Mọ̀ nípa àǹfàní tí iyọ̀ ń ṣe fún ara yàtọ̀ sí fífún oúnjẹ ládùn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ohun ti ọpọ wa mọ nipa iyọ fifi adun si ounjẹ wa ṣugbọn iwadii ijinlẹ sayẹnsi sọ pe ọpọ anfani mii ni iyọ n se ni ago ara wa.
BBC ṣe iwadii lori ipa ti iyọ n ko lara wa ati bi a ṣe le din wọn rẹ ti ko ni pọ lara wa.
Ki ni pataki iyọ jijẹ?
“Iyọ ṣe pataki fun igbesi aye ọmọ ẹda,” Paul Breslin, ọjọgbọn nipa ounjẹ aṣaraaloore ni fasiti Rutgers ni ilu Amẹrika ṣalaye.
“Iyọ jẹ eroja pataki fun ọpọlọ, ọpa ẹyin ati isan ara, paapaa o ṣe pataki fun awọn awọ ara ati egungun ara”
Ọjọgbọn Brealin sekilọ pe ti eeyan ko ba jẹ iyọ, o ṣeese ko ma pẹ laye.
Ti eeyan ko ba jẹ iyọ, o le fa ọpọ ipenija ara bi, eebi, didaku, aimọ nkankan ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ajọ to n ri si eto ilera lagbaye, WHO, gba awọn eeyan ni iyanju pe ki wọn ma jẹ iyọ ni iwọn giramu marun un lojojumọ.
ṣugbọn ọpọ awọn eeyan lo ma n jẹ iyọ to to giramu mọkanla lojojumọ, eyi si le ṣe ọpọlọpọ akoba, to si le fa aisan ọkan, jẹjẹrẹ, ara sisan ati aisan kidinrin.
WHO ni o din diẹ ni milọnu meji eeyan ti wọn padanu ẹmi wọn lọdọdun nitori iyọ jijẹ wọn ti pọju.
Awọn orilẹede to n jẹ iyọ ju

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọpọ awọn orilẹede, iyọ jijẹ wọn pọ nitori awọn ounjẹ to wa ninu agolo.
Awọn eeyan Kazakhstan ma n jẹ iyọ to to giramu mẹtadinlogun lojumọ, eyi to jẹ ilọpọ mẹta ohun ti WHO sọ.
Maryam to n gbe ni Astana, olu ilu Kazakhstan ni awọn ma n mu iyọ nitori ohun ti itan gbe kalẹ fun wọn.
“Fun ọpọ ọdun, ni awọn baba nla wa fi rin irinajo, ti wọn si n fi iyọ pa awọn ẹran pa lara lati ma jẹ ko bajẹ.
Ọmọ Maryam n koju ailera bayii, ti awọn dokita si ti rọ pe ko diwọn iyọ ati suga to n jẹ ku.
Lati igba ni idile Maryam ko ti fi iyọ si ounjẹ mọ.
“Nigba ti a bẹrẹ, ko si adun ninu ounjẹ naa, ko dun mọ wa ninu. A ma jẹ ounjẹ, ko ni mọ iru ounjẹ ti a n jẹ.”
Bawo ni ara wa ṣe maa n ri ti a ba jẹ iyọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
“Iyọ ma n fun ara wa ni agbara,” Ọjọbọn Breslin ṣalaye
Ipa ti ọpọ iyọ jijẹ n se lara pọ, to si n fa ọpọ aisan si ago ara.
O le ni bilọnu kan eeyan ti wọn ṣe aisan ẹjẹ riru.
Dindin iyọ ku ṣe ọpọ anfani fun ara wa.
Ni orilẹede UK, wọn ti mu adikun ba iye iyọ ti wọn n fi si ounjẹ wọn si giramu mẹjọ lojumọ
Ko rọrun lati mu idinku ba iyọ ti eeyan n jẹ sugbọn o se koko nitori eewu to dirọ mọ.
Bi iyọ se ni anfani to, bẹẹ naa ni o fa ọpọ aisan ti o ba pọ.
Ọjọgbọn Claire Collins, ti fasiti Newcastle ni orilẹedde Australia rọ awọn eeyan lati ma jẹ awọn ounjẹ ti ko nilo iyọ pupọ.
“Ti o ba n se ounjẹ, fi awọn ohun aladun miiran si lati dipo iyọ”















