Àwọn aṣòfin fún Tinubu ní gbèdéke ọ̀sẹ̀ méji láti gbé àbá ìṣúná 2025 jáde

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency
Ile igbimọ aṣoju-ṣofin lorilẹede Naijiria ti fun Aarẹ BolaTinubu ni gbedeke ọsẹ meji lati fi gbe aba iṣuna owo ọdun 2025 jade.
Bakan naa ni wọn tun pe aarẹ si akiyesi, lati fun awọn ẹka ileeṣẹ ijọba to yẹ lowo fun iṣẹ to yẹ bi 2024 ṣe n pari lọ.
Gbedeke ọsẹ meji yii n waye lasiko ti Aarẹ Tinubu wa lorilẹede France, ti Igbakeji rẹ, Kashim Shettima si wa ni Sweden.
Ọkan ninu awọn ọmọ ile igbimọ naa, Ọnarebu Alasan Rurum to n ṣoju ipinlẹ Kano, ṣalaye pe o ṣe pataki ki aarẹ tete gbe aba iṣuna ọdun to n bọ jade bayii, nitori ọrọ aje Naijiria.
Rurum sọ pe to ba n pẹ, o le ṣakoba fun ọrọ aje orilẹede yii.
Ọnarebu Rurum sọ pe ọpọlọpọ ẹka ijọba ni wọn buwọlu lati fun lowo iṣẹ lọdun yii, ṣugbọn ti wọn ko ti i ri owo ọhun gba.
Bẹẹ ọdun 2024 lo ku oṣu meji ti yoo tan yii, awọn iṣẹ to yẹ ni ṣiṣe ṣi wa nibẹ lai ṣe.
“Kò jọ pé ìgbìmọ̀ wadii ọrọ wò kí wọ́n tóó gbé ìgbésẹ̀”
Nigba to n fesi si gbedeke ijọba yii, ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ aarẹ, Abdulaziz Abdulaziz, sọ pe oun ko ro pe wọn wadii ọrọ naa wo ki wọn too gbe igbesẹ.
" Mo ro pe awọn eeyan ile igbimọ ko ṣe iwadii to kun lori ọrọ yii ki wọn too gbe ọrọ naa siwaju igbimọ.”
Abdulaziz ṣalaye pe ilana kan ti wa ti wọn la kalẹ lati fi nawo ti ijọba ba fọwọ si, ki ajẹbanu tabi ṣisẹ owo ilu mọkumọku ma baa ṣẹlẹ.
Ati pe ki awọn ayederu agbaṣẹṣe ma baa maa gbowo iṣẹ ti wọn o ni i ṣe, bii tigba kan.
Amugbalẹgbẹ Aarẹ Tinubu naa sọ pe aaye ṣi wa lati gbe aba eto iṣuna jade, o ni bi wọn ba ti pari eto to yẹ, ijọba yoo gbe aba naa lọ fun awọn aṣofin bo ṣe yẹ.













