"Bobo B jẹ Baálẹ̀ Alágùnsá ní oko wa, á ń palẹ̀ ìwúyè mọ́ ní Ọlọ́jọ́ dé"

Àkọlé fídíò, Ayobami Olabiyi: Òní la fẹ́ ṣí Mọ́ṣálásí tí Bobo B gbà fún oko wa, táwọn Saudia bá wa kọ́
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Awaye ku ko si, ọrun ma kanju, gbogbo wa la n bọ tori ko si ẹni ti ko ni ku, ko si si ẹni ti oko baba rẹ ko ni di igboro.

Agba osere tiata ni ede Yoruba ni Ayobami Olabiyi, ti ọpọ eeyan mọ si Bobo B nigba aye rẹ amọ se ni iku sadede da ẹmi rẹ loegbodo ni owurọ Ọjọru, ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹwaa ọdun 2024 yii.

Bi o tilẹ jẹ pe wọn ti sin oloogbe naa ni irọlẹ ọjọ to ku, sibẹBBC Yoruba de ile rẹ ni ọjọbọ lati ba awọn ẹbi rẹ sọrọ nipa igbe aye oloogbe naa.

Kabiru Olabiyi, Ayobami Olabiyi ati Olabisi Olabiyi

"Oni ni wọn n si Mọsalasi ti Ayobami Olabiyi gba fun oko wa, ti awọn Saudia ba wa kọ amọ oun gan ko si laye lati peju sibẹ"

Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, awọn aburo oloogbe ati ọmọ rẹ ni Ayobami Olabiyi sẹsẹ jẹ oye Baalẹ ni oko wọn ni, eyi ti wọn n pe ni Alágùnsà.

Koda, wọn ni awọ̀n n palẹ mọ fun ayẹyẹ iwoye baalẹ naa ni Ọlọjọ de ba.

Kabiru Olabiyi tii se aburo oloogbe ni oni Ọjọ Ẹti gan ni wọn n si Mọsalasi ti Ayobami Olabiyi ba wọn gba lati ọdọ awọn Saudia, ti wọn wa kọ si oko wọn naa.

"O se ni laanu pe Ayobami Olabiyi ko si laye lati peju sibi ayẹyẹ sisi Mọsalasi naa, ka si tun wuye Baalẹ Alagunsa to jẹ.

Baba wa wulo pupọ nigba aye rẹ, o wulo fun ẹbi, idile iya ati baba, o dara laarin awọn ti wọn jọ n sisẹ tiata, to si tun wulo laarin ilu ati awujọ.

Abiamọ tootọ ni, amọ ko duro jẹun ọmọ, oun ti Ọlọrun se fun yẹ ko pọ ju bayi lọ"

Kabiru ati Olabisi Olabiyi

Bakan naa, Kabiru Olabiyi ati ọmọbinrin oloogbe naa, Olabisi Olabiyi salaye fun BBC Yoruba nipa bi oloogbe naa se wulo fun ẹbi wọn.

"Ọmọ mọkanla ni baba agba wa fi silẹ saye, Ayobami nikan lo ti n sisẹ nigba ti baba agba ku.

Oun nikan si ni a ri, ti o n tọju wa, abiyamọ gidi ni, ti kii ta eeyan nu.

Gbogbo ohun ti Bobo B ni, ẹbi lo fi sin, igba ti gbogbo wa si jẹ eeyan tan, to yẹ ko maa jẹun ọmọ, ni Ọlọjọ de.

Ayobami kan sisẹ da silẹ lasan, akoko to si yẹ ko maa jẹun ọmọ, lo ku yii."

Ọmọ oloogbe naa wa fọwọ gbaya pe ko si ibi ti baba oun ko le tẹle ọmọ de amọ ko fẹ ki ọmọ oun daran tabi fa wahala wa sile.

Kòkòrò kan ló so sí ẹsẹ̀ Bobo B lóṣù mẹ́ta sẹ́yìn, a gbé e lọ sí UCH amọ́ ṣe ní ẹsẹ̀ náà ń ṣe omi - Ọmọ Olóògbé

Ayobami Olabiyi ati saare rẹ
Ile Bobo B to wa ni Amuloko nilu Ibadan

"Ahesọ ọrọ lasan ni pe Bobo B ko le gbe apa, gbe ẹsẹ, ti ko si le sọrọ, ki ọlọjọ to de"

Ẹni akọkọ to ba wa sọrọ, Ọlabiyi Kabiru, to jẹ aburo Bobo B amọ ti Oloogbe naa mu gẹgẹ bii ọmọ rẹ, ṣe alaye fun akọroyin BBC Yoruba bi olori ẹbi wọn se ku.

