Ààrẹ tó dàgbà jù láyé ń bèèrè ìbò àwọn ọ̀dọ́ lẹ́yìn ọdún 43 nípò

Oríṣun àwòrán, Reuters
Aarẹ Paul Biya ti orilẹede Cameroon lo dagba ju lagbaaye ninu awọn aarẹ, ẹni ọdun mejilelaadọrun-un (92) ni bayii. Sugbọn o ṣi fẹẹ kopa ninu ibo aarẹ orilẹede naa ti yoo waye lọla, ọjọ Aiku, ọjọ kejila, oṣu Kẹwaa ọdun 2025.
Igbiyanju lati kopa ninu ibo naa lo mu Aarẹ Biya maa beere atilẹyin ọdọ awọn ọdọ ati awọn obinrin orilẹede Cameroon, to si n ṣeleri fun wọn pe wọn yoo gbadun oun bi wọn ba ṣe toun lẹẹkan si i.
"Mo maa mu ileri ti mo ṣe fun yin ṣẹ ti ẹ ba dibo fun mi"
Biya lo sọ bẹẹ nibi ipolongo ibo rẹ lọjọ Iṣẹgun to kọja, lẹyin ti ọpọ atako ti dide si i lati ma ṣe dupo naa mọ lẹyin ọdun mẹtalelogoji (43) to ti n ba a bọ.
Ọdun 1982 ni Paul Biya ti wa nipo aarẹ orilẹede Cameroon, oun si ni ọpọ eeyan nilẹ naa gbọjunba nipo olori orilẹede.
O le ni ida ọgọta eeyan (60%) ti wọn jẹ ọdọ ninu eeyan ọgbọn miliọnu to wa ni Cameroon.
Ọdun meje ni saa kan, eyi to n du lọwọ yii ni saa kẹjọ rẹ, to ba si wọle ibo naa, yoo di aarẹ to ṣee ṣe ko pe aadọta ọdun lori aleefa, yoo si ti fẹrẹ to ẹni ọgọrun-un ọdun (100) nigba naa.
Pẹlu bi ọpọ awọn ajafẹtọọ ṣe n da Biya lẹkun to lati ma ṣe dupo naa mọ, ti wọn ni ko gba awọn ọdọ laaye, baba agba naa ko dahun rara.
Wọn ni ko si agbara fun un lati kopa ninu iwọde iponlongo ibo, iyẹn lo fi jẹ Europe lo gba lọ lasiko iponlongo ọlọjọ mẹwaa, to si jade polongo lọjọ kan ṣoṣo.
Imọ ẹrọ AI ti ki i ṣe otitọ ni wọn ni Biya n lo fi polongo ibo, nigba ti ọjọ ogbo ti n yọ ọ lẹnu.
"Ìdá ogójì àwọn ọ̀dọ́ Cameroon kò ríṣẹ́ ṣe''

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty Images
Gẹgẹ bi akọsilẹ International Organization for Migration (IOM), o fẹrẹ to ida ogoji (40%) awọn ọdọ orilẹede Cameroon ti wọn ko riṣẹ ṣe.
Ọjọ ori awọn ọdọ naa wa laaarin ọdun mẹẹẹdogun si marundinlogoji (15-35) bi ajọ naa ṣe wi.
Ida mẹtalelogun ninu wọn lo ti kẹkọọ gboye tan lai ri nnkan kan ṣe.
" Awọn ọdọ orilẹede wa maa n fẹ lati japa lọ si oke okun ni, nitori won maa n sọ funra wọn pe awọn ko le ṣe oriire ni Cameroon yii. Wọn maa n sọ pe awọn agbaagba ti gba gbogbo ipo tan, ko si nnkan kan fun awọn ọdọ mọ."
Ọdọ kan to ti kawe gboye, Vanina Nzekui; ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn (26) lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.
Ninu ọrọ awoye oṣelu kan niluu naa, Marie Flore Mboussi, o ni bi eeyan ba dagba to bayii nipo agbara, ti ko fi aaye silẹ fun awọn ọdọ, ọlẹ ni yoo pada da nipo naa, ko ni I le ṣe nnkan kan.
"Lẹyin ọdun mẹtalelogoji, o ti su awọn eeyan."
Yatọ si airiṣẹ ṣe awọn ọdọ, ai si aabo, ọwọngogo ọja,ajẹbanu, ai si nnkan amayedẹrun fun araalu tun jẹ awọn iṣoro miran to n koju orilẹede Cameroon lati ọdun pipẹ sẹyin.
Bakan naa ni ẹnu tun n kun awọn eleto idibo orilẹede naa, pelu bi wọn ṣe yọ Maurice Kamto, alatako Biya lara awọn oludije.
Oṣu Keje ni won yọ Kamto, ẹni ọdun mọkanlelaadọrin (71).
Wọn yọ ọ kuro lara awọn oludije lẹyin ti ẹgbẹ to fa a kalẹ tun yan ẹlomi-in lati ṣoju wọn.
Eyi ni awọn awoye sọ pe o waye ki Paul Biya maa baa ni alatako to le gbe e ṣubu .
Lapapọ, oludije mejila lo dide lati du ipo aarẹ naa tẹlẹ, lara wọn ni Issa Tchiroma Bakary ati Bello Bouba Maigari – ti wọn jẹ alajọṣẹ Biya tẹlẹ.
Awọn meji kan ti ja kuro bayii.
Ṣugbọn boya Paul Biya yoo tun ri ipo naa gba, boya awọn ọdọ yoo tun dibo fun ni ohun ti ọpọ eeyan n reti.














