Mọ̀ nípa ètò 'Nutrition 774' tí ìjọba àpapọ̀ gbé kalẹ̀ láti gbógun ti ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Pẹlu bi ọwọngogo se gbode bayii lorilẹede Naijiria, ijọba apapọ ti gbe eto kan kalẹ lati gbogun ti airi ounjẹ asara loore jẹ, eyi ti igbakeji aarẹ, Kashim Shettima se ifilọlẹ rẹ.
Eto naa ti wọn pe orukọ rẹ ni ‘Nutrition 774 initiative’ ni ajọ NEC ti buwọlu lati mojuto jijẹun kanu ati ounjẹ to saara loore kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ 774 lorilẹede Naijiria.
Ifilọlẹ naa lo waye ni ọfiisi aarẹ niluu Abuja lẹyin ipade kan to waye pẹlu awọn to ṣagbatẹru eto naa.
Igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima ni eto ọhun jẹ ọkan lara ọna ti Aarẹ Bola Tinubu fẹ lo lati jẹ ki ounjẹ pọ jaburata ni Naijiria.
Ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ si igbakeji aarẹ, Stanley Nkwocha fi lede, Shettima ni “ọkan gboogi ni pipese ounjé fun Aarẹ Tinubu, ti ijọba si setan lati se ohun to tọ lati ri pe ijọba gbogun ti airi ounjẹ asara loore jẹ.
“Ero wa gẹgẹ bii orilẹede ni lati ni ọpọ ounjẹ ni ipamọ kaakiri.
A ko le ni a ti se aṣeyọri ti a ko ba ti ri pe gbogbo ile ni anfaani si ounjẹ to ṣaara loore,” Igbakeji Aarẹ ṣalaye.
Ibi ipade apero nipa ọrọ aje ni oṣu to kọja ni wọn ti fi ontẹ lu eto ‘774 Nutrition’ gẹgẹ bi eto ẹṣẹ kuuku lati gbogun ti aijẹunkanu ni orilẹede Naijiria.
Bakan naa ni NEC rọ awọn onigbọwọ pẹlu ijọba lati pese iranlọwọ owo nlati gbe eto naa siwaju.
Igbakeji aarẹ fikun ọrọ rẹ pe eto “Nutrition 774’ jẹ idaniloju fun awọn ọmọ Naijiria - ọmọde ati agbalagba, tọkọtaya tabi awọn ti ko ti laya tabi iyawo nile, lati guusu lọ si ariwa.
“Gbogbo owo naira ti a ba na lori igbese yii ni a o ri pada ni ọpọ igba - ki se fun ilera awọn eeyan wa nikan sugbọn fun ilọsiwaju ati eto aabo ati ọjọ ọla lorilẹede wa.
Ki ni anfaani to wa ninu eto 'Nutrition 774'?
Gẹgẹ bii Igbakeji aarẹ se ṣalaye, eto naa wa fun amojuto ounjẹ to ṣara loore laarin awọn ọmọ orilẹede Naijira.
Bẹẹ ba gbagbe, awọn agbegbe kan lapa ariwa ti n koju airi ounjẹ to ṣe ara loore jẹ.
Ijọba ni pẹlu bi awọn onigbọwọ ati awọn alatilẹyin se ti fẹ se iranlọwọ igbọwọ pe airi ounjẹ to se ara loore jẹ yoo di ohun igbagbe lorilẹede Naijiria.
Igbakeji Aarẹ Shettima ni eto yii se koko fun ọjọ ọla orilẹede Naijiria.
Kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ to wa lorilẹede Naijiria ni eto yii yoo ti waye.















