Kí ló dé táwọn olórí orílẹ́èdè Áfíríkà ṣe máa ń fi ọ̀rọ̀ ìlera wọn ṣe nǹkan àṣírí?

Àwòrán ààrẹ Cameroon, Paul Biya

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ààrẹ Cameroon fòfin de àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn láti má sọ̀rọ̀ nípa ìlera rẹ̀
    • Author, Danai Nesta Kupemba
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

“O nílò láti jẹ́ irú èèyàn kan kí o tó lè ní ipa tó lòòrìn nínú òṣèlú – o gbọ́dọ̀ jẹ́ akọni, ẹni tí kìí kó àárẹ̀ ọkàn,” ohun tí Ọ̀jọ̀gbọ́n lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú ilẹ̀ Áfíríkà, Miles Tendi sọ rèé nípa bí àwọn olórí orílẹ̀ èdè Áfíríkà ṣe máa ń gbé ọ̀rọ̀ ìlera wọn pamọ́.

Ọ̀rọ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn èèyàn ń bèèrè pé níbo ni olórí orílẹ̀ èdè Cameroon, Paul Biya wà láti bíi ọ̀sẹ̀ kan sẹ́yìn. Ìjọba orílẹ̀ èdè náà sáré jáde síta sọ̀rọ̀ pé kò sí nǹkankan tó ṣe Biya, tí wọ́n sì tún fòfin de àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn láti yé sọ̀rọ̀ nípa ìlera ààrẹ náà.

Lẹ́yìn èyí ni ààrẹ Malawi, Lazarus Chakwera gbé àwọn àwòrán rẹ̀ níbi tó ti ń ṣe eré ìdárayá síta láti fi han àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè rẹ̀ pé òun kò ní àìsàn rọpárọsẹ̀.

Àwọn olórí orílẹ̀ èdè méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pẹ̀lú èrò kan náà, tí wọ́n ń gbìyànjú láti fọwọ́ bo ipò ìlera wọn.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Tendi sọ pé ọ̀rọ̀ òṣèlú jẹ́ ìṣe akọni láti ṣe àmójútó ipò agbára àti láti dì í mú ṣinṣin kí ó má bọ̀ ọ́ mọ́ èèyàn lọ́wọ́.

Àìsí obìnrin ní ipò ààrẹ

Nínú òṣèlú, nílẹ̀ Áfíríkà àtàwọn orílẹ̀ èdè tókù, ipò táwọn èèyàn máa ń fi àwọn adarí sí ni akọni àti ẹni tó gbọ́dọ̀ ní àgbàmọ́ra.

Kìí ṣe ilẹ̀ Áfíríkà nìkan ni èyí ti rí bẹ́ẹ̀ àmọ́ nǹkan tó wà nípò òṣèlú gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Tendi ṣe sọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Láti ọ̀pọ̀ sẹ́yìn, àwọn olórí orílẹ̀ èdè ní Áfíríkà ló máa ń bínú tàbí kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá bèèrè nípa ipò ìlera wọn.

Nínú ọdún 2010, ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Zimbabwe ni irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn pé òun ṣe iṣẹ́ abẹ tàbí pé àwọn dókítà láti ilẹ̀ òkèrè wá yọjú sí ilé òun.

Ikú ààrẹ Tanzania, John Magufuli lọ́dún mẹ́ta sẹ́yìn ló wáyé lẹ́yìn tí wọ́n ti ń fọwọ́ bo ìlera rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀, kódà ọ̀pọ̀ èèyàn ni wọ́n fi sí àhámọ́ pé wọ́n ń gbé ìròyìn irọ́ kiri lórí ìlera ààrẹ náà kó tó jáde láyé.

Ọ̀pọ̀ àwọn adarí ní ilẹ̀ Áfíríkà ni wọ́n máa ń rí ọ̀rọ̀ ìlera wọn gẹ́gẹ́ bí ohun tó pamọ́ sí wọn táwọn aráàlú kò sì nílò láti mọ̀ nípa rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olórí méjìlélógún ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn sórí ipò nílẹ̀ Áfíríkà.

“Ọ̀pọ̀ àwọn olórí yìí kàn fẹ́ dìrọ̀ mọ́ ipò agbára,” Ọ̀jọ̀gbọ́n Tendi sọ.

Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Cameroon, Ahmadou Ahidjo nìkan ni olórí nílẹ̀ Áfíríkà tó fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ látàrí ìlera rẹ̀ tí kò ṣe dáadáa lọ́dún 1982 lẹ́yìn tó ṣèjọba fún ọdún méjìlélógún.

