Don Jazzy dá N100M sí àpò àjọ tí VDM dá sílẹ̀, Portable fa ìbínú yọ

Portable, VDM ati Don Jazzy
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Se ni ori ayelujara n gbona ni owurọ ọjọ ti nitori ikede kan to n fa awuyewuye kan.

Idi ni pe gbajumọ kan lagbo amuludun, Michael Collins Ajereh, ti ọpọ eeyan mọ si Don Jazzy, to ti jẹ akọrin ri, to wa di agbe awo orin jade bayii, ti da owo to le ni ọgọrun miliọnu Naira si apo asunwọn ẹdawo kan.

Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni Verydarkman, ti ọpọ eeyan mọ si VDM, to jẹ onwoye nipa ohun to n lọ ni awujọ lori ayelujara, gbe ajọ alaanu kan kalẹ ni orukọ ara rẹ, eyi to ni kawọn eeyan maa da owo si.

VeryDarkMan kede olori ayelujara pe oun fẹ da ajọ naa silẹ lati maa pese iranlọwọ fun awọn ile ẹkọ kaakiri ni Naijiria.

Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo koro oju si igbesẹ naa lori ayelujara amọ awọn ọmọ Naijiria mii lo ti fi owo ransẹ si VeryDarkMan lati bẹrẹ eto dida NGO naa silẹ.

Amọ ni ọjọbọ ni ariwo sọ pe Don Jazzy ti gbe owo bii miliọnu lọna ọgọrun silẹ fun apo ẹdawo VDM naa, eyi to n ya ọpọ eeyan lẹnu.

Don Jazzy, ye lo mi lati se iwuri fun awọn olorin to wa ni abẹ rẹ sugbọn se ni ko ran mi lọwọ nidi orin kikọ - Portable

Ṣugbọn igbesẹ Don Jazzy yii ni ko dun mọ Portable ninu, to si figba ta.

Ni kete tí VeryDarkMan kede oore tí o gba lọwọ Don Jazzy, ni Portable sọko ọrọ si Don Jazzy pe o kuna lati ran oun lọwọ nidi isẹ orin kikọ

Ninu fọnran kan to wa loju opo ayelujara Portable, o ni Don Jazzy n lo oun gẹgẹ bii awukọse fun awọn olorin to wa ni abẹ rẹ sugbọn o kọ lati ran oun lọwọ.

"Don Jazzy n lo mi gẹgẹ bii awokọse fun awọn olorin to wa ni abẹ rẹ."

Portable ni kí Don Jazzy ye lo oun lati se iwuri fun awọn olorin to wa ni abẹ rẹ sugbọn ko ran oun naa lọwọ.

Ẹwẹ, Don Jazzy ti jẹ ko di mimọ pe oun ni oun fi owo nla ransẹ si apo owo akanti VeryDarkMan naa.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post