Ṣé lóòótọ́ ni pé agbénipa kọlú ọ̀gá Àmọ̀tẹ́kùn l'Osun? Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ẹ̀rí ò sí láti fìdí ẹ̀ múlẹ̀

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police ForceX
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọsun ni irọ to jinna si otitọ ọrọ ni bi ọga Amọtẹkun Isaac Omoyele ṣe pariwo pe awọn agbanipa fẹ gba ẹmi oun.
Ko si ootitọ ninu awuyewuye wi pe awọn kan ṣe ikọlu si Isaac Omoyele to jẹ ọga awọn Amọtẹkun ẹka ti ipinlẹ ọsun lati gba ẹmi rẹ rara.
Akọroyin fun BBC news yoruba kan si ofiisi awọn ọlọọpa nipinlẹ ọsun, ni bẹ ni agbẹnusọ fun ile isẹ ọlọọpa ẹka ti ipinlẹ ọsun Abiodun Ojẹlabi fi idi rẹ mulẹ pe, ko si ohun to jọ pe awọn agbanipa fẹ gba ẹmi Isaac Omoyele ọga Amọtẹkun ti ipinlẹ ọsun rara.
Ojẹlabi tẹsiwaju pe, ninu iwadi awọn ọlọọpa ni ko si ẹnikankan to le fi idi isẹ naa mulẹ ni agbegbe ti isẹlẹ naa ti sẹlẹ titi di asiko yii.
O ni, awọn ri ohun ti ọga Amọtẹkun ṣe bi ẹni to fẹ da omi alaafia ipinlẹ ọsun ru ati lati ko ipaya baa olugbe ipinlẹ ọsun ni.
Ojẹlabi, wa tẹsiwaju pe, ọpọlọ Isaac Omoyele ko mọ ọna odo mọ, o wa fẹ daa si iwuru ni iwa ti ko boju mu ti ọga Amọtẹkun naa wu, to sii lodi si agbekalẹ eto abọ.
O tun tẹsiwaju lati jẹ ki akọroyin BBC ko ri ọkọ ti ọga Amọtẹkun naa sọ pe, awọn agbanipa da ibọn bo. Sugbọn nipa ti a de ibi ọkọ naa ni ko si oju ibọn lara ọkọ naa rara.
Ojẹlabi, o ni di asiko ti oun bawa sọrọ yii, awọn ko ti ri Isaac Omoyele bẹẹ ni awọn ko ti mọ ile iwosan to sọ wi pe oun wa di asiko yii. Sugbọn iwadi awọn un tẹsiwaju lori isẹlẹ naa.
Ojẹlabi, wa rọ gbogbo olugbe ipinlẹ ọsun lati fi ọkan balẹ ki olukaluku mọ lọ si bi isẹ wọn pẹlu alaafia. O ni awọn ti kan si iluu Akinlalu lati tun fi wọn lọkan balẹ pe, ko si wahala mọ ki wọn si fi ọkan wọn balẹ.
Gẹgẹ bi awọn ti sọ pe, ọga agba fun ile isẹ ọlọọpa ni Najiira Kayode Egbetokun ti pasẹ lati jẹ ki ofiisi Amọtẹkun gbogbo to wa ni ipinlẹ ọsun ko wa ni ti ti pa ni asiko yii naa lati le jẹ ki alaafia ko wa ati lati le ṣe iwadi to peye lori gbogbo rogbodiyan naa.
Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Naijiria ní kí wọ́n ti gbogbo ọ́fíìsì Amotekun pa, lẹ́yìn táwọn afurasí agbénipa rọ̀jò ìbọn lórí ọ̀gá Amotekun l'Osun

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force?X
Ọga agba ọlọpaa ni orilẹede Naijiria, Kayode Egbetokun, ti paṣẹ pe ki wọn ti gbogbo ọfiisi ẹṣọ Amọtẹkun to wa nipinlẹ Osun pa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni igbesẹ yii ko ṣẹyin bi awọn Amọtẹkun ẹka ti ipinlẹ ọsun ṣe ṣi agbara lo, a ti pe bi ọga awọn ẹṣọ Amotekun l'Osun, ṣe kọ lati yọju si awọn ọlọpaa lẹyin ti wọn ranṣẹ pe e.
Ti ẹ o ba gbagbe, lọsẹ to kọja ni ẹṣọ Amọtẹkun ṣe ikọlu si awọn eeyan kan ti wọn pe ni janduku niluu Akinlalu to wa ni ijọba ibilẹ iwọ-oorun Ifẹ ti ikọlu naa si gbẹmi ọmọ iya meji ati ẹnikan ti ọpọ eeyan to fara kaasa nibi iṣẹlẹ naa si wa ni ile iwosan lọwọlọwọ bayii.
Ni ọjọ Aje ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kẹfa osu Kẹẹwa ọdun yii ni a tun gbọ pe, awọn afurasi agbanipa kan fẹ ṣeku pa ọga awọn Amọtẹkun l'Osun, gẹgẹ bi agbẹnusọ ẹṣọ eleto abo naa, Idowu Yusuf ṣe fi idi rẹ mulẹ.
Sugbọn gbogbo igbiyanju awọn ọlọpaa lati ri Oloye Omoyele lati gbọ ti ẹnu rẹ, pabo lo jasi.
Agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa ti ipinlẹ Osun, Ojelabi, ni gbogbo igbiyanju awọn lati ri ọga Amotekun ba sọrọ jasi pabo tori ko fi aye rẹ silẹ fun awọn.
O ni aimoye igba ni awọn ti ransẹ si i ti awọn si tun pe e lori ẹrọ alagbeka sugbọn to kọ lati yọju si awọn.
Sugbọn, lọwọlọwọ bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe gbogbo ọfiisi awọn ẹṣọ alaabo Amọtẹkun kaakiri ipinlẹ Ọṣun ti pa.
Agbẹnusọ ọlọpaa tun fi kun ọrọ rẹ pe awọn ẹṣọ Amọtẹkun ogun lo ti wa ni ahamọ ọlọpaa bayii.
Bakan naa ni Ọgbẹni Ojelabi sọ pe awọn ko ni kaarẹ igbiyanju awọn lati ri daju pe ọga ẹṣọ Amotekun l'Osun wa sọ tẹnu rẹ lori ikọlu to waye niluu Akinlalu.
Ọgbẹni Ojelabi ṣalaye siwaju si i pe ọga agba ọlọpaa Naijiria i orilẹ-ede yii tun ti pasẹ pe ki awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n pe ni Intelligence Response Team (IRT) lati Abuja lo duro wamuwamu ni gbogbo ofiisi Amọtẹkun to wa nipinlẹ Osun, ki wọn si bẹẹrẹ iwadii lori isẹlẹ naa.














