Àìsàn wo ni wọ́n ń pè ní PCOS, èyí tó mú kí àwọn obìnrin kan máa hu irungbọ̀n?

Theresa Mumbai, obìnrin kan láti orílẹ̀ èdè Kenya to ni irùngbọ̀n
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Bo tilẹ jẹ pe ohun to wọpọ ti awọn eeyan mọ ni pe ọkunrin lo maa n ni irungbọn, irunmu ati irun aya, sibẹ, lẹẹkọọkan, a maa n ṣalabapade awọn obinrin naa ti wọn maa n ni iru awọn irun wọnyi.

Eyi si ti wa mu ki awọn kan maa beere ibeere wi pe boya awọn irun to n jẹyọ loju ati eyikeyi ara awọn obinrin jẹ iṣoro, tabi pe bo ṣe yẹ ko wa niyẹn?

Idi ree ti BBC ṣe lọ ba Dokita Sadiya Musa Gwadabe, to jẹ akọṣẹmọṣẹ oniṣegun nipa ohun to n ṣẹlẹ lagọ ara ti a mọ si Obstetrics ati Gynecology ni ọsibitu awọn olukọni tipinlẹ Kwara sọrọ latio ṣewadii siwaju.

Ki lo de ti iru awọn irun bayii ṣe n jẹyọ lara awọn obinrin?

Gẹgẹ bi Dokita Sadiya ṣe ṣalaye, idi pataki ti awọn obinrin kan ṣe maa n ni irun lawọn ibi ti wọn mọ mọ ọkunrin ni pe o maa n ṣẹlẹ nigba ti kẹmika kan ti wọn n pe ni Androgen ti wọn tun n pe ni Testosterone ba pọ ju lagọ ara obinrin.

“Ati ọkunrin ati obinrin ni wọn ni nnkan wọnyi lara. Ṣugbọn ti awọn ọkunrin pọ ju ti awọn obinrin lọ, idi si ree to fi jẹ pe ti testosterone naa ba pọ ju lara obinrin, awọn irun maa n jẹyọ lara wọn lagbegbe ti wọn mọ mọ awọn ọkunrin.

“Bi apẹẹrẹ rẹ si ni irungbọn, irun imu tabi aya, tabi ikun ati awọn ibomiran,” gẹgẹ bi dokita ṣe ṣalaye.

Eyi ni wọn n pe ni Hirsutism ni ede Turkish.

Njẹ arun ni tabi bẹẹ kọ?

Irufẹ agbegbe ti irun naa ba ti wa ni yoo ṣalaye.

Dokita naa sọ pe irun to yọ loju ati lawọn agbegbe agọ miran kii dun wọn, bẹẹ si lawọn miran maa n dun wọn.

“Idi ti mo fi sọ eyi ni pe lawọn igba miran ti a ba ṣayewọ fun awọn obinrin ti wọn ni irufẹ awọn irun yii, a kii ri idi pataki, ohun to ma n ṣẹlẹ la n pe ni ‘Idiopathic’ – iyẹni ni pe, ohun to maa n fa irun to n yọ yii ni ipadanu,” dokita sọ bẹẹ.

Ju gbogbo rẹ lọ, o tun maa n nidi pataki ti awọn nnkan wọnyi fi n ṣẹlẹ lara irufẹ awọn obinrin bayii:

  • Iṣoro nipa ijakulẹ aile yin ẹyin, eyi to maa n fa iṣoro fun awọn obinrin lati loyun latilẹ
  • Awọn apẹẹrẹ bii aisan jẹjẹrẹ, iyẹn ni pe nigba ti aisan jẹjẹrẹ ba jẹyọ nibi ti irufẹ awọn irun yii ti n jẹyọ. Nigba miran, awọn alaboyun miran maa n ri nnkan wọnyi to n ṣẹlẹ si wọn.
  • Awọn obinrin yii kii ri nnkan oṣu wọn deedee. Wọn kii da ẹjẹ fun oṣu mẹta tabi ju bẹẹ lọ.
  • Igba naa lẹ maa ri irun to n jẹyọ loju wọn.
Aworan obinrin to hu irugbọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Harnaam Kaur

Ki lo maa n fa Hirsutism?

