Ọdún kẹwàá tí Boko Haram pa èèyàn 100 ní mọ́ṣáláṣí ìlú Kano, ipò wo làwọn èèyàn ìlú náà wà báyìí?

Aworan mọṣalaṣi naa.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkan lara ikọlu ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram to buru julọ ni Naijiria ni eyii ti wọn ṣe si Mọṣalaṣi nla ilu Kano, iyẹn, Grand Juma Mosquelọdun mẹwaa sẹyin.

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2014 ni ikọlu naa waye ti gbogbo ipinlẹ naa si mi titi.

Oni gan lo pe ọdun mẹwaa gerege ti iṣẹlẹ naa waye, awọn ti ọrọ naa kan ko si tii gbagbe ipa manigbagbe ti ikọlu ọhun ko ninu aye wọn.

Ọsan gangan lasiko ti irun Jimoh n lọ lọwọ ni ibugbamu Boko Haram naa waye, ninu eyii ti ọpọ ẹmi eeyan ti sọnu, ti pupọ lara wọn si jẹ Musulumi.

Lọdun naa lọhun, awọn agbofinro sọ pe o le ni ọgọrun un eeeyan too ba iṣẹlẹ naa lọ.

Amọ ṣa, o ṣeeṣe ki iye eeyan ku nibẹ ju iye ti awọn agbofinro kede lọ.

Igbeaye ọpọ eeyan ni Kano lo ti yipada latari ikọlu naa atawọn ikọlu lemọlemọ mii to ti waye lẹyin rẹ ni Kano.

Bi ikọ agbesunmọmi Boko Haram ṣe n kọlu olowo ni wọn n kọlu talaka, bẹẹ naa ni wọn n kọlu ọba, araalu awọn ọmọlẹyin Kristi atawọn Musulumi ni Kano.

Oniruru igbesẹ ni ijọba igba naa gbe lati dena irufẹ ikọlu bẹẹ.

Lara irufẹ igbesẹ ọhun ni ṣiṣe ayẹwo awọn ọkọ to n lọ loju popo, fifi ofin de irinajo alẹ, kiko igi di oju popo ati ṣiṣe ayẹwo awọn to ba n wọ inu Mọṣalaṣi tabi ṣọọṣi.

Wayi o, lẹyin ọdun mẹwaa lẹyin ikọlu ọhun, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan naa ko le gbagbe iṣẹlẹ naa titi ayeraye, awọn eeyan ilu Kano ti n gbe igbeaye wọn pada bii pe ko si ewu kankan fun wọn mọ.

Bi ibugbamu naa ṣe waye

Igba mẹta ọtọtọ ni awọn eeyan gbọ iromibugbamu ni mọṣalaṣi naa ọhun lọsan an ọjọ Eti ọhun.

Lẹyin naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram to wa nibẹ tun ṣina ibọn bolẹ fun awọn to moribọ lọwọ ado oloro ti wọn dana rẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti a mọ, fẹgbẹkẹgbẹ ile Emir ilu Kano ni mọṣalaṣi ti wọn kọlu naa wa.

Ṣaaju ikọlu ọhun ni Emir ilu Kano ti maa n bu ẹnu atẹ lu awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram, to si maa n sọ pe ohun ti wọn n ṣe ko ba ilana ẹsin Musulumi mu.

Aarẹ Naijiria lọdun naa lọhun, Goodluck Ebele Jonathan ba awọn eeyan ipinlẹ Kano lapapọ kẹdun awọn to ku, o si ṣeleri lati fi ṣikunofin mu gbogbo awọn kọlọrọsi to lọwọ ikọlu naa.