Àtúnṣe owó orí mú ifura dáa ni – Ndume, Zulum

Oríṣun àwòrán, BBC/other
Òfin owó orí tuntun mú ìfurà dání, ẹ̀kùn àríwà Nàìjíríà takò ó – Ndume
Aba lati sọ atunto eto ilana owo ori sisan tuntun ti Aarẹ Bọla Tinubu gbe ka iwaju ile aṣofin apapọ Naijiria di ofin ti n fa ọkanojọkan awuyewuye jakejado orilẹede Naijiria bayii.
Ṣaaju agbekalẹ aba naa niwaju ile lawọn eekan lawujọ, paapaa lati ẹkun ariwa Naijiria ati igbimọ eto ọrọ aje ni Naijiria ti ke si aarẹ pe ko da ọwọ duro lori ilana owo ori tuntun naa.
Ki aarẹ Tinubu to sọ fun mutumuwa pe gẹgẹbi aṣoju araalu ti ofin ilẹ Naijiria damọ, ile aṣofin apapọ nikan lo lee ọ boya awọn ọmọ Naijiria ko fẹ ilana tuntun naa tabi wọn fẹ ẹ.
Lara awọn to n tako abadofin ilana owo ori sisan tuntun yii ni ọkan gboogi lara awọn sẹnetọ Naijiria, Ali Ndume to n ṣoju ipinlẹ Borno, ati ỌjọgbọBabagana Umara Zulum.
Ki ni Sẹnetọ Ali Ndume sọ lori ilana owo ori sisan tuntun naa?

Oríṣun àwòrán, Others
Sẹnetọ to n soju guusu ipinlẹ Borno, Ali Ndume ti koroju si ile igbimọ aṣofin ṣe fẹ suure buwọlu abadofin to n pe fun atunse owo ori.
Ndume ni bi ileeṣẹ Aarẹ ati awọn aṣofin kan se fẹ suure buwọlu ofin naa lo mu ifura daa ni.
Ofin atunse owo ori ni o ti kọja ipele keji ni ile igbimọ aṣofin, to si ti fa ọpọ ariyanjiyan lati igba ti Aarẹ Bola Tinubu ti fi ofin naa ranṣe si ile igbimọ aṣofin agba.
Ajọ to n risi eto ọrọ aje lorilẹede Naijiria ti gba aarẹ ni imọran lati jawọ ninu ofin naa sugbọn ileeṣẹ Aarẹ kọ jalẹ.
Ndume lasiko to n ba ileeṣẹ momaworan kan sọrọ ni oun duro le ohun ti oun sọ, ni ko ba dara ti ileeṣẹ Aarẹ ba le gbọ ọrọ si ajọ to nsi eto ọrọ ajẹ lẹnu.
“Ẹ da ofin yii da, ẹ se iwadii, ẹ gbe ofin naa pada. Ki lo de ti a n kanju.”
O ni isọrọ kan ti oun ni pẹlu ofin owo ori yii ni pe ko se ni asiko yii,
“Ko yẹ ki wọn gbe ofin yii wa lasiko tii ọpọ ọmọ Naijiria n la inira kọja.
O ni ki se pe oun ati awọn amofin to tako ipe naa ko fẹ ki awọn araalu san owo ori ṣugbọn asiko ti wọn gbe wa yii ko dara.
“Mo tako asiko ti wọn gbe ofin naa wa nitori ọpọ ọmọ Naijiria lo n la nnkan kọja . Awọn baba nla wa san owo ori, a n san owo ori ni apa ariwa.
“Ko ki n se pe a n sa lati san owo ori, a n san owo ori, ti gbogbo ọmọ Naijiria si fẹ san owo ori yii ṣugbọn asiko yii ko dara rara.”
Ndume tẹsiwaju pe asiko to dara lati gbe ofin naa jade ni ti ko ba si ebi mọ lorilẹede Naijiria.
O ni ofin naa da bi pe ki eeyan fi ọwọ ọtun fi fun eeyan nikan, fi to si gba pada .
A ti pinnu lati tako atunṣe owo ori ti Aarẹ gbe jade- Zulum

Gomina ipinlẹ Borno ni ijọba yoo sisẹ papọ pẹlu ile igbimọ aṣofin lati apa ariwa orilẹede Naijiria lati tako afikun owo ori ti Aarẹ fẹ ki ile igbimọ aṣofin buwọlu ni kiakia.
Ọjọgbọn Babagana Umara Zulum ni ọpọ ofin ni wọn am jiroro lori rẹ fun igba pipẹ, ṣugbọn eyi ni ileeṣẹ aarẹ fẹ ki wọn buwọlu ni kiakia.
Zulum ni ki se apa ariwa nikan awọn eeyan ti tako ofin, ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo kọ ẹyin si ofin naa.
O ni o yẹ ki aarẹ Tinubu ranti apa ariwa lo ti ni ida ọgọta ibo to gbe wọle.
”Asiko ti to fun awọn eeyan wa kati dide, paapa awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin to n soju apa ariwa lati da bobo ẹtọ ọmọniyan awọn eeyan wa.
“Ti wọn ba fi le buwọlu ofin yii, ebi, ọwọngogo yoo gbode lorilẹede Naijiria.