Gẹgẹ bi dokita naa ṣe ṣalaye siwaju, arun kan wa ti wọn n pe ni Polycystic Ovarian Syndrome (POS).

"Bi obinrin ba ni iṣoro to nii ṣe pẹlu oju ara rẹ to n yin ẹyin loṣu – nibi to ti n ri nnkan ọmọbinrin rẹ - ti ko ba loyun, o le ni iṣoro.

“Idi niyẹn to fi jẹ pe bi obinrin ba ni iṣoro, o le ni irun loju, ikun tabi aya rẹ.”

Bawo ni obinrin ṣe le mọ pe oun ni Hirsutism?

Dokita Sadiya tun ṣalaye pe awọn obinrin to n koju ipenija yii kii ri nnkan oṣu wọn loṣooṣu.

“O le gba awọn obinrin miran ni oṣu mẹta, awọn miran ni oṣu mẹfa ko to di pe wọn ri nnkan oṣu wọn, tabi ko bẹrẹ sii dawọ duro diẹdiẹ, ko to duro patapata.

“Bi ẹ ba beere lọwọ awọn to n koju iṣoro yii, wọn maa sọ fun un yin pe irun n jẹyọ loju wọn. Bi ẹ ba si wa wo ara wọn, ẹ maa ṣakiyesi pe wọn ni irun nikun bii ti ọkunrin.

“Bi ẹ ba si ya aworan ikun wọn, ẹ maa ri ọpọlọpọ ẹyin nibujoko ti wọn ko tii farahan. Awọn nnkan wọnyi ni apẹẹrẹ ti ẹ maa ṣalabapade.”

Nipa bi a ṣe n ṣayẹwo arun yii, Dokita Sadiya sọ pe:

Awọn maa n ṣayẹwo Testosterone nigba ti obinrin ba ni irun loju. Ti ayẹwo naa ba sọ pe ohun to jẹyọ din ni igba, o ti fi han pe ko ni arun jẹjẹrẹ niyẹn.

“Awọn ayẹwo kan wa ti a maa n ṣe lati fi mọ ohun ti a n pe ni POS. A tun maa n ṣe awọn ayẹwo miran siwaju lati fi mọ ibi ti iṣoro ti wa.”

Atubọtan arun POS

Awọn omidan

Fun awọn obinrin ti wọn ko tii lọ sile ọkọ, nnkan ọmọbinrin rẹ yoo maa tan an jẹ, iyẹn ni pe kii ṣe oṣooṣu ni yoo maa ri nnkan oṣu rẹ, tabi pe ko maa wa segesege, Dokita Sadiya sọ eyi.

“Nigba miran, bi ẹ ba beere lọwọ obinrin bẹẹ, o maa sọ pe o ti lọ, oun ko si tii ri lati bi oṣu mẹta sẹyin.”

Awọn adelebọ

“Fun awọn obinrin ti wọn ti wa nile ọkọ, ti wọn si n fẹ lati loyun, wọn maa n ri gẹgẹ bi idaduro nigba miran, fun idi eyi, wọn ni lati loogun ko to di pe wọn loyun.”

Njẹ o pọn dandan lati ṣe itọju rẹ?

Idahun naa nii ṣe pẹlu ohun to ṣokunfa iṣoro ọhun.

Dokita Sadiya sọ pe: “Bi ko ba sohun to fa a, nigba miran a maa n gba wọn niyanju lati ge irun wọn. Bi a ba si mọ ohun to ṣokunfa rẹ, a maa n fun wọn loogun to maa jẹ ko dinku, tabi ka tọju ohun to n fa a.”