Arákùnrin tó fẹ́ fi ìyá rẹ̀ ṣe ògùn owó fi májèlé sí oúnjẹ pa ìyá rẹ̀, ìyá-ìyá rẹ̀, àbúrò ìyá rẹ̀ obinrin àti ọmọ rẹ̀

aworan olu ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Enugu

Oríṣun àwòrán, EnuguPolice/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Enugu ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori ọkunrin kan, ẹni to ṣekupa iya rẹ, iya-iya rẹ, aburo iya rẹ obinrin ati ọmọ aburo iya rẹ.

Iṣẹlẹ yii waye niluu Enugu ni agbegbe Amaeze.

Afurasi naa ni orukọ rẹ n jẹ Anaegbuachara.

Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ṣẹ̀ gan?

Gẹgẹ bii iroyin to tẹ BBC lọwọ, iṣoro Anaegbuachara bẹrẹ nigba to lọ si ọdọ alawo lati se oogun owo nini.

Anaegbuachara, nigba ti ọwọ tẹ, ṣalaye pe otitọ ni oun fi majele si ounjẹ ti gbogbo awọn eeyan to ku naa jẹ.

Iroyin sọ pe ọrẹ Anaegbuachara lo mu mi lọ si ọdọ alawo fun ogun owo.

Alawo yii la gbọ pe o fun un ni ogun ti yoo lo fun iya rẹ lati fi ṣe ogun owo.

Idari ti babalawo fun arakunrin naa ni pe inu ounjẹ ti iya rẹ ba fẹ jẹ ni yoo fi oogun abẹnugọngọ naa si.

Gẹgẹbi awọn iroyin ti a gbọn ṣe sọ, Arakunrin naa mọ pe majele ni Babalawo naa fun oun, ṣugbọn ipinnu rẹ lati ṣẹṣo ko daa lọwọ kọ.

Nigba to fi majele ọun si inu ounjẹ to gbe fun iya rẹ ni iya pẹlu ba pin ounjẹ naa jẹ pẹlu iya-iya rẹ, aburo iya rẹ ati ọmọ aburo iya rẹ naa.gbogbo awọn mẹrẹẹrin to jẹ ounjẹ yii ni wọn gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.

Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ?

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Daniel Ndukwe sọ fun BBC pe ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Daniel Ndukwe sọ pe, "Ohun ti a fi to mi leti ni pe ọwọ awọn agbofinro ti tẹ gbogbo awọn ti wọn funra si pe wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ yii".

alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Enugu naa tun ṣalaye siwaju sii pe iwadii ti n lọ lọwọ.