Kabiru ni bii oṣu mẹta sẹyin ni wọn ṣe akiyesi pe kokoro kan so si ẹsẹ Oloogbe naa, wọn si gbe lọ si ile iwosan ijọba UCH niluu Ibadan, ko to di pe ẹsẹ naa wu, o si n ṣ'omi.

Lati bii oṣu kan aabọ sẹyin si ni wọn ti kuro ni UCH nigba ti wọn ṣe akiyesi pe alaafia ti n ba agọ ara Oloogbe.

O ni ahesọ ọrọ lasan ni iroyin ti awọn eeyan kan n gbe kiri wi pe Oloogbe ko le gbe apa, ko le gbe ẹsẹ, bẹẹ si ni ko le sọrọ ki ọlọjọ to de.

Kabiru ni ko si nnkan to jọọ nitori Oloogbe Ọlabiyi ṣi ba awọn eeyan to wa layika rẹ sọrọ, ki o to di pe ohun gbogbo yipada laarin ọjọ marun un si igba ti gbajugbaja oṣere tiata naa jade laye.

Kabiru Olabiyi, aburo oloogbe

"O yẹ ki Oloogbe Bobo B ko ọrọ jọ, ṣugbọn bukata ẹbi lo n fi gbogbo nnkan to ni gbọ"

Aburo Oloogbe naa wa ṣe apejuwe Bobo B gẹgẹ bii opo to gbe ẹbi wọn ro, pẹlu afikun wi pe nipasẹ Oloogbe naa ni orukọ ẹbi wọn ṣe gun oke agba

O tẹsiwaju wi pe awọn mọkanla ni obi awọn bi, Oloogbe Ayọbami nikan si lo n ṣiṣẹ nigba ti baba wọn jade laye l'ọdun 1994.

Kabiru ni sugbọn ko jẹ ki awọn aburo rẹ mọ ala wi pe awọn ko ni baba.

O ni o yẹ ki Oloogbe ko ọrọ jọ, ṣugbọn bukata ẹbi lo n fi gbogbo nnkan to ni gbọ.

Laipẹ yii ni wọn fi Ologbe Ayọbami Ọlabiyi jẹ Baalẹ Alagunṣa ni oko wọn, bẹẹ sini wọn ti da ọjọ iwuye ki ọlọjọ to de. Ọjọ Ẹti ọsẹ yii si ni wọn fẹ ṣi mọṣalaṣi ti eto naa yoo ti waye.

Olabisi Olabiyi

"Wakati meji gbako ni Bobo B fi sunkun, ko to dagbere faye"

Akọbi Oloogbe, Ọlabiyi Ọlabisi naa ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ, lori iku baba rẹ.

Gẹgẹ bi o tis alaye, "gbogbo ipa ni awọn sa lati tọju Oloogbe naa, ṣugbọn aisan ni ẹda le tọju, ko si ẹni to ri ti ọlọjọ ṣe.

O wa bẹnu atẹ lu awọn eeyan to n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri wi pe baba oun ko le gbe apa, ko si le sọrọ ki ọlọjọ to de.

Ọlabisi ni iroyin naa jẹ nnkan to ba oun ninu jẹ gan an.

Ọlabisi wa ṣe apejuwe baba rẹ to di Oloogbe naa, gẹgẹ bii abiyamọ tootọ, to duro ti ọmọ.

O ni wakati meji gbako ni Oloogbe fi sunkun, ki o to dagbere faye.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe, ọpọlọpọ nnkan rere ni awọn yoo ṣe afẹri rẹ nipa Oloogbe naa.

Ile Bobo B ati awọn to n daro iku rẹ

Wọn ti sin Bobo B, adura ọjọ kejọ yoo waye lọjọru to n bọ

Wọn ti sin Oloogbe naa si ẹgbẹ ile rẹ to n bẹ ni agbegbe Amuloko ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ l'Ọjọru.

Adura ọjọ kejọ yoo waye lọjọru, kẹtalelogun oṣu yii.

A bi Oloogbe Ayọbami Ọlabiyi lọjọ kẹrinla, oṣu kọkanla. ọdun 1958, o si jade laye lọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹwaa ọdun yii.