Israel pa Yahya Sinwar, olórí ikọ̀ Hamas tó bẹ̀rẹ̀ ogun ní Gaza

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ikọ ologun Isreali ti kede pe awọn ti pa Yahya Sinwar, olori Hamas, ni Gaza.
Eyi si jẹ lẹyin oṣu meji ti Hamas yan an lati jẹ olori wọn.
Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa Isreal ṣe ṣalaye, wọn ni awọn kọkọ da oku Sinwar mọ pẹlu eyin ati ika rẹ.
Awọn nnkan meji yii pẹlu akọsilẹ gbogbo ara rẹ (DNA) ni Israel ni, latari ẹwọn ọdun mejilelogun ti Sinwar ṣe lati ọwọ Israel.
Sinwar, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Abu Ibrahim, jẹ ọkan lara awọn olori ogun ati ikọlu to waye lọjọ keje, oṣu kẹwaa ọdun 2023.
Bẹẹ ni orilẹede naa Israal ti n leri tipẹ pe awọn yoo dọdẹ rẹ, awọn yoo si mu un balẹ dandan.
Ta a ni Yahya Sinwar?
Ọdun 1962 ni wọn bi Yahya Sinwar sinu ile awọn eeyan to n ṣe atipo, ni Khan Younis, Gaza.
Ọmọ ọdun marun-un lo wa ti Isreael fi ṣigun si wọn lati Egypt, nigba ogun ọdun 1967.
Awọn ẹbi Sinwar tun wa lara ẹẹdẹgbẹrin ọmọ Palestine to sa kuro nile latari ogun Israeli ni 1948.
Nigba ti Sinwar le diẹ logun ọdun ni Isreali ju u si ẹwọn, lori ẹsun pe o pa ọmọ Palestine mẹrin ti wọn n ṣe amí.
Ninu ọdun mejilelogun ti Yahya Sinwar ṣe lẹwọn lo ti kọ ede Hebrew, o wadii awọn ọta rẹ o si mọ wọn tinu-tẹyin.
Wọn tu Sinwar silẹ ni 2011 pẹlu awọn Palestine ẹgbẹrun kan.
Isreal ṣe eyi lati fi gba iyọnda ṣọja kan ṣoṣo, Gilad Shalit, to wa lakata Hamas pada.
Lọjọ keje, oṣu kẹwaa ọdun 2023, Sinwar ati awọn ọmọ ogun rẹ ṣe ikọlu to lagbara si Israel, wọn ko si i ti i bọ nibẹ titi doni.
Ọmọ Israeli to ba ikọlu naa lọ, to ẹgbẹrun kan ati igba, (1, 200).
Ki ni awọn eeyan Sinwar wi fun Israel?
Ninu ipo idaru ati iwopalẹ ti Khan Yunis wa, nibi ti wọn ti bi Sinwar, BBC ba awọn olugbe ibẹ sọrọ, wọn si sọ pe ki ogun maa tẹsiwaju ni awọn fẹ.
" Ogun yii ki i ṣe ti Sinwar, Haniyeh abi Mishal nikan, ki i ṣe ogun olori nikan rara, ogun ti wọn fẹẹ fi pa awọn eeyan Palestine run ni, o ye wa daadaa."
Ọkan ninu awọn eeyan naa, Ramadan Faris, lo sọ bẹẹ.
Bakan naa niAdnan Ashour, sọ pe:
" Awa nikan kọ ni wọn fẹẹ parun, gbogbo Aarin Gbungbun Ila-Oorun (Middle East) ni wọn fẹẹ gba.
Wọn n ja ni Lebanon, Syria, ati Yemen. Ogun awa ati awọn Jew ree lati 1919, o ti le lọgọrun-un ọdun.
Ṣe iku Sinwar yoo ṣakoba fun Hamas? Adnan dahun pe oun ko ro bẹẹ. O ni Hamas kọjaa Sinwar, ogun gbogbo eeyan ilu awọn ni.
Lati 1990 titi di asiko yii, Isreali lo n pa awọn olori Hamas, ṣugbọn bi wọn ṣe n pa wọn ni awọn naa n fi ẹlomi-in rọpo ẹni ti wọn pa.
Bi Isreali ṣe n yọ ayọ iṣẹgun lori iku Sinwar, awọn eeyan kan naa ṣi wa nigbekun Hamas, bẹẹ ni wọn n jagun lọ.
