Àṣà àti ìṣe Yorùbá tó jẹ mí lógún ló máa ń ṣe atọ́nà àwọn iṣẹ́ mi
Tí a bá ń sọ̀rọ̀ eré sinimá pàápàá lẹ́ka Yorùbá, òdú ni Tunde Kelani kìí ṣe àìmọ̀ fún olóko.
Àgbà ọ̀jẹ̀ ayàwòrán náà ló ti ṣe àgbájáde ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré fíìmù láti bíi ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn táwọn èèyàn sì ń jẹ̀rán àwọn fíìmù náà di ọ̀la.
Lára àwọn fíìmù tí Tunde Kelani ti gbé jáde ni Saworoide, Magun, Agogo Eewo, Ti Oluwa nile, Arugba àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń jẹ̀rán àwọn eré yìí tí wọ́n sì máa ń sọ̀rọ̀ lórí ipa táwọn fíìmù náà ní lásìkò wọn. Àwọn mìíràn a sì máa fi àwọn eré yìí wé àwọn eré tí wan ń ṣe lóde òní.
Èyí ló mú BBC News Yorùbá kàn sí àgbà ọ̀jẹ̀ nídìí iṣẹ́ ayàwòrán, olóòtú àti adarí eré sinimá, Tunde Kelani láti sọ̀rọ̀ nípa bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ adarí eré tí ó ń ṣe àtàwọn nǹkan tó máa ń fun ní ìwúrí láti gbé àwọn eré náà jáde.

Oríṣun àwòrán, Tunde Kelani
Tunde Kelani ní láti ìgbà tí òun ti wà ní ilé ẹ̀kọ́ girama ni òun ti máa ń ya àwòrán, tí òun sì máa ń ra ẹ̀rọ ayàwòrán láti fi kọ́ ara òun níṣẹ́ nígbà náà.
“Kí n tó jáde ní Abeokuta Grammar School, mà á ti rà tó ẹ̀rọ ayàwòrán mẹ́rin.”
Ó ní òun ti ná owó àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsìkò láti fi kọ́ iṣẹ́ ayàwòrán kí òun tó parí ilé ẹ̀kọ́ girama, tí òun sì ti mọ̀ pé nǹkan tí òun máa fi ṣe iṣẹ́ ṣe nìyẹn.
Ó ní èyí ló mú kí òun sọ fún bàbá òun pé kí wọ́n jẹ́ kí òun tẹramọ tí òun sì lọ kọ́ iṣẹ́ náà síwájú si.
Ó ṣàlàyé pé lẹ́yìn náà ni òun lọ sí ilẹ̀ òkèrè ìyẹn London Film School láti lọ kọ́ iṣẹ́ sinimá ṣíṣe.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìrírí rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀, Kelani wàhálà púpọ̀ ni àwọn máa ń ṣe kí ó tó di odidi.
Ó sọ pé lẹ́yìn tí àwọn bá ṣe fíìmù tán, àwọn máa nílò láti kó wọn lọ sí ìlú òyìnbó láti lọ fọ̀ ọ́ àti láti lọ to àwọn ohùn àtàwọn èèyàn papọ̀ kí ó tó di nǹkan tí àwọn èèyàn máa ma gbéléwò.
Ó ní àmọ́ ìgbà ti yí padà lásìkò yìí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò tilẹ̀ nílò láti ṣe fíìmù tí wan nílò láti gbé lọ sí sinimá mọ́, ó ní ẹ̀rọ ayélujára ti mú ọ̀pọ̀ nǹkan rọrùn.
Inú mi kìí dùn tí mo bá ń wo àwọn eré tí wọ́n ti ń tàbùkù àṣà Yorùbá

Oríṣun àwòrán, TKProduction
Àgbà ọ̀jẹ̀ nídìí eré sinimá náà wòye pé owó tó wà lórí àwọn àwàdà àti eré kéékèèkèé èyí tí a mọ̀ sí “skit” ló fà á tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi dà si lásìkò yìí.
Ó ní òun gbàgbọ́ pé tí àwọn èèyàn kò bá máa wo skit mọ́, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó ń ṣe é náà kò ní ṣe é mọ́.
“Gbogbo nǹkan tí oníkálukú bá ń ṣe, àwọn èèyàn kàn wá tí wan fẹ́ wò ó, tí wọ́n sì fẹ́ràn rẹ̀.”
Kelani tẹ̀síwájú pé àwọn nǹkan tí Yorùbá jogún bíi àṣà, èdè, ìṣe ni òun ń lò láti fi mú ìlọsíwájú bá ìran Yorùbá.
Ó ní inú òun kìí dùn lọ́pọ̀ ìgbà tí wọ́n bá ń ṣàfihàn àwọn àṣà, ẹ̀sìn àti ìṣe Yorùbá lọ́nà tí kò bá ojú mu nínú àwọn fíìmù.
Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ló jẹ́ wí pé nǹkan tí wọ́n máa tà ni wọ́n ń wá, wọn kò ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ láti mọ òótọ́ nípa àṣà àti ìṣe Yorùbá.
Ó sọ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni inú òun máa ń bàjẹ́ nígbà tí wọ́n bá ṣàfihàn àwọn babaláwo àti ìran Yorùbá bíi ìkà nínú àwọn eré nítorí àwọn tó ń ṣe é kò ní ìmọ̀ kíkún lórí àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe.
“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àṣà tí àwọn ń bàjẹ́ ni àwọn ará ìlú òyìnbó ti sọ di ìmọ̀ ńlá ní ọ̀dọ̀ wọn lọ́hùn-ún tó dẹ̀ jẹ́ pé tí wọ́n bá wá sílé, lọ́dọ̀ àwa tí a ní, ẹ̀tẹ́ ni àwa ń bù lù ú.”
Kelani ní òun gbàgbọ́ pé ó yé kí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ máa wà fún àwọn òṣèré lórí àwọn ipa tí wọ́n ń fi àwọn babaláwo kó nínú eré.






