Ṣé lóòótọ́ ni Seyi Makinde fẹ́ kojú Tinubu nínú ìbò ààrẹ ọdún 2027?

Oríṣun àwòrán, Others
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti ní òun tó gbangba sùn lọ́yẹ́, tí òun sì lè fi ẹnu ara òun sọ̀rọ̀ tí òun bá ń wá nǹkan.
Seyi Makinde ló sọ̀rọ̀ yìí láti fèsì sí ìròyìn tí àwọn kan ń gbé kiri pé ó ń wá ipò Ààrẹ níbi ètò ìdìbò ọdún 2027.
Ní ọjọ́ Ẹtì ni Makinde sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ṣàbẹ̀wò sì oko Fashola Farm tó wà ní ìlú Oyo.
Ṣáájú ni àwọn kan ti ń gbé ìròyìn lábẹ́lẹ̀ pé Seyi Makinde fẹ́ díje du ipò Ààrẹ Nàìjíríà níbi ètò ìdìbò gbogbogboo ọdún 2027.
Gómìnà Oyo náà sọ pé kò yẹ kí àwọn ènìyàn máa ṣáájú ṣe ojú ṣàájú tàbí máa hun ọ̀rọ̀ pọ̀ nítorí òun gbójú gbóyà láti sọ nǹkan tí òun bá ń fẹ́ láì gba àṣẹ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni.
Ó ṣàlàyé òun máa jáde sọ̀rọ̀ lórí nǹkan tí òun bá fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú àmọ́ àsìkò ọ̀rọ̀ kò ì tíì tó sọ báyìí.
Ó ní àwọn kò ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nítorí ìfẹ́ ẹnìkan láti jẹ Ààrẹ Nàìjíríà ṣùgbọ́n nǹkan tí òun ní láti sọ ni pé òun máa jáde sọ̀rọ̀ lásìkò tí òun bá ń fẹ́ nǹkan.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àṣeyọrí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olóṣèlú ní ìpínlẹ̀ Oyo, Makinde ní òun kò ní bàbá ìsàlẹ̀ kankan àti pé àwọn aráàlú ló fẹ́ràn òun, tí wọ́n sì yan òun sípò gómìnà.
“Àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Oyo ló pinnu lọ́dún 2019, mi ò ní bàbá ìsàlẹ̀, kò sí ẹni tó ṣe àtìlẹyìn fún mi, àwọn aráàlú ló pinnu láti dán ẹlòmíràn wò.”
Ó wòye pé ṣáájú kí òun tó di gómìnà, níṣe ni àwọn ń gbé ìròyìn pé òun kò ní ìrírí kankan nínú ìṣèjọba nítorí pé òun kò fi ipò òṣèlú kankan mú rí.
Ó wá rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti fún àwọn olóṣèlú láti ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn láyé, kí wọ́n má sọ Naijiria di orílẹ̀ èdè oní ẹgbẹ́ òṣèlú kan ṣoṣo.















