"Mo ti gbin igi 250,000 àmọ́ àfojúsùn mi ni láti gbin igi tírílíọ̀nù kan, kí n tó pé ọmọ ọdún 18"

Oríṣun àwòrán, Ellyanne Wanjiku Chlystun
- Author, Mary Isokariari
- Role, Journalist
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹrinla kan lati orilẹede Kenya ti di gbajumọ kaakiri agbaye latari igbiyanju rẹ lati gba ilẹ aye la lọwọ iparun ayipada oju ọjọ.
Lara awọn ti ọmọde naa ti pade ni ọba Charles ilẹ Gẹẹsi, David Becham, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọmọ ọdun mẹrin pere ni Ellyanne Wanjiku Chlystun wa lasiko to ni iwuri nipa ọrọ awujọ lati ọdọ Ọjọgbọn Wangari Maathai to maa n gbin igi.
Ellyaane sọ fun BBC pe “mo n ṣe awọn iṣe kan ni kekere nipa awọn eeyan ti wọn ti gbe rere ṣe nile aye bii Martin Luther King, Nelson Mandela ati Florence Nightingale.
“Amọ ṣa ẹni to ṣe iwuri fun mi julọ ni Wangari Maathai to ti gbin ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu igi ni Kenya.”
Ọjọgbọn Maathai gbagbọ pe awọn obinrin le ṣe rere lawọn ilu igberiko nipa gbingbin igi si ayika ki wọn si dẹkun fifi igi dana.

Oríṣun àwòrán, Ellyanne Wanjiku Chlystun
Lọdun 1977, Maathai da ajọ The Green Belt Movement silẹ, o si gbin igi to le ni miliọnu marundinlaadọta ni Kenya
Maathai di obinrin akọkọ nilẹ alawọ dudu ti yoo gba ami ẹyẹ Nobel Peace Prize lọdun 2004.
Lọdun 1977, o da ajọ The Green Belt Movement silẹ, o si gbin igi ti iye rẹ le ni miliọnu marundinlaadọta ni Kenya.
Nigba ti Ellyanne ka nipa obinrin naa, o sọ fun iya rẹ pe oun fẹ ṣe irufẹ nnkan ti Ọjọgbọn naa ṣe.
Iya rẹ ni ọmọ naa sọ fun oun pe “mo fẹ da bii ti Ọjọgbọn Maathai.”
Amọ nitori iya rẹ mo bi Ọjọgbọn naa ṣe jiya, to tun ṣẹwọn, o sọ fun pe “rara o, o san ki o di agbẹjọro tabi dokita ki o si kawe ni fasiti Harvard,”
Ṣugbọn ọmọ kekere naa kọ jalẹ titi ti iya rẹ fi gba pe ko ṣe bii obinrin Ọjọgbọn ọhun.
Ellyanne ni “mo nifẹ ohun ti mo n ṣe, mo si n sa gbogbo ipa mi lori rẹ.
Eyii lo mu ko lọ kọ nipa imọ sayẹnsi bi igi ṣe n dagba.
Pẹlu atilẹyin awọn obi rẹ o da ajọ kan silẹ ti orukọ rẹ n jẹ Children With Nature lọdun 2017.
O ni “nipa Children With Nature, mo fẹ maa kọ awọn ọmọde nitori pupọ ninu wọn ni ko mọ pe wọn le ṣe atunṣe layika wọn.”
"Ni 2023, Maathai lọ peju si ipade ayipada oju ọjọ ni Dubai, o pade ọba ilẹ Gẹẹsi ati awọn eeyan jankan mii"
O ni nigba ti yoo fi di ọdun 2020, oun funra oun ti gbin igi ti iye rẹ to 250,000, bẹẹ lo ti kọ ọpọ eeyan nipa igi gbingbin ati anfani rẹ lati Kenya si awọn orilẹede mii.
O ni “mo ti gbin igi kaakiri agbaye lawọn orilẹede ti mo lọ, lara wọn ni Uganda, Poland, UK, Crater Lake nilẹ Amẹrika, Zanzibar, Morocco ati Zambia.
“Ṣugbọn Kenya ni mo gbin igi to pọju si.”
Amọ ṣa, laarin ọdun mẹta sẹyin, ko fi bẹẹ gbin igi bii tẹlẹ mọ latari awọn ojuṣe rẹ mii nipa ayipada oju ọjọ.
Nipa bo ṣe n gbin igi, ṣe iṣẹ ayipada oju ọjọ ati eto ẹkọ rẹ, o ni “ko ṣoro fun mi lati gbajumọ ẹkọ mi rara nitori mo n ṣe daadaa nile ẹkọ, inu mi dun si maaki mi bẹẹ si ni ori iya mi n wu si maaki ti mo n gba.”
Lọdun 2023, o lọ sibi ipade ayipada oju ọjọ to waye ni Dubai nibi to ti pade ọba ilẹ Gẹẹsi to si tun ba awọn eeyan jankan sọrọ nipa ibaṣepọ to wa laarin ayipada oju ọjọ ati aisan iba.
O sọ nibi ipade naa pe “bi oju ọjọ ṣe n yipada naa ni aisan iba n peleke siwaju si.
“Nibi ti mo n gbe ni Kenya, aisan iba n farahan lawọn agbegbe tuntun ti a ko si ri iru rẹ ri.”

Oríṣun àwòrán, Ellyanne Wanjiku Chlystun
"Maathai ti n kopa ninu ere sinima, amọ o ni oun ko ni fi ojuṣe igi gbingbin silẹ"
Oun atawọn ọmọde mii lati oniruru orilẹede agbaye kopa ninu fiimu kan nipa ayipada oju ọjọ ti ileeṣẹ iroyin Sky News ati Sky Kids FYI gbe jade, orukọ fiimu naa ni SaveOurWildlife.
Bo tilẹ jẹ pe o ti n kopa ninu fiimu, o sọ fun BBC pe oun ko ni fi ojuṣe igi gbingbin silẹ ati pe oun yoo pada sinu ojuṣe naa laipẹ.
O ṣalaye pe “afojusun mi to ga julọ ni lati gbin igi ni agbegbe Green Belt ilẹ adulawọ, eyii to jẹ lati gbin igi si agbegbe Senegal ati Djibouti lọna ati maa dena itankalẹ aṣalẹ Sahara.
Yatọ si eyii, o tun fẹ gbin igi to le ni tiriliọnu kan kaakiri agbaye ko to pe ọmọ ọdun mejidinlogun.
Amọ ṣa, o ni oun ko ni erongba kankan lati wọ inu oṣelu lọjọ iwaju.















