Ìdí rèé tí Maryam Sanda, obìnrin tó gún ọkọ rẹ̀ ní ọbẹ̀ pa, ṣe gba àforíjìn ààrẹ lẹ́yìn ọdún mẹ́fà àti ààbọ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Ọkọ Maryam Sanda, Bilyaminu Bello, de fila alawọ eérú gogoro pẹlu aworan obìnrin náà, tó we gele Pupa pelu aṣọ Pupa àti goolu, to si n rẹrìn pẹlu eyin funfun nita.

Oríṣun àwòrán, Maryam Sanda

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tí forí jin Maryam Sanda, obìnrin kan tí ilé ẹjọ́ dàjọ́ ikú fún lọ́dún 2020 lórí ẹ̀sùn pé ó gun ọkọ rẹ, Bilyaminu Bello, ni ọbẹ̀ pa.

Sanda, ẹni ọdún mẹtadinlogoji lo tí lo ọdún mẹ́fà àti oṣù mẹ́jọ ni ọgbà ẹ̀wọ̀n Suleja, kò tó rí ìdáríjìn gba láti ọ̀dọ̀ ààrẹ.

Atẹjade kan tí agbẹnusọ fún ààrẹ, Bayo Onanuga, fi síta lo ṣalaye ìgbésẹ̀ náà.

Atẹjade náà ni idarijin tí ààrẹ fún Sanda da lori ìmọ̀ràn tí Ìgbìmọ̀ to wa eto ìpèsè idarijin fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n láti ọ̀dọ̀ ààrẹ gbé kalẹ.

Agbẹjọ́rò agba àti Mínísítà feto idajọ, àgbà Amòfin Lateef Fagbemi si lo kọ̀ igbimọ náà sodi.

Igbìmọ̀ náà ni "Sanda ń hùwà bíi ọmọlúwàbí lọgba Ẹ̀wọ̀n, tó sì ti fihan pe o kabamọ ìwà isekupani to hu náà."

Wọn ní àwọn àyípadà rere sí ti bá ìhùwàsí rẹ, èyí tí wọn ṣàpèjúwe bíi awokọse rere fawọn ẹlẹ́wọ̀n to tí ronú pìwà dà.

"Àwọn ẹbí rẹ náà tún ti bẹbẹ fún ìdáǹdè rẹ kúrò lọgba Ẹ̀wọ̀n nítorí àyípadà rere to tí bà a, tó sì tún nílò láti lọ máa ṣe itọju àwọn ọmọ rẹ méjèèjì."

Maryam Sanda wa ni aarin àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí wọn dàjọ́ ikú fún, pẹlu awọn òun àti ọkọ rẹ tó di olóògbé

Ki ní ohun tí Maryam Sanda ṣe, to fi gba ìdájọ́ ikú?

Aanu abiyamọ̀ yoo se eeyan nile ẹ́jọ lọ̀jọ Aje ogunjọ oṣu kejì ọdún 2020 nigba ti adajọ ileẹjọ giga nilu Abuja gbe idajọ kalẹ pe Maryam Sanda jẹbi ẹsun ipaniyan.

Maryam yii ni wọn lo fi ọbẹ gun ọkọ rẹ, Bilyaminu Bello, eyi to ran sọrun ọsan gangan lọdun 2017.

Bi o tilẹ jẹ pe Maryam sọ̀ pe oun ko mọwọ mẹsẹ lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan oun naa, sibẹ o papa foju ba ileẹjọ.

Lẹyin atotonu agbẹjọro fun ijọba ati igun olujẹjọ, ni adajọ kede pe Maryam jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan, to si ni ki wọn lọ yẹgi fun titi ti ẹmi yoo fi bọ ni ara rẹ.

Ṣe ni Maryam ń wa ẹkún mu nílé ẹjọ́ lórí ìdájọ́ ikú tí wọn fun, to fi mọ̀ awọ̀n ẹbi ati ibatan rẹ to wa nile ẹjọ.