Lẹ́yìn náà ni Biya gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀ tó sì ti ń ṣe ìjọba láti ìgbà náà.

Ọ̀jọ̀gbọ́n ilé ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Johannesburg, Adekeye Adebajo ní àpilẹ̀kọ kan ṣàlàyé pé àwọn adarí nílẹ̀ Áfíríkà kò ní òótọ́ nítorí wọ́n máa ń rí ìlú àti ìlera wọn bíi ọ̀kan náà.

“Àwọn olórí orílẹ̀ èdè ní Áfíríkà máa ń so ìlera wọn pọ̀ mọ́ orílẹ̀ èdè wọn,” ó sọ.

Ọ̀pọ̀ àwọn olórí orílẹ̀ èdè ni wọ́n ti di bárakú pẹ̀lú orílẹ̀ èdè wọn nítorí ọdún pípẹ̀ tí wọ́n ti fi wà lórí ipò.

Tí nǹkan bá ṣe wọ́n, yóò ṣe ètò ọrọ̀ ajé, tó sì lè fa ìjákulẹ̀ fún ètò òṣèlú.

Wọ́n gbàgbọ́ pé tí àwọn bá ṣe àfihàn ìlera tí kò dá pé, ó dábì fífún àwọn alátakò tàbí àwọn aláṣẹ nílẹ̀ òkèrè láti dá sí ọ̀rọ̀ orílẹ̀ èdè wọn.

Ọ̀pọ̀ àwọn olórí orílẹ̀ èdè ni wọ́n ti gba ipò lọ́wọ́ wọn lẹ́yìn tí wọ́n fi ipò ìlera wọn léde.

Àwòrán Mobutu Sese Seko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Wọ́n gba ipò lọ́wọ́ ààrẹ Democratic Republic of Congo Mobutu Sese Seko nígbà tó wà nílé ìwòsàn

Ohun tó hàn sárá ìlú ni pé ààrẹ orílẹ̀ èdè Democratic Republic of Congo tẹ́lẹ̀ rí, Mobutu Sese Seko ní àìsàn jẹjẹrẹ abẹ́ lọ́dún 1996.

Ọgbọ̀n ọdún ló fi ṣèjọba DRC, tí ìgbàgbọ́ sì wà pé ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ bílíọ̀nù dọ́là ló kó nígbà tó wà nípò èyí tó fi ra àwọn ilé ní Switzerland àti Morocco.

Orílẹ̀ èdè náà ni ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀ kò ṣe dáadáa lásìkò náà.

Nígbà tí ìròyìn pé ó wà nílé ìwòsàn jáde síta, àwọn ajaguntà kan dìde, tí wọ́n sì gba ìjọba lọ́wọ́ rẹ̀.

Onímọ̀ nípa ètò ààbò ìjọba kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Zimbabwe sọ fún BBC pé àwọn adarí máa ń parọ́ nípa ìlera wọn láti mú àdínkù bá bí àwọn èèyàn ṣe le fẹ́ gab ipò lọ́wọ́ wọn.

Àgbẹ̀ kan àti olùkọ́, Abeku Adams sọ pé bí àwọn olórí ṣe máa ń parọ́ nípa ìlera wọn le jẹ́ nǹkan tó wà nínú àṣà.

Ọ̀kan lára bíbo ìlera olórí ni ti ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Nàìjíríà, Umaru Yar’Adua tó sọ fún BBC News Hausa pé ara òun ti ń balẹ̀ nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan lọ́dún 2010.

Fún oṣù márùn-ún ni kò fi sí èèyàn kankan nípò lásìkò tó fi wà nílé ìwòsàn, táwọn èèyàn sì ń gbé ìròyìn pé ọpọlọ rẹ̀ kò ṣiṣẹ́ mọ́ ni.

Bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń ps si nílẹ̀ Áfíríkà, tí wan sì ń kọminú lórí bí àwọn olórí ṣe ń kú sórí ipò, ọ̀pọ̀ wọn ló wòye pé ó yẹ káwọn olórí náà máa túnbọ̀ ṣe àgbéjáde ipò ìlera wọn si.

Adams ní àwọn ìjọba nílò láti máa jẹ́ kí ará ìlú mọ̀ nípa wọn dáadáa si.

Ó tẹmpẹlẹmọ pé níwọ̀n ìgbà tí àwọn ará ìlú bá ti ń san owó orí, wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ̀ nípa ìlera àwọn adarí wọn.