Kọmíṣọ́nà tí ìjọba ní kó lọ rọ́kún ńlé lórí ẹ̀sùn àgbèrè pẹ̀lú abílékọ sọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, Auwal Danladi Sankara/Facebook
Komiṣọna fun akanṣe iṣẹ nipinlẹ Jigawa ti ijọba ti jawe gbele ẹ fun lori ẹsun wi pe o ni ajọṣepọ pẹlu abilekọ kan, Auwal Danladi Sankara, ti sọ pe irọ to jina si ootọ lẹsun ti wọn fi kan oun.
Koda, Sankara ni oun ṣetan lati gbe awọn to wa nidi ọrọ naa re ile ẹjọ.
O ni awọn to wa nidi ọrọ yii fẹ ba oun lorukọ jẹ ni.
Ọlọpaa Hisbah ipinlẹ Kano lo fi ofin Sharia mu Sankara lori ẹsun wi pe o n ni ìbálòpọ̀ pẹlu iyawo oniyawo.
Ọgaagba awọn ọlọpaa Hisbah, Abba Sufi, ṣalaye pe ọkọ obinrin naa, Nasiru Bulama, lo fẹsun kan kọmiṣọna yii pe o n ba iyawo oun ni ajọṣepọ.
Amọ, ninu ọrọ rẹ, kọmiṣọna ti ijọba ti ni ko lọ rọkun nile ọhun ti sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ rara.
O ni ẹsun ti wọn fi kan oun yii ko lẹsẹ nlẹ, ati pe wọn fẹ fi ba oun lorukọ jẹ ni.
Ọgbẹni Sankara ni awọn oloṣelu kan lo wa nidi iroyin yii lati fi le ba oun lorukọ jẹ.
Mo rọ gbogbo eeyan lati kọ eti ikun si iroyin yii - Sankara
"Mo rọ gbogbo eeyan lati kọ eti ikun si iroyin ti wọn gbe jade nipa mi yii tori ọrọ ko ri bẹẹ rara.
Ọkunrin to ni iyawo nile ni mi, tori naa, mi o le ṣe ohunkohun lati tabuku igbeyawo.
Gbogbo ara mi ni mo fi gbaruku alakalẹ ati ofin igbeyawo.
Mi o ni mu ọrọ yii ni kekere o, mo si ti ṣetan lati gbe awọn to fẹ bami lorukọ jẹ yii re ile ẹjọ," Ọgbẹni Sankara lo sọ bẹẹ.
Ẹwẹ, Gomina Umar A. Namadi ipinlẹ Jigawa ti paṣẹ pe ki kọmiṣọna naa ṣe gaaya fun ọfiisi rẹ lọwọ yii titi ti iwadii yoo fi pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.















