Èèyàn mẹ́rìn kú níbi àjọ̀dún ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n ní kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀

Aworọn ọgọrọ ero

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àkọlé àwòrán, Aworan ibi ṣẹlẹ naa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọjọ buruku, eṣu gbomimu lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2024 jẹ ninu itan ile ijọsin Aguda ẹkun Aba ni ipinlẹ Abia lasiko ti wọn n ṣe ajọyọ ajọdun "Christ The King", ẹlẹẹkẹrinlelọgbọn iru ẹ nibi ti awọn olujọsin ku.

Ninu atẹjade ti olori ijọ naa, Biṣọọbu Augustine Ndubueze Echema toun naa wa nibi iṣẹlẹ naa fi sita, lasiko apejọpọ ọlọpọ ero fun ajọdun naa lawọn eeyan naa ti ku.

Ijọ naa sọ pe iṣẹ iwadii ṣi n lọwọ lati mọ awọn to pada iku ojiji, ati ohun to ṣokunfa iku wọn. Bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọ iye awọn to ku tabi ti wọn farapa.

Bẹẹ ni wọn fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn, ati ọrọ iyanjuu si awọn to farapa, pẹlu ileri iranlọwọ to yẹ lasiko ibanujẹ naa.

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?

Ohun ti a gbọ ni pe iṣẹlẹ aburu naa waye nigba ti ọpọ ero korajọ niwaju ati ayika ile ijọsin CKC to wa niluu Aba lati ṣayẹyẹ 'Christ The King Procession', eyi ti wọn pe ni 'Corpus Christi'.

Bi wọn ti ṣayẹyẹ naa niluu Aba, naa ni wọn tun n ṣe e kaakiri gbogbo ijọ Aguda to wa lagbaye.

A gbọ pe bi ero ọhun ṣe pọ lo fa ooru, eyi ti ko faaye gba atẹgun pupọ lati fẹ, idi ree ti awọn kan fi bẹrẹ sii ṣe daku.

Loju ẹsẹ ni wọn lawọn to n daku naa ti ṣubu lulẹ, to fa a ti awọn eeyan fi n tẹ wọn mọlẹ, nitori aisi aaye lati mu ẹsẹ si.

Pẹlu gbogbo igbiyanju ni wọn sọ pe awọn to wa nibẹ fi sare gbe wọn lọ sile iwosan to wa nitosi fun itọju, ati lati doola ẹmi wọn.

A gbọ pe awọn kan jade laye nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ, nigba ti awọn yooku ṣi wa nibi ti wọn ti n gba itọju lọiwọ.

Lara awọn to ku naa la ti gbọ nipa iya agbalagba meji, ọmọdekunrin ati ọmọdebinrin kan.

'Eyi kii ṣe igba kọkọ ti iru iṣẹlẹ bẹẹ yoo maa waye'

Aworan ọpọ ero

Oríṣun àwòrán, screenshot

Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn, Chinenye sọ fun BBC pe “awọn eeyan wa sibẹ pẹlu ongbẹ, eyi to jẹ ko ṣoro fun wọn lati min.

“Eyi kii ṣe igba akọkọ ti awọn eeyan yoo maa ku lasiko eto bayii, ṣugbọn igba akọkọ ree ti mo maa wa nibi irufẹ iṣẹlẹ na.

“Oorun pọ gidi lọjọ naa, awọn kan tiẹ wa to jẹ pe ko yẹ ki wọn wa sibi eto ayẹyẹ yii. Bi awọn agbalagba, ọmọde, arugbbo, alaboyun, to fi mọ awọn to n tọmọ lọwọ.”

Chinenye sọ pe yoo dara ti awọn alakoso ijọ naa ba fi le wa ọna ti wọn yoo fi mu adinku ba awọn ti yoo maa wa sibi ayẹyẹ ọlọdọọdun naa.

O ni ki wọn sọ fawọn eeyan lati ṣe ayẹyẹ ni ijọ ti wọn ba n lọ, dipo ki wọn kan wa korajọ

Bakan naa ni ẹnikan to pe orukọ ara rẹ ni Ebere ni tiẹ jẹ ko di mimọ pe ijamba ọhun bẹrẹ ni kete ti awọn kan bẹrẹ sii da owo soke, ti awọn eeyan si n fo lati mu.

“Bi awọn eeyan ṣe n gbiyanju lati fo soke mu owo, ni wọn bẹrẹ sii tẹ ara wọn mọlẹ, eyi to ṣokunfa iku ojiji naa.”