Bi o tilẹ jẹ pe Maryam Sanda pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ ikú náà àmọ́ síbẹ̀, ilé ẹjọ́ kotẹmilọrun da ẹjọ́ náà nù, to si n ṣe Ẹ̀wọ̀n lọ.

Wo àwọn èèyàn miran ti ààrẹ Tinubu fún ní idarijin bíi Herbert Macaulay àti Nnamdi Azikwe tí wọ́n ti kú àtàwọn mẹ́rìnlá míì

Herbert Macaulay wọ aṣọ kootu dudu ati ẹwu funfun, Ọgagun agba Mamman Vatsa wọ aṣọ ologun, nigba ti Nnamdi Azikwe wọ aṣọ funfun balau pẹlu fila dudu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Bayo Onanuga/X

Àkọlé àwòrán, Ọgagun Mamman Jiya Vatsa ti ijọba Babangida ṣeku pa, Ken Saro-Wiwa ti ijọba Ọgagun Sani Abacha pa, Farouk Lawan, to jẹ ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin l'Abuja tẹlẹ lawọn mii ti Tinubu forijin.

Aarẹ Bola Tinubu kede l'Ọjọbọ ọjọ kẹsan an oṣu Kẹwaa ọdun yii wi pe oun ti ṣe aforijin fawọn ajijagbara ọmọ Naijiria kan, atawọn oloṣelu to fi mọ ọgagun agba kan to ṣiṣẹ nile iṣẹ ọmogun Naijiria sẹyin.

Lara awọn ti Aarẹ Tinubu forijin ni Herbert Macaulay ati Nnamdi Azikiwe ti wọn jẹ ajijagbara fun ominira orilẹede Naijiria.

Ọgagun Mamman Jiya Vatsa ti ijọba Babangida ṣeku pa, Ken Saro-Wiwa ti ijọba Ọgagun Sani Abacha pa, Farouk Lawan, to jẹ ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin l'Abuja tẹlẹ lawọn mii ti Tinubu forijin.

Oludamọran aarẹ lori ọrọ iroyin, Bayo Onanuga, to fọrọ naa lede loju opo Facebook re; ṣalaye pe igbimọ alaṣẹ orilẹede Naijiria buwọlu aṣẹ aarẹ lati fori jin gbogbo awọn eeyan naa.

Herbert Macaulay

Tinubu fori jin Herbert Macaulay to jẹ ogbontarigi ajijagbara fun ominira Naijiria, ti sun jẹ ọkan lara awọn oloṣelu to da ẹgbẹ oṣelu NCNC silẹ.

Macaulay ni aarẹ akọkọ ẹgbẹ oṣelu NCNC, ẹgbẹ naa si ko ipa pataki ninu akitiyan lati gbominira fun orilẹede Naijiria lati ọwọ ijọba amunisin ilẹ Gẹẹsi.

Amọ, ijọba amunisin ilẹ Gẹẹsi sọ pe Macaulay jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an wi pe o kowo jẹ nibi iṣẹ awọlẹ kan to ṣe, wọn si fofin de e lọdun 1913 wi pe ko gbọdọ dipo oṣelu kankan mu ni Naijiria.

Bo tilẹ jẹ Macaulay ku lọdun 1946, o si wa ninu akọsilẹ nipa rẹ o si ni ẹsun ọdaran ti wọn fi kan an.

Mamman Vatsa

Ọgagun agba Mamman Vatsa ti ijọba ologun Ibrahim Babangida ṣeku pa naa wa lara awọn ọmọ Naijiria to tik u ti Aarẹ Tinubu fori jin.

Lọdun 1986 ni ijọba Babangida dajọ iku fun Ọgagun agba Vatsa lori ẹsun pe o ditẹ mọ ijọba ologun to wa lode nigba naa.

Ọdun 1986 yii naa ni wọn si fi ẹyin rẹ ti agba.

