Ọlọ́run táwọn mùsùlùmí àtàwọn onígbàgbọ́ ń sìn pẹ̀lú àwọn òrìṣà tiwa lẹgbẹ́ - Alaṣẹ Ijọ Orunmila

Àkọlé fídíò, Ìjọ Orunmila
Ọlọ́run táwọn mùsùlùmí àtàwọn onígbàgbọ́ ń sìn pẹ̀lú àwọn òrìṣà tiwa lẹgbẹ́ - Alaṣẹ Ijọ Orunmila

Alaṣẹ Ijọ Orunmila Apapọ Odu, Ifaleke Awurela, ti tako ọrọ tawọn eeyan kan maa n sọ wi pe Olọrun kan naa lawọn ẹlẹsin Ifa atawọn musulumi to fi mawọn kirisitẹni jọ n sin.

Ọgbẹni Awurela ni igbagbọ oun ni pe Ọlọrun musulumi ati Ọlọrun Kirisitẹni yatọ si Ọlọrun tawọn Oni Ifa n sin.

''Ọlọrun ti wọn pẹlu awọn oriṣa tiwa ni ẹgbẹ, emi gbagbọ wi pe ọrun paadi wa gẹgẹ bi Bibeli ṣe sọ.

Mi o mọ idi tawọn tawọn ọmọlẹyin Kristi atawọn musulumi ko fi gbagbọ ninu Olodumare tawa n sin to fi jẹ pe ooṣa ni wọn n sin gẹgẹ bi Ọlọrun ti wọn.''

Alaṣẹ Ijọ Orunmila Apapọ Odu ni Ọlọrun kan naa lo yẹ ki gbogbo aye gbagbọ pe o wa, ṣugbọn o ni o ṣeni laanu wi pe awọn musulumi ati kristẹni ko gba bẹẹ.

Ọgbẹni Awurela ni iranṣe lawọn Irunmọlẹ awọn, wọn kii ṣe Ọlọrun.

Bakan naa ni Alaṣẹ ijọ Orunmiula Apapọ Odu ni oun gbagbọ pe ọrun apaadi wa, ati pe idajọ n bẹ lẹyin iku.

O ni idi niyii ti eeyan fi gbọdọ gbe aye ṣe rere ki iku o to de tori ko yẹ ki iku ka iwabajẹ mọ ẹnikẹni lọwọ.

‘’Ọrun iye ni gbogbo eeyan yoo lọ lẹyin iku ati ẹni to ṣe buburu ati ẹni to ṣe rere tori ọrun o pe meji.

Nigba ti a ba de ọrun iye ni a maa gba idajọ, ile aye yii ni gbogbo ẹlẹṣẹ ti maa wa jiya ẹṣẹ wọn tori pe ko si aye fun ẹlẹṣẹ lode ọrun.

Iya ẹṣẹ gbogbo wa ko le dọgba o, tori oriṣiiriṣii ẹṣẹ ni a n da nigba ti a wa ni ode aye.

Fun apẹẹrẹ, ija ẹṣẹ ẹni to fi ibọn pa eeyan yoo tatọ si ti ẹni to fi ada ṣa eeyan pa.

Amọ, ile aye yii ni gbogbo ẹlẹṣẹ yoo ti wa jiya ẹṣẹ wọn.

Ẹlomiran yoo pada waye gẹgẹ bi eniyan lati wa jiya ẹṣẹ rẹ,'' Alaṣẹ Ijọ Orunmila ṣalaye.