‘Àhesọ lásán ni ẹ̀sùn tuntun tí ìjọba America fi kan Peace Airline’

Oríṣun àwòrán, Air Peace/Facebook
Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofufuru Peace Airline, ti fesi si awọn ẹsun tuntun ti ijọba ilẹ Amẹrika fi kan wọn, wọn ni ahesọ lasan ti ko lẹsẹ nilẹ ni.
Olori ileeṣẹ naa, Allen Onyema ati alabojuto inawo rẹ, Ejiroghene Eghagha, ni ijọba ilẹ America tun ṣẹṣẹ ka awọn ẹsun kan si lẹsẹ.
Lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa ọdun 2024 ni ijọba America fi atẹjade sita, pe Onyema n di idajọ ododo lọwọ pẹlu ayederu iwe to ko kalẹ.
Ilẹ America ṣalaye pe ọna ti Onyema yoo fi da iwadii duro lori ẹsun ti wọn fi kan an lo n wa.
Bakan naa ni wọn ni Arabinrin Ejiroghene Eghagha, n ṣatilẹyin fun ọga rẹ nipa bi wọn yoo ṣe dena idajọ ododo ọhun.
Ati pe obinrin naa lọwọ ninu lilu banki kan ni jibiti.
Ṣugbọn ninu ọrọ kan ti awọn alaṣẹ ileeṣẹ Peace Airline fi sita loju opo X wọn lọjọ Aiku, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹwaa 2024, wọn ni ahesọ ẹsun lasan ni, nitori Onyema ati Eghagha ko lẹbọ lẹru.
Tẹ o ba gbagbe, lati 2019 ni wọn ti n ṣe iwadii awọn eeyan mejeeji yii, lori ẹsun jibiti, ati pe iṣẹ ibi ni wọn n sẹ ti wọn si n fi ileeṣẹ ọkọ baaluu boju.
Ẹsun mẹtadinlọgbọn (27) to ni i ṣe pẹlu ọja okunkun ni wọn fi kan Onyema, ẹni ọdun mọkanlelọgọta.
Owo to ju miliọnu lọna ogun dọla lọ ni wọn fi ẹsun rẹ kan an.
Ni ti Eghagha, ẹni ọdun mejilelogoji, wọn ni o lo orukọ ẹlomi-in gẹgẹ bii tirẹ lati fi jẹ anfaani, eyi to lodi labẹ ofin.
Àwọn ẹ̀sùn wo ni America fi kan Allen Onyema?
Gẹgẹ bi Olootu idajọ ilẹ America, Ryan K. Buchanan, ṣe sọ ninu ẹsun tuntun naa, o ni:
‘’Lẹyin to fi ileeṣẹ ọkọ ofurufu rẹ boju tan lati lu jibiti l’’America, Onyema ati ikeji rẹ, la gbọ pe wọn tun lu jibiti miran, wọn gbero lati da oju iwadii ijọba ru.
Bakan naa ni Lisa Fontanette, to n ri si pipa owo wọle lẹka Internal Revenue Service Criminal Investigation ni Atlanta, fẹsun kan awọn olujẹjọ pe wọn sọ America di ibi ti wọn yoo maa tọju owo iṣẹ ibi wọn si.
O ni ẹsun tuntun yii wa fun lati dena awọn onijibiti to fẹẹ da idajọ ododo duro.
‘Ọga wa maa n tẹlẹ ofin ijọba deede’
Ninu ọrọ awọn alabojuto Airpeace, wọn ni ọga awọn ati awọn ikọ amofin rẹ ko tapa si aṣẹ ilẹ America ri latigba ti ọrọ yii ti bẹrẹ.
Wọn lo da awọn loju pe otitọ ni yoo leke, ọga awọn yoo bori ogun ẹjọ America yii.
Ta a ni Allen Onyema?
Ilu Mbosi, nipinlẹ Anambra ni wọn ti bi Allen Onyema.
O kawe gboye nipa ofin ni Yunifasiti Ibadan, o si lọ sileewe ofin laaarin 1987 si 1988, ki wọn too sọ ọ di lọọya ni 1989.
Ọdun 2013 lo bẹrẹ ileeṣẹ Air Peace.
Allen Onyema ni awọn ọmọ Naijiria fun ni ami ẹyẹ ọkunrin to pegede julọ ni 2019, nitori ipa nla to ko nigba ti awọn eeyan South Africa n pa awọn ọmọ Naijiria.
Eeyan188 lo fi ọkọ ofurufu rẹ gbe lọdun naa pada wa si Naijiria.















