Awakọ̀ BRT tí wọ́n ló pa Bamise Ayanwola, sọ àwọn tó ní wọn ṣiṣẹ́ ibi náà lójú òun

Bamise àti Andrew

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awakọ ero to jẹ ti ijọba ipinlẹ Eko BRT, Andrew Nice Omininikoron , to n jẹjọ lori ifipabanilopọ ati iku ọkan lara awọn ero to gbe, Bamise Ayanwola ti sẹ́ pe, oun ko jẹbi awọn ẹsun ifipabanilopọ̀ ati ipaniyan ti wọn fi kan an.

Ọgbẹni Omininikoron, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta, sọ nile ẹjọ l’Ọjọbọ pe, ero mẹta mii ti oun gbe, lo fi ipa ba Bamise lopọ, ti wọn tun seku pa a.

Ile ẹjọ giga ijọba ipinlẹ Eko to wa ni Tafawa Balewa Square ni Omininikoron ti sọ awọn ọrọ yii niwaju Onidajọ Sherifat Sonaike.

Ileeṣẹ iroyin Channels jabọ pe afurasi naa sọ lasiko ti agbẹjọro rẹ, Abayomi Omotubora, n fí ọrọ wa lẹnu wo, pe oun ko lọwọ si nnkan to ṣẹlẹ si Bamise, ẹni ọdun mejilelogun naa, to jẹ aranṣọ nigba aye rẹ.

"Awọn ọkunrin mẹta ti mo gbe lo fi ipa ba Bamise lo pọ, ti wọn si ju u sita lati inu ọkọ BRT mi"

Andrew Nice Omininikoron salaye pe "Awọn ọkunrin mẹta ti mo gbe lo fi ipa ba Bamise lo pọ, ti wọn si ju u sita lati inu ọkọ BRT mi."

O ṣalaye pe oun o tilẹ le sọ bi nkan ti ri lara oun lasiko ti gbogbo iṣẹ aburu naa n ṣẹlẹ.

"Mi o ni nkankan ṣe pẹlu awọn to fa ibọn yọ lẹgbẹ mi rara, Chevron ni mo ti gbe arabinrin naa, mo si gbe awọn ọkunrin ọhun ni ibudokọ mii".

Awakọ naa ṣalaye pe nigba ti awọn yẹn fa ibọn yọ ti wọn fi han oun, oun ko jẹ ara oun mọ.

"Ibẹru ti bo mi jinijini, nitori naa, gbogbo nnkan ti ẹni to gbe ibọn lọwọ ba sọ fun mi ni mo kan n tẹle".

Nice Andrew Omininikoron ṣalaye bi wọn ṣe ni ki o da ọkọ duro nigba ti awọn de Third Mainland Bridge, ti wọn si ni ki oun gba de ori afara Carter ti wọn si n wọ ọmọbinrin naa bọlẹ, "nigba ti mo ri i to n sunkun, ko sohun ti mo le ṣe".

O ni ibẹru lo jẹ ki oun sa lọ nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe bẹrẹ?

Ohun ti a gbọ ni pe agbegbe Chevron Estate ni Ajah ni oloogbe naa ti n ṣiṣẹ gẹgẹbi aranṣọ, ti o si maa n lọ si Ota nipinlẹ Ogun lọdọ ẹgbọn rẹ obinrin lati lọ ṣe isinmi opin ọsẹ lọsọọsẹ.

Omidan Ayanwola n lọ si Ota lọjọ Satide lẹyin to pari iṣẹ tan ni Ajah lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji lo fi wọ bọọsi BRT naa ti nọmba rẹ jẹ 240257.

Oshodi ni bọọsi BRT naa n lọ ṣugbọn omidan naa ko de oshodi, to fí di awati ko to o di pe wọn ri oku rẹ lẹyin ọjọ diẹ ni agbegbe Ebute-Ero.

Ọrẹ rẹ kan to n fi fọnran ohùn ranṣẹ si bo ṣe fura pe oun wa ninu ewu, lo jẹ ki àṣírí tu pe, inu BRT naa lo ti kagbako.

Lẹyin naa ni ọwọ tẹ Andrew Nice Omininikoron, awakọ BRT to gbe Bamise, ni agbegbe Odogbolu to salọ nipinlẹ Ogun.

Onidajọ Sonaike ti sun igbẹjọ mii si ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa.

Sugbọn ṣa, ko ṣai fi aidunnu rẹ han lori bi ẹjọ naa ṣe n falẹ lati ọdun 2022.

Ọjọ karundilogun, oṣu Keji ọdun 2023, ni igbẹjọ ti waye kẹhin.

Eyi ni ile ẹjọ sọ pe ko ṣẹyin agbẹjọro olujẹjọ.