Ilé-ẹjọ̀ kòtẹ́mílọ́rùn dá Dókítà Olaleye tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n gbére lórí ẹ̀sùn ìfipá bọ́mọdé lòpọ̀ láre

Oríṣun àwòrán, Dr Femi/Instagram
Ile-ẹjọ kotẹmilọrun nipinlẹ Eko ti sọ pe ki Dokita Olufemi Olaleye ti wọn da ẹjọ ẹwọn gbere fun lori ẹsun fifi ipa ba ọmọ kekere lajọṣepọ ti wọn fi kan an maa lọ lalaafia.
Oni, ọjọ Ẹti, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun 2024 ni Onidajọ Olukayode Bada da Olaleye silẹ wi pe ko maa lọ sile nitori pe ko jẹbi ẹsun ti wọn fi ju u sẹwọn lọdun to kọja.
Inu oṣu kẹwaa, ọdun 2023 ni Onidajọ Rahman Oshodi ti ile ẹjọ to n gbọ ẹsun ifipabanilopọ nipinlẹ Eko ju Olaleye sẹwọn gbere, lori ẹsun wi pe o ba ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹrindinlogun laṣepọ.
Ile-ẹjọ naa sọ pe awọn iwa ti Olaleye n hu lasiko ti wọn n gbọ ẹjọ rẹ lọwọ, ati pe ko ṣebi ẹni ti ọrọ naa ka lara, lo fa a ti wọn fi da ẹjọ ẹwọn gbere fun un.
Lẹyin idajọ naa ni Olaleye to jẹ alakoso agba ni ile iwosan oju ti ipinlẹ Eko, iyẹn Optimal Cancer Care Foundation pe ẹjọ kotẹmilọrun, to si jẹ ko di mimọ pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti wọn fi kan oun.
Ẹri to wa lati ọdọ iyawo ati ọmọ ti wọn lo fipa ba laṣepọ ko papọ - Ile-ẹjọ
Ile-ẹjọ kotẹmilọrun sọ pe awọn ẹri ti ẹlẹri mẹfa to yọju sile ẹjọ lati tako Olaleye niwaju ile-ẹjọ ko papọ mọra wọn, bẹẹ si ni ko si ẹri kankan to fidi rẹ mulẹ wi pe lotitọ ni Olaleye fipa ba ọmọ ọhun laṣepọ.
Bakan naa ni ile-ẹjọ kotẹmilọrun tun bu ẹnu atẹ lu onidajọ to ju Olaleye sẹwọn gbere wi pe niṣe lo fi imọ-tara-ẹni ṣe idajọ naa, leyi to ni ko bojumu to.
“Abọ igbesẹ mi ni si ipinu ile-ẹjọ naa jẹ eyi to ya ni lẹnu. Fun idi eyi, mo da Dokita Olufemi Olaleye lare lati maa lọ layọ ati alaafia,” adajọ sọ bẹẹ.
Ile-ejọ fidi rẹ mulẹ pe iyawo Dokita Olaleye lo gba foonu ọkọ rẹ lati maa fi fi awọn ẹri kan ranṣẹ loriu imeeli, eyi ti wọn le lo lati fi tako ọkọ rẹ nile ẹjọ.
Gẹgẹ bi ile-ẹjọ ṣe ṣalaye, dokita naa ati iyawo rẹ ti wa nile ẹjọ tẹlẹ lati pinya, ati pe mimu obinrin naa wa sile ẹjọ lati wa duro gẹgẹ bi ẹlẹri ko ba ilana mu, nitori bo ṣe ni ifẹ si ẹjọ naa to tako ọkọ to fẹẹ kọ silẹ.
Ile-ẹjọ sọ pe, “O ti lọ ṣe paṣipaarọ iwe ọkọ ọkunrin naa si ti ara rẹ lai jẹ ki ọkunrin naa mọ, o tun gbiyanju lati ta ile rẹ, koda to tun gbiyanju lati yọ ontẹ ọkọ rẹ kuro ninu apọ iṣuna ti wọn jọ n lo nile ifowopamọ, ati paapaa o tun gbiyanju lati ko awọn ọmọ salọ soke okun lai jẹ ki ọkọ rẹ mọ.”
Gbogbo awọn nnkan wọnyi lo waye lasiko ti ọkunrin naa wa lahamọ awọn agbofinro nigba ti ẹjọ rẹ n lọ lọwọ nile ẹjọ.
“Ko yẹ ki ile-ẹjọ kekere gba awọn ẹri ọmọ naa jẹ, nitori pe awọn ọrọ rẹ ko ba ara wọn mu.”
Ile-ẹjọ kotẹmilọrun ni o ṣee ṣe ko jẹ pe nitori awọn ohun ti obinrin naa fẹẹ ri gba bii owo, dukia ati awọn ọmọ lo fa a, to fi duro lati tako ọkọ rẹ niwaju ile-ẹjọ.
“Niṣe lo yẹ ki wọn farabalẹ fun awọn ẹri obinrin naa, nitori pe o ni lati fura si,” ile-ẹjọ ṣalaye.
Awọn ẹri fi han wi pe iyawo dokita naa lu ọmọdebinrin ọhun lalubami ni ọjọ meji ko to di pe wọn jẹri lati purọ mọ ọkunrin naa wi pe oun lo fipa ba a laṣepọ.
“Ohun ti mo ri sii ni pe ko yẹ ki ile-ẹjọ kekere naa gba awọn ẹri ọmọ naa jẹ, nitori pe awọn ọrọ rẹ ko ba ara wọn mu.”
Ile-ẹjọ agba naa sọ pe aṣiṣẹ nla ni ile-ẹjọ kekere ọhun ṣe lati ran Dokita Olaleye lẹwọn nitori pe ẹri iyawo dokita ati ọmọkekere naa ko ba ara wọn mu.
Labẹ ofin, awọn ẹri ọmọ kekere gbọdọ ba ara wọn mu ko to di pe ile-ẹjọ lo o.
Bakan naa ni ile-ẹjọ tun sọ pe magomago wa laarin ẹjọ ti wọn gbe wa sile ẹjọ ati ohun ti iwe ayẹwo ọsibitu sọ.
“Ẹri ko fidi rẹ mulẹ pe ibalopọ to waye laarin awọn mejeeji naa kii ṣe nipa ipa”, ohun ti ile-ẹjọ kotẹmilọrun sọ leyi.
Gẹgẹ bi ile-ẹjọ tun ṣe ṣalaye siwaju, fọnran ẹri ti wọn ri gba fi han daju pe ọmọdebinrin naa n ni ifẹ ikọkọ pẹlu ẹni to n ṣi geeti ile wọn, ati pe ki lo wa fa a to fi jẹ pe dokita ni wọn da ẹjọ fun.
Onidajọ Olukayode Bada sọ pe gbogbo awọn igbimọ oludajọ kotẹmilọrun naa ni wọn faramọ idajọ ọhun
Olupẹjọ Ọgbẹni Babajide Martin lo ṣoju ipinlẹ Eko, nigba ti Amofin Chukwudi Enebeli lewaju igbimọ agbẹjọro fun dokita.