Ọgagun agba Vatsa to jẹ onkọwe nigba aye rẹ ni minisita olu ilu Naijiria lasiko ijọba Babangida.

Ken Saro-Wiwa

Ajijagbara, onkọwe ati ajafẹtọọ ayika, Ken Saro-Wiwa ni ogbontarigi ọmọ Naijiria mii to ti ku ti Aarẹ Tinubu ṣe aforijin fun un.

Lọdun 1995 ni ijọba ologun Sani Abacha ṣeku pa Saro-Wiwa atawọn ajijagbara mẹjọ mii ti wọn jọ jẹ Ogoni lati ipinlẹ Rivers.

Saro-Wiwa lo n ṣiwaju ijagbara fun ayika ilẹ Ogoni eyi ti wọn sọ pe ileeṣẹ rọbi Shell n bajẹ.

Ijọba Abacha fẹsun kan Ken Saro-Wiwa atawọn ajijagbara mẹjọ mii ti wọn jọ n ja fun ilẹ Ogoni wi pe awọn lo ṣokunfa iku awọn oloye mẹrin nilẹ Ogoni.

Ijọba ologun Abacha ni wọn jẹbi ẹsun to fi kan wọn, wọn si yẹgi fun Saro-Wiwa atawọn akẹgbẹ rẹ mẹjọ.

Nnamdi Azikwe

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oloogbe Ọmọwe nnamdi Azikwe naa wa lara awọn to ti ku ti Aarẹ Tinubu darijin.

Arokọ kan ti Ọmọwe Azikwe kọ eyi Wallace-Johnson gbe jade to pe akọle rẹ ni ''Ṣe ilẹ Afirika ni Ọlọrun?'' lọdun 1936 lo ko o si wahala.

Ijọba amunisin ilẹ Gẹẹsi fẹsun kan an pe o ditẹ o si n kọ awọn araalu si ijọba.

Wọn lo jẹbi ẹsun naa, o si gba idajọ ẹwọn oṣu mẹfa, bo tilẹ jẹ o jare bọ nile ẹjọ kotẹmilọrun ti o si pada sile lọdun 1937.

Aarẹ Tinubu tun darijin Farouk Lawan, Arabinrin Anastasia Daniel Nwaobia, amofin Hussaini Umar ati Ayinla Saadu Alanamu.

Aarẹ darijin wọn ki wọn le maa ṣe gbogbo nnkan tawọn ọmọ Naijiria mii n ṣe lẹyin ti ilẹ ẹjọ ti sọ ṣaaju pe wọn jẹbi oniruuru ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Tinubu tun darijin Nweke Francis Chibueze, to wa lẹwọn gbere lori wi pe o jẹbi ẹsun gbigbe ogun oloro cocaine pẹlu Ọmọwe Nwogu Peters toun ti wa lọgba ẹwọn fun ọdun mejila ninu ọdun mẹtadinlogun ti ileẹjọ da fun un lori ẹsun iwa jibiti ti o jẹbi rẹ.

Aarẹ tun foye dawọn oloye Ogoni mẹrin, Albert Badey, Chief Edward Kobani, Chief Samuel Orage, ati Theophilus Orage ti wọn ṣeku pa lasiko ijọba Abacha lọla.

Aarẹ Tinubu tun lo agbara rẹ lati darijin ẹlẹwọn mejilọgọrin, o si tun mu adinku ba iye ọdun ẹwọn awọn ẹlẹwọn marundinlaadọrin

Tinubu tun foju aanu wo awọn ẹlẹwọn meje ti wọn dajọ iku fun, aarẹ yi idajọ wọn pada si ẹwọn gbere.

Ọgọọrọ eeyan mii naa ni wọn ri idarijin gba lọwọ Aarẹ Tinubu gẹgẹ bi oludamọran aarẹ ṣe kede lanaa Ọjọbọ.