Kọ̀nténà wó lu mọ́tò ọkọ àti ìyàwó mọ́lẹ̀ nílùú Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, Ogbomoso Insight
Ori ko ọkọ ati iyawo kan yọ lọsan an Ọjọbọ niluu Ogbomoso lẹyin ti koto ikẹru kọntena ti ọko ajagbe tirela kan gbe ja lu mọ lori.
Ni agbegbe Ogbomoso High School ni a gbọ pe kọntena naa ti jabọ le ọkọ awọn tọkọ taya yii lori lẹyin tirela to gbe e pẹlu nọmba JZ 101 ZA.
Ohun ti a gbọ ni pe lẹyin iṣẹju diẹ tawọn lọkọ laya naa gbe ọkọ wọn silẹ ti wọn si lọ ra awọn nnkan kan ni ijamba yii ṣẹlẹ.
O ṣoju mi koro kan ṣalaye fun iwe iroyin OgbomosoInsightonline wi pe ‘’Eledeua lo ko ọkọ ati iyawo naa yọ ninu ewu nla.
Ko pẹ rara tawọn tọkọ taya ọhun kuro ninu mọto wọn lati lọ ra nnkan ni iṣẹlẹ yii waye.
Amọ, a dupẹ lọwọ Ọlọrun wi pe ko si ẹnikan kan ninu ọkọ naa nigba ti kọntena naa wo lu u mọlẹ.’’
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ tun ṣalaye pe awakọ tirela ọhun to n bọ lati ọna ilu Oyo n gbiyanju lati ma le kọlu ọkọ bọọsi kan ti awakọ rẹ n tẹ foonu, bayii ni ko ṣe le ri tirela naa dari mọ ti ijamba naa fi ṣẹlẹ.
‘’Nigba ti awakọ tirela naa gbiyanju pe koun ma baa kọlu bọọsi naa ni o yẹ si koto lẹba ọna ti kọntena ẹyin rẹ si wo lu ọkọ tọkọ taya naa mọlẹ.















