Ọmọ ọdún 15 pe ìjọba, àjọ JAMB àti NUC lẹ́jọ́ lórí òfin tó ní akẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ̀ pé ọdún 18 kó tó wọ fásítì

Oríṣun àwòrán, Prof. Tahir Mamman/ Facebook
Ọmọ ọdun mẹẹẹdogun kan,Chinaemere Opara, ti pe minisita eto ẹkọ lorilẹede yii, Ọjọgbọn Mamman Tahir, ajọ JAMB to n ri si igbaniwọle si ile ẹkọ giga ati ajọ NUC lẹjọ, lori ofin ọdun mejidinlogun ti akẹkọọ gbọdọ pe ko too wọ ile ẹkọ giga.
Ile ẹjọ giga ilu Abuja ni wọn pe ẹjọ naa si lọjọ Aje, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa ọdun 2024.
Maxwell Opara to ni oun ni baba Chinaemere, lo ṣagbatẹru bi iwe ipẹjọ naa ṣe de kootu.
Ajọ akọoroyinjọ Naijiria, NAN, fidi ẹjọ naa mulẹ pẹlu nọmba rẹ ti i ṣe FHC/ABJ/CS/1512/2024 .
Wọn ko ti i yan adajọ kankan ti yoo gbọ ẹjọ naa.
Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni minisita eto ẹkọ lorilẹede yii, Ọjọgbọn Tahir Mamman, kede pe ọmọ ti ko ba ti i pe ọdun mejidinlogun ko ni i le wọle sile ẹkọ giga mọ lati saa igbẹkọ ọdun 2025, afi ti ọjọ ori naa ba pe.
Kí ni ọmọdé to pe ìjọba lẹ́jọ́ yii fẹ́ kí kóòtù ṣe?
Gẹgẹ bo ṣe wa ninu ibeere Opara, ọmọde yii ni oun fẹ ki kootu ri ofin ọlọdun mejidinlogun naa bii oju-ṣaaju ati ohun to lodi labẹ ofin.
Chinaemere ṣalaye pe titẹ ẹtọ oun lati sọrọ mọlẹ ni ofin ijọba naa jẹ, gẹgẹ bo ṣe wa lawọn abala kan iwe ofin orilẹede yii.
Ọmọ ọdun mẹẹẹdogun naa loun fẹ ki kootu kede pe awọn olujẹjọ mẹta yii ko lẹtọọ lati di oun lọwọ nipa ẹgbẹ to wu oun lati darapọ mọ.
Bakan naa lo ni ofin to n de asiko toun yoo ṣe idanwo JAMB tabi wọ fasiti yii tumọ si pe oun ko le jẹ anfaani ijọba ti oun lẹtọ si labẹ ofin.
Fun idi eyi, ọmọde naa loun fẹ ki kootu lo agbara rẹ lati da awọn nnkan naa duro.
Kilaasi keji, nipele awọn akẹkọọ girama (SS2) ni Chinaemera wa, ẹkọ nipa iṣegun oyinbo lo si fẹẹ kọ ni yunifasiti .