Ojú wo ni àwọn ọmọ Isreali fi ń wo olórí wọn?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Loju ọpọlọpọ ọmọ Isreali, Benjamin Netantahu ti i ṣe olori wọn fẹ ki ogun yii maa tẹsiwaju, ko ma baa jẹjọ lori aikunju oṣuwọn, eyi to mu Sinwar ati ikọ rẹ wọle si wọn lara.
Ikeji ni pe wọn ni Netanyahu ko fẹ ki ogun pari, ko ma baa jẹjọ lori owo ilu ti wọn lo ṣe mọkumọku, ti wọn si ti fi ẹsun rẹ kan an.
Ṣugbọn olori Isreali naa sọ pe ko sohun to jọ awọn ẹsun yii.
O ni aṣeyọri tawọn ba ṣe ni Gaza ni yoo da aabo to peye pada si Israel.
Gẹgẹ bi iṣe wọn, Israel ko jẹ kawọn oniroyin kọja si Gaza lati wo ohun to n ṣẹlẹ, afi ti wọn yoo ba tẹle awọn ologun lọ to ba doju ẹ tan.
“Àjálù ńlá ni iku Sinwar jẹ fun Hamas, ṣugbọn ogun ṣì ń tẹ̀síwájú’’
Lẹyin ti ikọ ologun Israel ti pa olori awọn Hamas, Yahya Sinwar, Israel ti n yọ ayọ iṣẹgun pẹlu alaye pe iku naa jẹ ajalu nla fun Hamas, ṣugbọn ogun yoo ṣi maa tẹsiwaju pẹlu wọn lọ ni.
Iṣẹgun to ga ju fun Israel latigba ti ogun naa ti bẹ silẹ ni Gaza, ni bi wọn ṣe ri Sinwa pa yii.
Ki i ṣe pe wọn pilẹ ikọlu to pa Sinwa, iku naa kan waye lagbegbe Rafah ni, lẹyin ti ado oloro ba ile kan ti olori Hamas naa wa .
Aworan kan ṣafihan Sinwar nibi to ku si, o dubulẹ sinu ile to da wo naa.
Ọjọru, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2024 yii ni wọn pa Yahya Sinwa.
Olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu, gboriyin fun awọn ṣọja to ṣiṣẹ naa.
O ni aṣẹyọri nla ni wọn ṣe, ṣugbọn ogun ṣi n tẹsiwaju.
" Ogun yii ko ti i pari, o nira pupọ, o si n gba ọpọlọpọ nnkan lọwọ wa.
A nilo aforiti, iṣọkan, igboya ati iduro ṣinṣin.
Pẹlu iranlọwọ Ọlọrun, a maa ṣẹgun pọ."
Bẹẹ ni Olootu ijọba Israel wi.
Ọpọ igba ni Olootu ijọba naa ti sọ pe awọn gbọdọ ṣẹgun Hamas, kawọn si ko awọn to wa nigbekun wale, ṣugbọn eyi ko ti i waye.
Awọn ọmọ Palestine to ti ba ogun yii lọ bayii ti to ẹgbẹrun mejilelogoji (42, 000), o si ti sọ Gaza di ahoro.
Awọn to wa nigbekun ṣi wa nibẹ, awọn Hamas naa ṣi n ja, wọn n pa awọn ikọ Israeli tọwọ wọn ba to.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Israel ṣapejuwe Sinwar bii olori to le
Ikọ ologun Israel naa ṣapejuwe Yahya Sinwar bii olori to le to si ṣoro pupọ.
Micha Kobi, oṣiṣẹ ajọ Internal Security Agency tẹlẹ, ṣalaye pe oun fi ọrọ wa Sinwar lẹnu wo nigba to wa lẹwọn, ifọrọwanilẹnuwo naa si gba ohun ni aadoje wakati (150 hours) .
O ni Sinwar buru, o le ni eeyan.
Gẹgẹ bi ẹka iroyin AFP ṣe wi, lọjọ keje, oṣu kẹwaa ọdun to kọja, awọn Hamas ko ọmọ Israeli 251 sigbekun.
Israel naa da a pada fun wọn pẹlu pipa eeyan ẹgbẹrun mejilelogoji.
Pupọ ninu awọn ti wọn pa ni Gaza yii si jẹ obinrin ati awọn ọmọde.
Gẹgẹ bi ẹka ilera Gaza ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images















