii lati ila oorun Naijiria sọ pe awọn ko ni ṣatilẹyin fun Atiku lati wọle ipo Aarẹ latari pe ko tọ ki ipo Aarẹ tun lọ si ariwa Naijiria lẹyin ti Muhammdu Buhari ti lo ọdun mẹjọ lori alefa.

Damagun – alaga fidihẹ

Umar Iliya Damagum

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/Umar Iliya Damagum

Umar Damagun to jẹ igbakeji alaga tẹle lati ariwa di alaga fidihẹ lẹyin ti wọn yọ Iyorchia Ayu nipo bii jiga, eyii ti ile ẹjọ fontẹ lu.

Bi wahala naa ṣe n lọ lọwọ ni Aarẹ Bola Tinubu yan Nyesom Wike sipo minisita, eyii to mu ki ọpọ ọmọ ẹgbẹ pe ke si awọn adari rẹ lati fi iya to tọ jẹ Wike ṣugbọn Damagun ko gbe igbesẹ kankan lori rẹ.

Aibikita Damagun naa bi ọpọ ọmọ ẹgbẹ ninu.

Bakan naa nigba ti wọn ṣeto idibo nipinlẹ Rivers, awọn alatilẹyin Wike fidi awọn alatilẹyin gomina Sim Fubara janlẹ.

Ipa wo ni rogbodiyan yii yoo kuro ninu ẹgbẹ PDP?

Ọjọgbọn Yahaya Tanko Baba, to jẹ onimọ nipa eto oṣelu ni fasiti Usman Dafodiyo sọ fun BBC pe ohun to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP kii ṣe ohun babara ati ohun ti oju ko ri ri.

Baba sọ pe ija inu ẹgbẹ naa ti bẹrẹ ṣaaju eto ididbo gbogbogbo ọdun 2023.

O fikun pe ija naa tunbọ gbilẹ si lẹyin idibo naa latari pe o lọwọ ijọba apapọ ninu.

Ọjọgbọn naa pari ọrọ rẹ pe Nyesom Wike gan ni eku ẹda to jẹ ki rogbodiyan ọhun tunbọ buru siwaju si.

Ki lo yẹ ki PDP ṣe ṣaaju eto idibo 2027?

Baba sọ pe awọn adari ẹgbẹ PDP gbọdọ joko lati ni ijiroro alaafi lori itesiwaju ẹgbẹ naa ti wọn ko ba fẹ lulẹ lọdun 2027.

O ni wọn ni lati bere lọwọ awọn to n binu lati mọ ohun ti wọn n fẹ ki wọn si gbiyanju lati yanju awọn aawọ aarin wọn ni itubi inubi.